Gbogbo Ìṣísẹ̀ Ńy'ọrí SíbìkanÀpẹrẹ

Every Step An Arrival

Ọjọ́ 5 nínú 5

Ìjọsìn Tòótọ́

Bóyá gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó se àìwọ́pọ̀ jù nínú Orin Dáfídì yí ni "O bomi rin poro oko rẹ̀ lọpọlọpọ, o ṣètò àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀; o rọ òjò tó mú kí ilẹ̀ rọ̀, o sì mú kí ohun ọ̀gbìn rẹ̀ dàgbà."(Orin Dafidi 65:10 Bm) Ìmọ̀lára ẹni tí ó kọ psalmu yí jẹ́ ti ọ̀pọ̀. Ó ríi bí ìgbàtí ọdún bẹ̀rẹ̀ nínú ayé titun ti ìgbà òjò, bí ayaba tí a dé ní adé ọ̀ṣọ́ ti Ọlọ́run, tí a wọ̀ ní àsẹ̀sẹ̀ dàgbà ti oko. Tí àwọn agbo ẹran tí ó wà ní àwọn òkè àti ilẹ̀ se ìránṣẹ́ fún.Bí a se ńfetí sí bí oní psalmu se ńfi ìmọ̀lára rẹ̀ hàn nípa àwọn nǹkan ìyanu yìí, àwa náà á máa fẹ́ kí á wà níbẹ̀

Bíótilẹ jẹ pé psalmu yí ò sọ tààrà nípa rẹ̀, àkókò ìgbà tí a kọ psalmu yìí kún fún ìkìlọ nípa Ọkùnrin tí yíò rọ́pò ìṣẹ̀dá pẹ̀lú ìjọ, tí yíò ṣe ìjọsìn rẹ̀ níbẹ̀ kàkà kí ó ṣé nínú tẹ́mpìlì tàbí ilé ìjọsìn. Èyí tún jẹyọ nínú Ọkùnrin tí ó sọ wípé òhun le sin Ọlọ́run ní ọ̀nà tí ó dára jùlọ, nípa wíwo ẹwà wíwọ̀ oòrùn Dípò kí òhun gbàdúrà lọ́nà àtijọ́ nínú ilé ìjọsìn tí ó móoru. Ó lè jọ́sìn lọ́nà tí ó dára jùlọ lójú rẹ̀, sùgbọ́n kò dàbí ó jọ́sìn sí Ọlọ́run ṣùgbọ́n ó ńsin òòrùn, tàbí ìmọ̀lára rẹ̀ nípa òòrùn.

Ìjọsìn Krìstẹ́nì jẹ́ yíya àkókò àti ààyè s'ọ́tọ̀. Ohun tí à ńwò, ibi tí à ńgbé, àti àwọn ohun tí ó jámọ́ ǹkan lásán ni a ńsọ di ògidì fún wákàtí ìjọsìn Krìstẹ̀nì, nígbẹ̀hìn, kí á lè rí ìtumọ̀ ayérayé tí ó ní. Ìjọsìn fún wa ní ìtumọ̀ pàtàkì tí ó ga jùlọ nípa àkókò àti ààyè ti ayé lásán. Kò sí ẹnití yíò fẹ́ gbé nínú ayé ìjọsìn ní gbogbo ìgbà. Sùgbọ́n ìjọsìn má ńjẹ́ kí gbogbo ohun tí krìstẹ́nì bá se dára síi ni.

Krìstẹ́nì tí ó kúrò nínú wákàtí ìjọsìn mọ̀ wípé ìfẹ́, ìrètí, ìgbàgbọ, ìyìn, Ìbùkún àti oore ọ̀fẹ́ pèsè ìdá ìyàtọ̀ ní ìṣẹ́jú kékeré, tí ó se ìyàtọ̀ ayérayé nínú ìgbésí ayé.Krìstẹ́nì tí ó ńjọ́sìn rí bíi oníṣẹ́ ìdárayá tí ó ńdárayá. Ó ní ìrírí ìtumọ̀ àkókò àti ààyè. Tí ó bá padà sí bí ó ṣe wà kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí dárayá, ìyàtọ̀ àti ìṣe déédé yíò wá nínú ìmọ̀lára rẹ̀ àti ìṣesí rẹ̀, tí kò sí níbẹ tẹ́lẹ.

Nígbà wo ni ìrírí ìjọsìn se yí Ìbálòpọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn àti Ọlọ́run padà níkésé tí o parí ìjọsìn?

Tí o bá gbádùn ètò ọlọ́jọ́ máàrún yìí tí ó wá láti ọwọ́ Eugene Peterson, yẹ ìwé Eugene wò níGbogbo Ìṣísẹ̀ Ńy'ọrí Síbìkan. .

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Every Step An Arrival

A lérò wípé àwọn ẹ̀kọ́ àṣàrò márùn-ún tí a t'ọwọ́ Eugene Peterson kọ yìí máa mú àyà àti ọkàn rẹ lọ síbi ti o fẹ́, nítorí a kò mọ ǹkan tí Ẹ̀míi nì ma lò láti gbani níyànjú, peni níjà, tàbí tuni nínú. O lè yàn láti lo àwọn ìbéèrè tó wà ní ìparí ẹ̀kọ́ àṣàrò kààǹkan láti ṣe àkòrí àdúrà rẹ fún ọjọ́ náà — kìíṣe ṣe gẹ́gẹ́bí ìparí ṣùgbọ́n bíi ìbẹ̀rẹ̀ fún àwọn ìbùkún tí a ti ṣètò sílẹ̀ fún ọ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://waterbrookmultnomah.com/books/540871/every-step-an-arrival-by-eugene-h-peterson/