Gbogbo Ìṣísẹ̀ Ńy'ọrí SíbìkanÀpẹrẹ

Every Step An Arrival

Ọjọ́ 4 nínú 5

Ìjọ Tí a Lè Fojú Rí

Bí Sólómọ́nì ti ṣe dúró níwájú tẹ́ńpìlì tuntun, ó bere ìbẹ̀rẹ̀ tí gbogbo wa ma ń bèrè leekokan: “Ǹjẹ́ Ọlọ́run le fi adúgbò wa ṣe ibùgbé ní tòótọ́?” (1 Àwọn Ọba 8:27, msg).

Irú ìbéèrè akọ yìí ní a fi kẹ́gàn Sólómọ́nì, ṣùgbọ́n ó gbàdúrà síbẹ̀ síbẹ̀. Ó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run gbọ́ igbe àwọn eniyan nígbàtí wọ́n bá wá sinú ilé náà láti gbàdúrà, pé kí Ọlọ́run dáhùn sí ẹ̀dùn wọn lọ́sàán lóru, àti pé kí Ọlọ́run dárí jì wọ́n tí Ó bá gbọ́ ohùn wọn. 

Àìgbàgbọ́ yi ti di oun tí a ńṣe lé ra wọn lọ́kanòjọkan láti orí Sólómọ́nì títí kàn wá. Ṣùgbọ́n awa na, bi Solomon, a ti tẹ síwájú làti ma gbàdúrà, láì bìkítà. Ọgbọ́n orí lásán tó tako wípé Ọlọ́run fi ayé ṣe ibùgbé nínú ilé àdúrà, pẹ̀lú pé Ọlọ́run ń bá wa pàdé nínú ilé ìjọsìn, kò tíì ní agbára tó lè d'ojú ẹ̀rí ìrírí àti ti ìgbàgbọ́ bo ilẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lo, ọgbọ́n orí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ètò àyẹ̀wò tí kò láyọ̀lé ti a fi n jeri òtítọ́. Ìbéèrè akọ “Ǹjẹ́ ó ha le ríbè?” ni ó gba ìdáhùn àròjinlẹ̀, ìrírí tó gbòòrò, àti ọkàn ìgbàgbọ́ tó yanrantí tó n wípé, “Bẹ̀ẹni, ní tòótọ́!” 

Nínú àdúrà Sólómọ́nì tí ó gbà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, a lè rí bí oríṣi ọ̀nà mẹ́ta tí àwọn oun tí a rí ṣe jẹ́ atọ́kùn oun tí a kò rí, àwọn ọ̀nà yi, bákan náà sì jẹ́ oun tí à ń bá ṣe lóde òní. Àkọ́kọ́ ní ṣe pẹ̀lú ìtàn. Solomon mú wá sí ìrántí àwọn ìbápàdé ńlá pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtijọ́. Ọkàn tí kìí rántí àtẹ̀yìnwá, ọ̀tá àdúrà ni. 

Èkejì ní ṣe pẹ̀lú ìdáríjì. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni à ń wọ inú àdúrà pẹ̀lú ọkàn láti mú Ọlọ́run gbè sẹ́yìn wa. Ṣùgbọ́n ìjọ tí a rí yii kò fàyè gba irú ẹ. Ìdáríjì ní o mú àyípadà bá àdúrà, ìtẹ̀síwájú kúrò nínú lílé ọ̀nà tiwa lòdì sí Ọlọ́run sí fífi ayé wa jìn fún Un kí Ó ba à lè ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ nínú ẹ̀. 

Abala kẹta ni Sólómọ́nì fi ẹnu bá nígbàtí ó sọ pé in the word àtìpó, which can also be translated “àjèjì.” Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀dùn ọkàn wa kò bá ti ta yọ àwa nìkan ṣoṣo, ẹbí wa, agbo kótópó àwọn ojúlùmọ̀ wa, a sọ gbogbo ìmọ̀lára ìjọ Kristì lapapọ nù àti ti ayé tí Kristì ń wá láti mú wọnú ìdàpọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. 

Àwọn ẹ̀kọ́ mẹ́ta nínú àdúrà ti Sólómọ́nì yí ni a lè gé nì kúkúrú sí ọ̀rọ̀ mẹ́ta: ìtàn (iṣẹ́ Ọlọ́run láti ẹ̀yìn wá), ìdáríjì (ìyípadà kúrò lọ́dọ̀ ara ẹni sí ìfẹ́ Ọlọ́run), àti àwọn ẹlòmíràn (tàbí àjèjì). Gbàdúrà nípasẹ̀ ọrọ tí ó ń fọ sí ọ báyìí-báyìí. 

  

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Every Step An Arrival

A lérò wípé àwọn ẹ̀kọ́ àṣàrò márùn-ún tí a t'ọwọ́ Eugene Peterson kọ yìí máa mú àyà àti ọkàn rẹ lọ síbi ti o fẹ́, nítorí a kò mọ ǹkan tí Ẹ̀míi nì ma lò láti gbani níyànjú, peni níjà, tàbí tuni nínú. O lè yàn láti lo àwọn ìbéèrè tó wà ní ìparí ẹ̀kọ́ àṣàrò kààǹkan láti ṣe àkòrí àdúrà rẹ fún ọjọ́ náà — kìíṣe ṣe gẹ́gẹ́bí ìparí ṣùgbọ́n bíi ìbẹ̀rẹ̀ fún àwọn ìbùkún tí a ti ṣètò sílẹ̀ fún ọ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://waterbrookmultnomah.com/books/540871/every-step-an-arrival-by-eugene-h-peterson/