Gbogbo Ìṣísẹ̀ Ńy'ọrí SíbìkanÀpẹrẹ
Ní Ìgbà Kan Rí
“Ní Ìgbà Kan Rí” ló ma ń ṣáájú gbogbo ìtàn tó bá lóyin. Ohun náà ni ọ̀nà tí àwọn Kristẹni ma ń gbà kojú ìbéèrè náà wípé “Ǹjẹ́ ayé mi ní ìtumọ̀” Nínú ìtàn, gbogbo àwọn tó wà nínú ìtàn náà ló ṣe kókó. Oníkálukú nínú ìtàn náà ló ní ipa tirẹ̀. Fún ìdí èyí, a máa ń sọ wípé “Nígbà kan rí” tí a ó sì tẹ̀lẹ́ e pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti iyèméjì wa, ìgbọràn àti àìgbọràn wa, ìjọsìn àti àìbìkítà wá. Àwọn ǹkan wọ̀nyí àti irúfẹ́ rẹ̀ a máa wà nínú ìtàn—ìyẹn ìtàn tó ní ìtumọ̀.
Kìíṣe gbogbo ìtàn ló dá lórí àwọn akọni. Kìíṣe gbogbo ìtàn ló dá lórí ìrìnàjò ní ayé àtijọ́. Lóòótọ́ ni ìtàn nípa àwọn akọni wà—bíi ìtàn Jósẹ́fù, Mósè, Dáfídì, àti Pọ́ọ̀lù. Àmọ́ a rí àwọn ìtàn bíi ti Náómì, Rúùtù, àti Bóásì. Nínú eléyìí, bí ìṣẹ̀lẹ̀ ti ń ṣẹ̀ lójojúmọ́ là ń pa àlọ́ rẹ̀. Àmọ́ gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ ojojúmọ́ náà—ìrìnàjò náà, ìdúróṣánṣán Rúùtù pẹ̀lú Náómì, ìkáàánú Rúùtù tí Bóásì ṣe, ìfọkànsí Òfin—gbogbo atótónu yìí ló ní ipa tirẹ̀ nínú ìtàn tó jẹ́ ẹ̀yà ìtàn ìgbàlà ńlá tí Ọlọ́run ńṣe. Ìtàn náà tó ní ìtumọ̀—tó sì nííṣe pẹ̀lú ohun gbogbo.
Ìtàn yí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìkùnsínú Náómì. Ó ń jẹ̀róra àdánù tó bá a, ó fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ hàn, ẹni tó kọ ìtàn náà fa àlà sábẹ́ ìbànújẹ́ rẹ̀ àti bí ó ti fi ẹ̀dùn náà hàn sí Ọlọ́run. A kọ àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì yí bí ìgbà tí olòfisùn bá wà níwájú adájọ́. Ìwé Jeremáyà náà ní irú ìtakùrọ̀ yí, níbi tó ti ń sọ̀rọ̀ bíi agbejọ́rọ̀ láàrin Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn Rẹ̀. Ó mú gbogbo ẹ̀dùn ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì kó wọn lọ síwájú Ọlọ́run bí agbejọ́rọ̀, olórí ẹ̀sùn tó mú wá náà ni wípé Ọlọ́run kùnà láti ṣe ohun tó tọ́ àti èyí tó yẹ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìtàkùrọ̀sọ fẹ́ jọ èyí tí kò ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, kódà bíi ọ̀rọ̀ òdì lórí, láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ báyìí, àmọ́ òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé ó bá ìlànà Bíbélì mu. Nípasẹ̀ títẹ́ etí sí ẹ̀dùn ọkàn àwọn tó yí wa ká tí a sì kó wọn tọ Ọlọ́run lọ, à tipasẹ̀ èyí mú oníkálukú ènìyàn wá sínú ìtàn náà. Kò pọn dandan fún wa láti gbè lẹ́yìn Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà. Àwọn àkókò kan wà tí àwọn ìdúró wa nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì a máa fì sí ọ̀dọ̀ olùfisùn. Nípasẹ̀ fífún un ní àkíyèsí—láì fọwọ́ rọ́ ọ sẹ́gbẹ̀ẹ́, láì fomi já a—àròyé àti ẹ̀dùn Náómì wá di ara ìtàn náà. Bí ìgbésí ayé rẹ̀ ti ṣófo ni ó wà nínú kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn yí, pẹ̀lú pẹ̀lú, fún ìpèsè àti ìwàláàyè Ọlọ́run láti farahàn.
Ǹjẹ́ ìwọ ń kánukò láti fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ hàn fún Ọlọ́run bí? Báwo ni ìtàn Náómì ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ láì f'ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A lérò wípé àwọn ẹ̀kọ́ àṣàrò márùn-ún tí a t'ọwọ́ Eugene Peterson kọ yìí máa mú àyà àti ọkàn rẹ lọ síbi ti o fẹ́, nítorí a kò mọ ǹkan tí Ẹ̀míi nì ma lò láti gbani níyànjú, peni níjà, tàbí tuni nínú. O lè yàn láti lo àwọn ìbéèrè tó wà ní ìparí ẹ̀kọ́ àṣàrò kààǹkan láti ṣe àkòrí àdúrà rẹ fún ọjọ́ náà — kìíṣe ṣe gẹ́gẹ́bí ìparí ṣùgbọ́n bíi ìbẹ̀rẹ̀ fún àwọn ìbùkún tí a ti ṣètò sílẹ̀ fún ọ.
More