Gbogbo Ìṣísẹ̀ Ńy'ọrí SíbìkanÀpẹrẹ
Gbígba Oun tí Ọlọ́run tií Ńṣe
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igba, nínú ìtàn Bíbélì, a máa ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ara wa ju àwọn ìtàn àti ẹ̀yìn wá lọ. Ọ̀rọ̀ inú ìbéèrè Gídíónì ti ẹ̀kọ́ kíkà á máa fò síwa lẹ́nu: “Bí Olúwa bá wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo ìwọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa?" (verse 13, Byo).
Ó dàbí pé Ọlọ́run wà jìnà réré nígbàtí ayé wa kún fún ikú, wàhálà, àìní rí nkan ṣe, iṣẹ́ tí kò tẹ wa lọ́rùn, àwọn ènìyàn tí ọ̀rọ̀ wa kò wọ, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò le yí padà. A un fetí léko sí ìdáhùn sí ìbéèrè Gídíónì ní ìrètí pé a óò gbó ìdáhùn sí tiwa náà. Ṣùgbọ́n ní bí ó ti ma ń ṣẹlẹ̀ ni ọ̀pọ̀ ìgbà láàrín Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn inú Bíbélì, kò sí ìdáhùn, tàbí kí ísẹ irú oun tí a kà sí ìdáhùn. Dípò bẹ́ẹ̀, àṣẹ ni: “Gba àwọn ará Israẹli sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani” (verse 14, byo).
Èsì Gídíónì dàbí èyí tí àwa náà yóò ṣe: “Wò mí, Ìdílé mi ni ó jẹ́ aláìlera jù ní Manase, àti pé èmi ni ó sì kéré jù ní ìdílé baba mi.” (verse 15, byo). Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi hàn Gídíónì pé kò sí àyè láti tún má ní ìrònú òdì sí àwọn àṣìṣe àtẹ̀yìnwá, kò sí àyè fún à ń wádìí àlàyé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àmúwá, kò sí à ń ṣe àyẹ̀wò ara ẹni. Àtiṣe wà lọ́wọ́ Ọlọ́run, bí ó ti ṣe wà ní Íjíbítì. Gídíónì kàn nílò láti gbọ́ràn kí ó sì di ìlérí mú. Kìkì kí ó ti sìn, Ọlọ́run Yóò sì mú ìṣẹ́gun wá.
Nísinsìnyí, o le wo ọjọ́ ayé ẹ sẹ́yìn, tú itan ìdílé lọ sẹ́yìn, ṣàkíyèsí àwọn ìṣe ti orílẹ̀-èdè, kí o sì rí ohun tí ó ma ń ṣẹlẹ̀ nígbàtí ènìyàn bá kọ̀ láti kọjú sí Ọlọ́run tí ó si kọ ìfẹ́ Rẹ̀. Àìgbọràn rọrùn láti dámọ̀. Lára àwọn ìfarahàn rẹ̀ ni kí á máa lọ́ra láti wùwà ẹ̀tọ́, ọkàn ìdá lẹ́bi tí ó lè mú kí oúnjẹ má dà, ẹrú ẹ̀bi ẹ̀sẹ̀ tí ń mú kó rẹ ní láì jaunpata, àti ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tí ó ma ń fa ẹ̀bùn àtinúdá gbẹ.
Fún ẹ̀yin tí ẹ rí irú ìfarahàn yí nínú yín, mo ní ìròhìn ayọ̀: Ọlọ́run fẹ́ràn yín, Ó sì ṣe tán láti dárí ẹ̀sẹ̀ rẹ ji àti láti tún ọ dá àti láti fún ọ ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ọlọ́run tí ṣe tán, ní àkókò yí, láti fa igi lé oun àti atijọ́, láti pa àkọsílẹ̀ rẹ, láti jó run àwọn ìwé àkọsílẹ̀ lórí ẹ. Kòsí oun kan ti o ti ṣe tàbí tí ó gbà lérò ni yóò mú ọ kùnà làti ģba oun ti Ó ún ṣe lọ́wọ́ báyìí fun o.
Àkókò wo ni o ti kẹ fín àìlera rẹ tàbí àkíyèsí awon ìkùnà àtijọ́ tí wọ́n ń dè ẹ lọ́nà láti tẹ̀lé ona Ọlọ́run?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
A lérò wípé àwọn ẹ̀kọ́ àṣàrò márùn-ún tí a t'ọwọ́ Eugene Peterson kọ yìí máa mú àyà àti ọkàn rẹ lọ síbi ti o fẹ́, nítorí a kò mọ ǹkan tí Ẹ̀míi nì ma lò láti gbani níyànjú, peni níjà, tàbí tuni nínú. O lè yàn láti lo àwọn ìbéèrè tó wà ní ìparí ẹ̀kọ́ àṣàrò kààǹkan láti ṣe àkòrí àdúrà rẹ fún ọjọ́ náà — kìíṣe ṣe gẹ́gẹ́bí ìparí ṣùgbọ́n bíi ìbẹ̀rẹ̀ fún àwọn ìbùkún tí a ti ṣètò sílẹ̀ fún ọ.
More