Nínú Ohun GbogboÀpẹrẹ

In All Things

Ọjọ́ 5 nínú 5

Ayọ̀ Wa Ṣe Pàtàkì sí Jésù

Ní alẹ́ tó ṣíwájú ọjọ́ tí yóò kú, Jésù jẹ oúnjẹ àjẹkẹ́yìn, ó sì sọ ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀. Kínni ohun tó jẹ Jésù lógún jù bí ó ṣe ń palẹ̀mọ́ láti fi àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí jùlọ sílẹ̀?

Ni Johannu 14-16 a kà á pé Jésù tu àwọn ọmọ ẹ̀hin Rẹ̀ nínú Ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ọkàn wọn dàrú. Ó tún kọ́ wọn láti dúró ṣinṣin. Láì sí Jésù, kò sí ohun tí wọ́n lèè ṣe. 

Jésù tún ṣàlàyé ìdí tí Ó fi ń bá wọn sọ gbogbo eléyìí. Ó sọ pé, "Gbogbo nnkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fun yín, kí ayọ̀ mi le wà nínú yín, àti kí ayọ̀ yín k'ó lè kún" (Johannu 15:11). 

Ayọ̀ wa ká Jésù lárá.

Omijé kún ojú mi bí mo ti ṣe ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Ìyanu ìfẹ́, ìfẹ́ aláìlábùkù! Ní àsìkò t'ó wà nínú ìrora tí kò láfiwé, ayọ̀ tèmi àti tìrẹ ni Jésù ń ṣàfẹ́rí. Ó ya ni lẹ́nu, àbí bẹ́ẹ̀kọ́? Nítorí ayọ̀ tí a gbé síwájú Rẹ̀, Jésù fara da àgbélébú (Heberu 12:2).

Kìí ṣe ayọ̀ díẹ̀ ni Jésù ń retí pé kí á ní, Ó fẹ́ kí á ní ayọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ - ayọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti àkúnwọ́sílẹ̀. Ayọ̀ wa ṣe pàtàkì sí Jésù  

Jésù ni orísun àti alágbèéró ayọ̀ wa. Láì síi Rẹ̀, òfo ni ayé wa àti gbogbo ìlàkàkà wa láti ní ìtẹ́lọ́rùn. A ó ma rìn kiri, a ó sì ma pòùngbẹ gidigidi títí tí a o fi mu láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin, Álfà àti Ómígà. Ọwọ́ Rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀bùn rere ti wá, kò sì sí ohun rere kankan tó sẹ̀yìn Rẹ̀. Nítorí náà àníyàn wa láti láyọ̀ túmọ̀ sí àníyàn láti ní Jésù.

Nínú Fílípi, a rí ayọ̀ nítòótọ́. Ayọ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàlà, ó sì ń kún síi bí a ti ń ní ìrírí ìbáṣepọ̀ tòótọ́, tí ipò Jésù gẹ́gẹ́ bí Olúwa ń yé wa síi, tí à ń ṣe alábàápín ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Krístì, tí a sì ń gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí a ṣe ń dàgbà nínú ìgbàgbọ́, àníyàn wa ń yípadà. À ń ṣàfẹ́rí láti mọ Jésù. A ń fi ìrètí wa sínú ayọ̀ ti ọ̀run dípò àyídáyidà ayé. A ń gbàdúrá pẹ̀lú ọpẹ́ dípò kí á máa káyà sókè pẹ̀lú ìdààmú ọkàn. A ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtọrẹ kí isẹ́ ìhìnrere lè máa tẹ̀síwájú. 

Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe kọ́ àṣírí níní ìtẹ́lọ́rùn nínú ọ̀pọ̀ àti nínú àìní, bì a ṣe ń dàgbà nínú gbígbáralé Ọlọ́run, a ó máa rẹwà gẹ́gẹ́ bí obìnrin aláyọ̀.

Ọ̀rọ̀ mi sí ọ lákòtán, yóò fi ìpòngbẹ ọkàn mi fún ọ hàn pé: Má tẹ̀tì láti kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlórun. Dúró nínú Ọlọ́run, gbàdúrà sí I kí o sì máa ṣàfẹ́rí Rẹ̀ nígbà gbogbo.

Kí ayọ̀ Rẹ̀ kó wà nínú rẹ lẹ́kùnrẹ́rẹ́.

Kí ló túmọ̀ sí láti yan ayọ̀, bí ó ti wù kí ó rí?

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

In All Things

Ìwé náà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ tó wà ní Fílípì ló ti la ìran kan kọjá sí ìmí láti mú ìtùnú àti ìpèníjà bá ọkàn wa lónìí. Ètò kíkà ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí yóò fún ọ ní ìtọ́wọ̀ ìwé Fílípì, lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún mélòó kan ọdún tí Ọlọ́run ti t'ọwọ́ Pọ́ọ̀lù kọ ọ́. Kí Ọlọ́run kún ọ fún ìyanu àti ìfojúsọ́nà bí o ti ń ka ìwé tó kún fún ayọ̀ yí! Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kìí ṣe ti Pọ́ọ̀lù nìkan sí ìjọ àtijọ́ kan—ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ọ ni wọ́n jẹ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://waterbrookmultnomah.com/books/561570/in-all-things-by-melissa-b-kruger/