Nínú Ohun GbogboÀpẹrẹ
Ní ìbẹ̀rẹ̀ létà rẹ̀ sí àwọn ará Fílípì, Pọ́ọ̀lù fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Kristi Jésù, ó sì kọ̀wé sí àwọn ẹni mímọ́ nínú Kristi Jésù. Yíyan òrò rẹ nibi jẹ́ pàtàkì lórí awọn àbájáde méjèèjì. Káàkiri jákèjádò Májẹ̀mú Láíláí, awọn olùdarí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni a fun ni ìyàtọ̀ ti a pe ni awọn ìránsé Ọlọ́run.
Nígbà ti Páùlù fi ara rẹ̀ hàn, o ṣe ìyípadà díè. Páùlù ko pe ara rẹ ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run tabi ìránṣẹ́ Olúwa. Ó sọ pé ìránṣẹ́ Kristi Jésù ni òun. Yiyan ọrọ yìí ni ìtúmọ pàtàkì kan:o fi Jésù dọgba pèlú Ọlórun.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè jẹ́ ìròyìn àtijọ́ fún èmi àti ìwọ, ó ṣe pàtàkì láti inú ojú ìwòye ìtàn pé Pọ́ọ̀lù gbà pé Jésù àti Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kan náà. Òye pé Jésù ni Ọlọ́run kì í ṣe ìtàn àròsọ kan tó wáyé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ikú Rẹ̀, nígbà táwọn èèyàn ti gbàgbé ẹni gidi. Àwọn tí wọ́n tẹ̀ lé e tí wọ́n sì mọ̀ ọ́n fúnra wọn gbà pé Jésù jẹ́ Ọlọ́run ní kíkún àti ènìyàn ní kíkún.
O wù ní lórí láti kíyèsi pé Póòlù pé àwọn ará Fiílípì níàwọn èèyàn mímó. Níti gidi, gbólóhùn òrò yìí ní o lọ déédéé nínú àwọn létà é nígbà tí o bá tóka síàwọn onígbàgbọ ẹlẹgbé rẹ. (Póòlù kò kowe sí “àwon elésè ní Róòmù” tàbí níbomíràn òràn rè yí)
Níwòn ìgbà tí a bá jẹ ara ẹbí Olórun, a rí wa gégé bí àwọn èèyàn mímó, kìí ṣe èlèsè. Jíjẹ a eni mímó kò túmò sí pé a jé pípé. Ẹni tí a bá gbàgbó pé a má jé ní a máa di ìdánimọ̀ wa kò túmò sí pé a gbà òmìnira lówó esè. A máa se àsìse ní ilé ayé wa. Àmó sa, ìyàtò nlá wa láàrin jíjẹ ẹni mímó tón tiraka pèlú ẹ̀ṣẹ̀ àti elèsè tó gbìyànjú láti jé ẹni mímó.
Ní ìsírí lónìí: o jé eni mímó Olórun Tó féràn! Ọ lè máa nímòlárà pé o jé béè, àmó ìdánimò rè kò yípádà, o fìdí múlẹ̀ ní ìhà tí Olórun kò sí e. Nípa ìgbàgbọ nínú Jésù, Olórun tí so wá dọmọ a sí jé ara ẹbí E.
Lọ àkókó nínú ádùrá, béèrè lówó Olórun láti fún ọ nítúrá àti so ọkàn rẹ dótún pèlú ìròyìn ayọ. O rorun láti ní ìrèwèsi nípa àwọn àṣìṣe àti ìkùna wa. Dájúdájú kí a ní ìróbínúje àti jewó ẹse. A tún nílò láti yọ ayò nínú ìdánimọ̀ wa tuntún. Tò Olúwa lọ isllníinsinyi, fàlàlà, ní ìháragàgà, pèlú ìgboyà, àti kún fún ìrètí. O rí é gégé bí ọmọ Rè, o sí lè mú gbogbo ìrètí, ìbẹrù, àti àwọn ìjákúlè rè sódò E.
Kíni dì tí ìdánimò wa nínú Olórun se jé nńkan láti láyò nípa?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ìwé náà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ tó wà ní Fílípì ló ti la ìran kan kọjá sí ìmí láti mú ìtùnú àti ìpèníjà bá ọkàn wa lónìí. Ètò kíkà ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí yóò fún ọ ní ìtọ́wọ̀ ìwé Fílípì, lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún mélòó kan ọdún tí Ọlọ́run ti t'ọwọ́ Pọ́ọ̀lù kọ ọ́. Kí Ọlọ́run kún ọ fún ìyanu àti ìfojúsọ́nà bí o ti ń ka ìwé tó kún fún ayọ̀ yí! Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kìí ṣe ti Pọ́ọ̀lù nìkan sí ìjọ àtijọ́ kan—ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ọ ni wọ́n jẹ́.
More