Nínú Ohun GbogboÀpẹrẹ

In All Things

Ọjọ́ 2 nínú 5

Ore Ọ̀fẹ́ Ìgbàlà

Ẹjẹ́ kí á padà lọ sí ìbẹrẹ iṣẹ́ ìránṣẹ́ Pọ́ọ̀lù, nígbàtí Ọlọ́run ṣe ìpìlẹ̀ fún ayọ̀ Pọ́ọ̀lù. Ọlọ́run yí ọkàn Pọ́ọ̀lù padà ó sì tún dáasí láti jẹ́ àpọsítélì, èyí fún ní ìpè àṣẹ nínú ìjọ, nígbà díẹ̀ si, àǹfàní láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́. Ọlọ́run yí ayé Ọkùnrin yí padà, ó gbé sí ònà láti pín ìhìnrere Jésù pẹ̀lú àwọn tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ àwọn Júù. Ọlọ́run pèsè isẹ́ ìránṣẹ́ fún Pọọlù, Ó sì ṣe ìgbáradì Pọ́ọ̀lù fún isẹ́ ìránṣẹ́ náà. Pọ́ọ̀lù lọ láti ẹni tíí ṣe inúnibíni ó di oníwàásù ó tún wá di ẹni tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí.

Bí ó ti jẹ́ pé àwá lè má nìí ìrírí tí Pọ́ọ̀lù ní, bí iná se yìi ká lójijì, tí ó la ojú tí kò ríran ní ìrìn-àjò rẹ̀ sí Damasku, ìkọ̀ọkan wa ní ìtàn ìgbàgbọ́ tí ó jẹ́ iṣẹ́ ìyànu fún ra rẹ̀ Ìtàn rẹ lè rí bíi ti Pọ́ọ̀lù, tàbí kí ó ní ìrírí ìjídìde sí ìgbàgbọ́ lẹ́sẹsẹ. Ọlọ́run a máa pe ìkọ̀ọkan wa sí ọ̀dọ̀ Rẹ ní onírúurú ọ̀nà. Ní ọ̀nà-kọnà tí ó gbé sisẹ́ nínú ayé rẹ̀, ìròyìn ayọ̀ ibẹ̀ ni wípé, ìpẹ́pẹ́ tí ó dí ọ lójú tẹ́lẹ̀ jábọ́ kúrò ní òjú ẹ̀mí rẹ! Ọlọ́run ti pèsè iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún o, ó sì tún ṣe ìgbaradì fún o láti ṣe ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn.

Pọ́ọ̀lù pàdé orísirísi àwọn ènìyàn nígbàtí ó wà ní Fílíppì. Lydia, fún àpẹrẹ, jẹ́ onísòwò obìnrin tí ó wá láti Thyatira, ó l'ówó láti pe Pọ́ọ̀lù àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wá sí ìdílé rẹ̀. Pọ́ọ̀lù tún pàdé ọmọbìnrin erú, àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n, àti olùṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tí ó pín ìhìn rere pẹ̀lú gbogbo ìdílé rẹ.

Àwọn ọkùnrin àti obìnrin, olówó àti àwọn tí kò ní, ẹlẹ́sìn àti àwọn tí wọ́n kò l'ẹ́sìn, àwọn tí wọ́n lágbára nípa ti ìṣèlú àti àwọn ọ̀tá ìlú. Ìròyìn ti ìhínrere wà fún gbogbo ènìyàn. Kò si ẹni tí ó dára jù láti nílò ìhìnrere, kò sìi sí ẹnití ó ti sọnù tí ìhìnrere ò lè wárí.

Wá àkókò díẹ̀ lónì láti fi ìrísí lórí ìtàn ìgbàlà tìre. Bóyá o ṣì wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àti mo ore ọ̀fẹ́ ìgbàlà! Tàbí o mọ ẹni kàn tí ó nílò láti gbọ́ ìròyìn ayọ̀ tí ìhìnrere. Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run sí ojú ọkàn irú ẹni bẹ́ẹ̀.

Ìwé Filippi jẹ́ ìgbàsílẹ̀ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ láàrin Pọ́ọ̀lù àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ ní Filippi, gbogbo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ìwé ìránṣẹ́ láàrin Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn Rẹ̀, bí Ó se ń fi ara rẹ̀ hàn láti àìmọye ọdún, kí gbogbo ènìyàn le wá s'ọ́dọ̀ Rẹ̀.

Tani Ọlọ́run ń lò nínú ayé rẹ láti mú ọ súnmọ́ Ọlọ́run?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

In All Things

Ìwé náà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ tó wà ní Fílípì ló ti la ìran kan kọjá sí ìmí láti mú ìtùnú àti ìpèníjà bá ọkàn wa lónìí. Ètò kíkà ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí yóò fún ọ ní ìtọ́wọ̀ ìwé Fílípì, lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún mélòó kan ọdún tí Ọlọ́run ti t'ọwọ́ Pọ́ọ̀lù kọ ọ́. Kí Ọlọ́run kún ọ fún ìyanu àti ìfojúsọ́nà bí o ti ń ka ìwé tó kún fún ayọ̀ yí! Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kìí ṣe ti Pọ́ọ̀lù nìkan sí ìjọ àtijọ́ kan—ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ọ ni wọ́n jẹ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://waterbrookmultnomah.com/books/561570/in-all-things-by-melissa-b-kruger/