Nínú Ohun GbogboÀpẹrẹ

In All Things

Ọjọ́ 1 nínú 5

Ìpòngbẹ Wa Tó Ga Jùlọ

Owó, òkìkí, ìbáṣepọ̀, àti àṣeyọrí—àwọn oun tí à ń lé kiri—wọ́n dàbí àtẹ̀gùn láti fi já ọ̀nà. Ìpòngbẹ wa tó ga jùlọ ni ayọ̀. Àlàáfíà. Ìtẹ́lọ́rùn.

A lè ma retí pé owó yóò ra àlàáfíà fún wa tabi ìbáṣepọ̀ yóò mú ayọ̀ wa fún wa. Ṣùgbọ́n ìgbé ayé kìí tọ̀ọ́ lọ bàa ṣe rò pé ó yẹ. Àwọn ohun tí a kò jọ pọ̀ yí wa ká síbẹ̀ wọn kọ̀ láti fún wa ní ìtẹ́lọ́rùn. Ìbáṣepọ̀ tó gún régé jù lè mú ìdààmú tó ga jù wá. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn Ìpòngbẹ ọkàn dáradára yi—ayọ̀, àlàáfíà, ìtẹ́lọ́rùn—dàbí pé wọ́n ga kọjá ìnàgà. 

Ìwọ àti èmi nílò oun kàn tó ju gbogbo oun tí a lè kó jọ nípa agbára wa. A nílò oun kan tó tayọ wa, oun kan tó lágbára jù wá, oun kan tó dúró ṣinṣin. Oun kan yìí tí a ń wá kiri, oun kan yìí tí a ní ìrètí láti rí? Kìí ṣe oun kan. Ènìyàn ni. 

Jẹ́ kí n ṣe òfófó: Jésù ni. 

Mo mọ̀ pé ó jọ oun tí kò ní ìtumọ̀. Ó ti rọrùn jù, àbí? Bótiwùkórí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan ni kò yé wa ju èyí tóyé wa lọ nípa Jésù. Òun ni Ẹlẹ́dàá, Olùgbéró, àti orísun oun gbogbo tó dára, àti pẹ̀lú ní iwájú Rẹ̀ ni "ekúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ wa” (Psalm 16:11). Bí a bá ṣe ń mọ Jésù síi, bẹ́ẹ̀ ni mí mọ ayọ̀, àlàáfíà, àti ìtẹ́lọ́rùn wa ń pọ̀ si. Kí kọ ẹ̀kọ́ ìwé Fílípì ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye síi bi mii mọ́ síi ṣe mú ìyàtọ̀ dání. 

Ìwé Fílípì jẹ́ ìpè sí ayọ̀, tí a ti ọwọ́ Pọ́ọ̀lù àpọ́sítélì nínú ìdè àtìmọ́lé kọ sí àwọn onígbàgbọ́ ìjọ ìṣáájú tí à ń pọ́n lójú who lati ọwọ́ àwọn alátakò. Oun kan pàtó tí ó tẹnu mọ́ nínú ìwé yìí ni "Ẹ máa yọ̀!” 

Ayọ̀ rẹ̀ kò ṣeé mí. Àlàáfíà rẹ̀ dúró ṣinṣin. Ìrètí rẹ̀ kún rẹ́rẹ. Ibo ló ti rí irú ọrọ̀ tó jinlẹ̀ báyìí láàrin irú ipò tó nira yìí? Irú ìsun wo ló mu tí ó yó báyìí? Báwo ló ṣe mọ àṣírí ìtẹ́lọ́rùn? 

Ǹjẹ́ èmi náà lè mọ́ọ bí? 

Gbogbo àwọn ìbéèrè yìí dúró lọ́kàn mi lóòrèkóòrè tí mo bá ti ka ìwé Fílípì. Bí mo ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ́ síi, bẹ́ẹ̀ ni òún yé mi síi ìyàtọ̀ ayọ̀ Pọ́ọ̀lù àti ìdùnnú tí mò ń lé kiri. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni mò ń fi ọkàn mi lépa wúrà òmùgọ̀ àti ọ̀ṣọ́ asán dípò kín gbé e lé ọrọ̀ tó wà nínú Kristi. Àwọn nkan mèremère ayé—ilé tí kò ní àléébù, iṣẹ́ tó ṣeé fi yangàn, ìsinmi tó gbà fẹ́, tàbí ètò ìsúúná tó fi ọkàn balẹ̀—wọ̀nyí lè fún ni ní ìdùnnú tí kò tọ́jọ́ tí ń já ni kulẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Kò sí oun tó burú nínu kí ènìyàn jẹ ìgbádùn èyíkéyìí nínú àwọn nkan wọ̀nyí; ó kàn jẹ́ pé wọn kò le fún ni ní ìtẹ́lọ́rùn tó ń báni di alẹ́. Ní kòpẹ́kòpẹ́, wọn á sọ dídán mèremère wọn nù. Ìrètí àti àdúrà mi ni pé a ó le di (ènìyàn) aláyọ̀ tó dúró kalẹ. 

Kíni nkan tí ó ń fún ọ ní ayọ̀ jùlọ ni ayé rẹ ni báyìí?

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

In All Things

Ìwé náà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ tó wà ní Fílípì ló ti la ìran kan kọjá sí ìmí láti mú ìtùnú àti ìpèníjà bá ọkàn wa lónìí. Ètò kíkà ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí yóò fún ọ ní ìtọ́wọ̀ ìwé Fílípì, lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún mélòó kan ọdún tí Ọlọ́run ti t'ọwọ́ Pọ́ọ̀lù kọ ọ́. Kí Ọlọ́run kún ọ fún ìyanu àti ìfojúsọ́nà bí o ti ń ka ìwé tó kún fún ayọ̀ yí! Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kìí ṣe ti Pọ́ọ̀lù nìkan sí ìjọ àtijọ́ kan—ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ọ ni wọ́n jẹ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://waterbrookmultnomah.com/books/561570/in-all-things-by-melissa-b-kruger/