Nínú Ohun GbogboÀpẹrẹ

In All Things

Ọjọ́ 4 nínú 5

Ìpè sí Ayọ̀

Bí o tilẹ̀ jé wípé Poolu wà nínú ìdè, inú ré dún. Kíni ì bá mú irú ìdùnnú báyìí débá a pẹ̀lú ìrora àti ifarada ìrora bíburú tó n là kojá? Póòlù mò dájú pé kò sí enití ó lé gbá ìtúsíle òn nípa èmí lówó on. Nígbàtí gbogbo nnkan sókùnkùn, ìgbàlà ré mú inú re dùn. 

Ìwé Fílípì pè wá sí ìgbé ayé ayò. Igbàlà wa fún wa ní ayò tí o sinmi lori ohun tí o ní aabo ju ohúnkohún to wà lórí ilè. Ayò wa nínú Jésù: Ìgbé aiyé pípé Re, ìrúbo ikú Re, ìyánú àjínde Re. 

Bí o tílẹ̀ jé pé a tí see àsìse, tí a sï ñbá èsè jìjàkadì, tí a bá wa nínú Kristi, kò sí ohun tí o lè yà wá kúrò nínú ìfé Olórun. Àní orísun ayò ayérayé wà fún wa. 

Jesu fí ìdí òdódó múlè nípa rírán àwon omo èhìn Re létí pé ìpìlè ayò won kì í se àseyorí isé òjísé won, sùgbón bíkòse Olórun tí o dá won ní ìdè tí o sí ra won padà. Ìgbàlà je èbùn nla jùlo tí a le gbá. Ìgbàlà wa ni orísun ayò lópòlópò. Èyí yí ní ìhìnréré tabi ìròhín “ayò naa.” 

Lákókò ìjoba Griki ati Romu, ìhìnréré yí ní àwon adarí won maa nlo léhìn ìgbàtí won ba tí jagun-segun. Adarí yio rán asojú saaju láti maa polongo ìhìnréré tí o fún won ní ìségun. Eléyi ní o jásí ìdùnnú àti ayò fún gbogbo mùtúmùwà lábé àkóso adarí won. 

Nígbàtí Póòlù ñbá won sòrò ìhìnréré yí ní Fílípì, o sòrò gégébí asojú àwon ti o rí ìségun láti òkè wa. Ìhìnréré tí a sí nsòrò re yí tí tàn kaákìri fùn égbèrún méjì odún títí o fí dé òdò èmi atí ìwo lóní. 

A ti di aségun lórí èsè tí o jé ìdíwó àti ïdènà fun wa. A sí tí dárí jì wa lórí gbogbo ìdájó àti ìjìyà ti o tó sí wa. Ikú Jesu lórí igi àgbélébu tí San gbèsè èsè wa, àjínde Re so já sí ìségun fún wa. Bí o sí tí njoba ní òdò Baba, bee gégé ní àwa naa yio joba pèlú Re. 

Òpòlópò ohun ní o ye kí o jé áyò fún wa tí a bá wa lá bé ìjóbá Kristi, ìségun dájú pèlú ìdojúko tí a lè ní nínú aiyé gégé bí ìpónjú, ìtíráká, ìbásepò tí o méhe, àîléra, àti àwon ìdánwò miran nínú ïrìn àjò ìgbàgbó yí. Sùgbón a o ní àseyorí ní ìgbèhìn. Ohun gbogbo ní yio wa létòlètò. Ní òjókan, a o wá pèlú Oba wa nínú ìsímí àti aabo tí kò lópin. 

Báwo ní ìrísí ayérayé sé le yi ìwòye re nínú ayé re lóní?

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

In All Things

Ìwé náà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ tó wà ní Fílípì ló ti la ìran kan kọjá sí ìmí láti mú ìtùnú àti ìpèníjà bá ọkàn wa lónìí. Ètò kíkà ọlọ́jọ́ márùn-ún yìí yóò fún ọ ní ìtọ́wọ̀ ìwé Fílípì, lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún mélòó kan ọdún tí Ọlọ́run ti t'ọwọ́ Pọ́ọ̀lù kọ ọ́. Kí Ọlọ́run kún ọ fún ìyanu àti ìfojúsọ́nà bí o ti ń ka ìwé tó kún fún ayọ̀ yí! Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kìí ṣe ti Pọ́ọ̀lù nìkan sí ìjọ àtijọ́ kan—ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ọ ni wọ́n jẹ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://waterbrookmultnomah.com/books/561570/in-all-things-by-melissa-b-kruger/