Má Ṣe Rẹ̀wẹ̀sìÀpẹrẹ

Don't Give Up

Ọjọ́ 7 nínú 7

Ọjọ́ 7—Nehemiah Mọ̀ Ògiri Ná

Nehemiah ní ìmọ̀lára pé Ọlọ́run pe ohún láti tún ódí Jerusalemu mọ. Ni àkókò ìpè yí, ó wà ní ìlú àjèjì níbi tí o ti ńbá ọbà ṣiṣẹ́, ní ìlú tí o jìnà réré si ohún tí ó wà ni ọkàn rẹ̀ láti ṣe. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nìkan ti lè ṣé, Ó ṣí gbógbó ilẹ̀kùn Ó si ṣí ọ̀nà fún Nehemiah láti gbé ìgbésẹ sínú ìpè yi.

Kìí ṣe iṣẹ́ tí ó rọrùn. Ògiri náà ti di àlàpà. Àwọ́n ọmọ Israẹli tí fọ́n káàkiri. Ó sí dájú pé àtakò yóò wá. Ó wá nítóòtọ́.

Àwọn ènìyàn gbọ́ oún tí Nehemiah ń gbìyànjú láti ṣe wọ́n sì sapá láti tako iṣẹ́ náà. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n rú ìbínú, wọ́n sì gbèrò àti ṣe ibi. Ó burú tó bẹ́ẹ̀ tí Nehemiah fi yan ìdajì àwọn arákùnrin rẹ̀ kí wọ́n má sọ́nà pẹ̀lú oun ìjà ní ìgbáradì tí ọ̀tá bá dìde. Botilẹ̀jẹ́pé eléyìí yíó ṣe àmójútó ààbò, ṣùgbọ́n ó fi kún àkókò àti mọ́ odi náà tán ní ìlọ́po méjì.

Nígbàtí mo bá ka ìtàn yí, mo mà ńgbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀rọ-rọ́bọọti ti inú eré Lost in Space tó sọpé, “Ewu, Will Robinson.” Mi ò mọ̀ nípa tìrẹ, ṣùgbọ́n èmi lè ti ju ọwọ́ sílẹ̀. Iṣẹ́ tó ní ìdààmú, tí a bá tún wá fi ewu tí ó lè ṣẹlẹ̀ kun, tàbí fífi ẹ̀mí ara ẹni wéwu, o nílò láti fi ìdánilójú ìpè rẹ si oókan-àyà rẹ.

Ní ìlòdi sí gbógbó aiṣedede, Nehemiah ní ìfaradà. Kò kàn nìforítiì nìkan, ṣùgbọ́n gbógbó àwọn tó ń tẹ̀lé ìdarí rẹ̀ bákan náà. Ẹsẹ̀ 6 sọpé, “nítorí àwọn ènìyàn náà ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn.” Èyi jẹ́ LẸ́YÌN ìṣẹ̀rùbaní—kìí ṣe ṣíwájú. Ọkàn àti ìdúróṣinṣin Nehemiah láti mú ìlànà Ọlọ́run ṣẹ́ di ìtẹ́wọ́gbà láàárín àwọn tó ń bàa ṣiṣẹ́. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ gbòógì fún adarí tí nrẹ̀wẹsì.

Oún kan tó tún dàpọ̀ mọ́ ìfaradà wọn ni ìkọbiara sí adura. Wọ́n ké sí Ọlọ́run. Pàápàá jùlọ, wọ́n ṣe báyìi kí wọ́n tó gbé ìgbésẹ̀ kankan láti ṣètò ìdáàbòbò. Ipò àkọ́kọ́ tí wọ́n mú ni ti àdúrà—ìgbésẹ̀ to ṣe pàtàkì jù lọ láti gbé. Nígbàtí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run gbéra. Ọlọ́run dá hùn Ó sì dìde fún ààbò wọn.

Ó ṣe pàtàkì láti fi àdúrà sí ibi àkọ́kọ́ ìlàkàkà rẹ. Yóò rú ọkàn rẹ, rán ọ létí, àti fi ojú rẹ sójú kan kí o le faradà. Àdúrà jẹ́ gbòógì fún ìforítì.

Gẹ́lẹ́ tí ògiri náà di mímọ, ìwé Nehemiah parí pẹ̀lú àkọsílẹ̀ pé gbógbó àwọn orílẹ̀ èdè tó yí wọn ká rí ohún tó ṣẹlẹ̀ wọ́n sì mọ̀ pé Ọlọ́run ni Ó wà ní ìdí rẹ̀. Ìṣòtítọ Nehemiah mú kí iṣẹ́ náà parí, ṣùgbọ́n ju èyí lọ, ó fi ògo fún Ọlọ́run ní ọ̀nà tí kò ní ṣeé ṣe tí ó bá kọ̀ lati dúró d'ópin.

Àdúrà mi nii pé ìrìn àjò ọjọ́ méje yí ti rú ọkàn rẹ sókè láti tẹ̀ síwájú. Máà rántí àwọn ìlérí Ọlọ́run àti òdodo Rẹ̀. Ṣe rántí àwọn ọkùnrin àti obìnrin inú Bíbélì tí wọn kò juwọ́ sílẹ̀ nígbàtí ayé kọjú àtakò sí wọn. Ìwọ náà, ọ̀rẹ́ mi, o lè la ìjì kọjá. 

Bí o bá ń wá ọ̀rọ̀ ìṣítí síwájú si, jọ̀wọ́ tẹsíwájú sí orí ìwé ayélujára mi fún àwọn ìmọ̀ràn àmúlò fún àwọn ìpèníjà ojojúmọ́http://www.brittanyrust.com.

Ìwé mímọ́

Day 6

Nípa Ìpèsè yìí

Don't Give Up

Ṣé ìgbà kan wà tí ó rẹ̀ ọ́ tàbí tí làálàá ayé ti lù ọ́ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó dàbí kí o kọ ohun gbógbó sílẹ̀? Bíbélì kún fọ́fọ́ fún ìgbani-níyànjú láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú àforítì! Ètò kíkà ọlọ́jọ́-méje yìí yóò tù ọ́ lára ní ìmúrasílẹ̀ fún ìrìn-àjò iwájú rẹ.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Brittany Rust fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọ̀wọ lọ sí: http://www.brittanyrust.com