Má Ṣe Rẹ̀wẹ̀sìÀpẹrẹ
![Don't Give Up](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F11747%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Ọjọ́ 1— Ààlà-àríwà Tòótọ
Nígbà míràn ìwọ́ lè ní ìmọ̀lára bí ọkọ̀ ojú omi náà tí ó yà ara sọ́tọ̀ tí ìjì omi òkun ńsọ soke káàkiri. Síwájú àti sẹ́yìn ó ń léfòó láìsí ìtọ́sọ́nà, ó ńwá àpẹrẹ ìrètí àti ìrànlọ́wọ́. Láìsí atọ́ka ọ̀nà, àti dé orí ilẹ̀ gbígbẹ le ṣòro.
Alè sọ ohún kannáà nípa ìgbésí ayé. Arìnká láìsí atọ́ka ọ̀nà, pẹ̀lu ìrètí ati ṣé amúṣẹ ètò Ọlọrun ni fún ọ̀ lórí ilẹ̀ aye yíì, lé wá tà kókó púpọ. Kò jẹ́ ìdí tí o ṣe nílò ààlà-àríwà tòótọ- ìfojúsí ojúàmì kan tí ó dúró ṣinṣin, tí kò lè yí padà. Ọ̀kan ṣoṣo ló wà orúkọ rẹ̀ sì ni Jésù.
Ọlọ́run nìkan ló lè fún ọ ní ókún àti ìfaradà fún ìgbésí ayé tí ó gbilẹ̀. Tí ó bà rẹ̀ ọ́, Ọwọ́ Rẹ̀ tó dúró ṣínṣín yíò gbé ọ sókè, yíò sì mí èémí titún sínú egungun rẹ́. Nígbàtí gbogbo nǹkan bá dojú rú, tí o kò mọ ìsísẹ̀ tí ó kù láti gbé síwájú, Èémí Rẹ yíò dìde láti gbé ọ lẹ́ẹ̀kan si. Nígbàtí o bá sọnù àti tí kò sí ìdánilójú, Ọgbọ́n Rẹ àti òye Rẹ yíò ṣí ojú tó ńsàárẹ̀, yíò sì tán ìmọ́lẹ̀ Rẹ sí ìrìn-àjò tí ó wà níwájú.
Jẹ́ kí ó dá o lójú: kò sí ààlà-àríwà tòótọ míràn, kò sì sí orísun okun tí yíò mú ọ dúró, tàbí ìmọ́lẹ̀ tí yíò tọ́ ọ̀ sọ́nà ní tòótọ́. Fi èsì ayé nípa ohún tí ò ń là kọjá sẹ́yìn, kí o sì di ààlà-àríwà tòótọ rẹ mu. Òhún nìkan ni orísun tí kìí yẹ̀ àti ìdákọ̀rò rẹ nínú gbógbo ohún tí ò ń là kọjá.
Tí o bá ní ìmọ̀lára bíì ọkọ̀ ojú omi tí ìjì ń gbé lónì, kí o tó lépa ohunkóhun míràn, lépa Jésù. Kí Olúwa tọ́ ọkàn rẹ sọ́nà àti kí okun Rẹ̀ gbé ọ kọjá ìfonífojì nígbàtí ó bá fẹ́ sú ọ.
Lórí ètò kíkà ọlọ́jọ́ méje yìí, a ó kọ́kọ́ lọ sínú Bíbélì láti ṣe àwárí ohun tí Ọlọ́run sọ nípa sùúrù àti ìfaradà. Eléyìí jẹ́ ohun tí yíò ràn ọ létí àti tí yíò jẹ́ ìwúrí láti máa tẹ̀síwájú nígbàtí o bá dojú kọ ìṣòro. Nítorí náà, wá kí à jọ ṣíjúù ohun tí Bíbélì sọ nípa nkán tí àfaradà ńmú jáde àti pé tá ló tún ṣe sùúrù nínú ìpọ́njú.
Àti Rántí wípé: máa wo Jésù, ẹ̀yin ọ̀rẹ́!
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
![Don't Give Up](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F11747%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Ṣé ìgbà kan wà tí ó rẹ̀ ọ́ tàbí tí làálàá ayé ti lù ọ́ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó dàbí kí o kọ ohun gbógbó sílẹ̀? Bíbélì kún fọ́fọ́ fún ìgbani-níyànjú láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú àforítì! Ètò kíkà ọlọ́jọ́-méje yìí yóò tù ọ́ lára ní ìmúrasílẹ̀ fún ìrìn-àjò iwájú rẹ.
More