Má Ṣe Rẹ̀wẹ̀sìÀpẹrẹ

Don't Give Up

Ọjọ́ 4 nínú 7

Ọjọ́ 4—Èrè tí Nbẹ Níwájú Rẹ

Kò sí asáré tí o ńgba àmì ẹ̀yẹ lai sáré ìje. Kò sì agbábọ́ọ́lù tí o n gba ife ẹ̀yẹ lai se ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ imurasilẹ oún eré tí ma nmú ní borí. Kò sì alásè tí o gba ami ẹ̀yẹ James Beard laì si ipínnu ati iṣẹ́ kárakára ni ile ìdáná (Emi gégé bí àrounjẹyọ̀ rèé níbi!).

Kókó ọ̀rọ̀ ni wípé gbógbo èrè a má nilò ìfaradà. Dájudaju, èyí lè túmọ̀ sí ohùn dídára ni ile ayé yìí látàrí fífi wíwá Ọlọ́run ṣáájú. Ṣùgbọ́n jú èrè wọ̀nyí tó wà fún ìgbà díè, ní èrè ayérayé èyí tí a na ọwọ́ rẹ̀ sì onígbàgbọ́ òdodo.

Ó kò gbọ́dọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ lọ́wọ́ silẹ nígbàtí o bá dojú kọ ìdánwò àti ìpọ́njú. O kò gbọ́dọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ lọ́wọ́ sílè nígbà tí iji bá jẹ ki o rẹ̀ ọ́. Bí o tilè jẹ́ wípé tipátipá ni ori rẹ́ fi ńgbé sókè láàrín ìjì, má dáwọ́ dúró, máà wa ọkọ̀ ayé rẹ títí ìtura yóò fi de. Ṣáà má sọ ìrètí nu. Èrè tí ó rigba yíò jẹ́ iyalẹnu!

Èrè ìyè àìnípẹ̀kun pẹ̀lú ìmúṣẹ ohún gbógbo tí Ọlọ́run tí ṣèlérí mbẹ̀ fún ọ, bí o bá ní ìfaradà láti sáré ìje yìí. Bí o bá tẹjú mọ́ Jésù ti o si pá ìgbàgbọ́ mọ́, ó kì yíò kábàmọ̀ yíyọnda ohún gbógbo tí o ní fún Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá ìwọ̀ yíò kábàámọ̀ awon ìgbà tí o jọ̀wọ́ ohun gbógbo sílẹ̀ pé o sú ọ. Sọ̀dá álà ìṣẹ́gun botilewù kí o rẹ̀ tó nítorí o sà gbógbo ìpá rẹ̀ pẹlu inú dídùn, ni ìrètí èrè tí Ọlọ́run tí ṣé ìpinnu.

Ìwé mímọ́

Day 3Day 5

Nípa Ìpèsè yìí

Don't Give Up

Ṣé ìgbà kan wà tí ó rẹ̀ ọ́ tàbí tí làálàá ayé ti lù ọ́ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó dàbí kí o kọ ohun gbógbó sílẹ̀? Bíbélì kún fọ́fọ́ fún ìgbani-níyànjú láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú àforítì! Ètò kíkà ọlọ́jọ́-méje yìí yóò tù ọ́ lára ní ìmúrasílẹ̀ fún ìrìn-àjò iwájú rẹ.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Brittany Rust fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọ̀wọ lọ sí: http://www.brittanyrust.com