Má Ṣe Rẹ̀wẹ̀sìÀpẹrẹ

Don't Give Up

Ọjọ́ 3 nínú 7

Day 3—Níní Ìfaradà Nítorí Àwọn Elòmíràn

Pọ́ọ̀lù kìí ṣe àjèjì sí ìpọ́njú. Ó ní ìrírí ẹ̀wọ̀n, ìjìyà, ìjàmbá ọkọ̀-ojú-omi, ebi, ìrẹ̀wẹ̀sì, àti onírúurú ǹkan nítorí Kristi. Síbẹ̀, láàárín gbogbo ǹkan wọ̀nyí, ó ní ìfaradà. Ó ń tẹ̀síwájú síbẹ̀. Ṣùgbọ́n kìí ṣe fún Kristi nìkan—ó ṣeé fún nítorí àwọn èèyàn míràn pẹ̀lú.

Bẹ́ẹ̀ni, lábẹ́ ewu ikú ni à ń gbé lójojúmọ́ nítorí à ń sin Jésù, kí ìwàláàyè Jésù lè fara hàn nínú ẹran ara wa tó ń ṣègbé lọ. Fún ìdí èyí ojú ikú là ń gbé, ṣùgbọ́n èyí tí jásí ayé àìnípẹ̀kun fún un yín..”

Pọ́ọ̀lù mọ̀ wípé fífaradà ìpọ́njú ma ń fàyè sílẹ̀ fún ìṣelógo Kristi, èyí tó padà fa ìgbàlà ọkàn fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Bákan náà ló ti rí fún ìwọ àti bí o ti gbé ìgbésí ayé rẹ. Nígbà tí o bá ní ìfaradà lákòókò ìnira, tí o sì tẹra mọ́ ǹkan òtítọ́ àti iyì, àwọn èèyàn ma ṣ'àkíyèsí. Nígbà tí wọ́n bá rí bí o ti tamọ́ra ní àkókò ìnira yí, wọ́n ma fẹ́ mọ bí o ti ṣeé.

Àbúrò mi kùnrin fi èyí hàn dáadáa ní àkókò kan tó ṣòro ní ìgbésí ayé rẹ̀. Nígbà tó wà ní ọmọ ogún ọdún ó lé díẹ̀, òhun àti ọ̀rẹ́-bìnrin rẹ ní ìbálọòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. Èyí padà jásí oyún, èyí tó sì hàn sí wọn ní óku ọjọ́ kan tó ma filọ àfẹ́sọ́nà rẹ̀ pé kí wọ́n di lọ́kọ-láyà. Wọ́n ti s'àṣìṣe, àmọ́ wọn kò mọ ǹkan tó ma t'ẹ̀yin rẹ̀ yọ.

Ní kòpẹ́ẹ̀ tí wọ́n mọ̀ nípa oyún náà, ọ̀rẹ́-bìnrin rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò sì ri títí tó fi bí ọmọbìnrin fún un. Àkókò ìbànújẹ́ ọkàn tó nípọn ló jẹ́ fún àbúrò mi. Kò kàn pàdánù olólùfẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n kò tún ní àǹfààní láti wà níbẹ̀ nígbà tí a bí ọmọbìnrin rẹ̀ sáyé.

Ohun tó wá yani lẹ́nu nípa àkókò náà ni bí o ti la sáà náà kọjá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn. Ó tọ ipasẹ̀ ìmúbọ̀sípò lẹ́yìn ìkùnà rẹ̀, àmọ́ pẹ̀lú èyí ó tún wá rí ìbárẹ́ àti ìwòsàn lọ́dọ̀ Baba. Àwọn ènìyàn tó mọ̀ọ́—ìyẹn àwọn aláìgbàgbọ́—ṣe àkíyèsí ìfaradà rẹ̀ nínú ìjì náà, èyí fi ògo Ọlọ́run hàn. Ìnira rẹ̀ fi ògo fún Ọlọ́run ní àwọn ọ̀nà tó rẹwà. Pẹ̀lú ìdùnnú sì ni mo fi ń jẹ́rìí wípé Ọlọ́run mú ìbáṣepọ̀ wọn bọ̀ sípò, wọ́n sì ti fẹ́'ra níṣu-lọ́kà pẹ̀lú ọmọ méjì!

Mo sọ ìtàn yí nítorí oníkálukú wa lè ní ìrírí àwọn àkókò tó lè fẹ́ fa ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìsiyèméjì. Àmọ́ a kò gbọ́dọ̀ da ara sílẹ̀. A ní láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú bí sáà náà ṣe lè le tó. Ìbùkún ni yóò t'ẹ̀yin rẹ̀ yọ bí o bá lè fara dà á, àti wípé yóò wá di ìwúrí fún àwọn mìíràn. Ìfaradà rẹ ní agbára láti tari àwọn ènìyàn lọ sọ́dọ̀ Kristi, èyí tí yóò sì mú ìyípadà dé bá ayé àwọn ènìyàn!

Ìwé mímọ́

Day 2Day 4

Nípa Ìpèsè yìí

Don't Give Up

Ṣé ìgbà kan wà tí ó rẹ̀ ọ́ tàbí tí làálàá ayé ti lù ọ́ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó dàbí kí o kọ ohun gbógbó sílẹ̀? Bíbélì kún fọ́fọ́ fún ìgbani-níyànjú láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú àforítì! Ètò kíkà ọlọ́jọ́-méje yìí yóò tù ọ́ lára ní ìmúrasílẹ̀ fún ìrìn-àjò iwájú rẹ.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Brittany Rust fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọ̀wọ lọ sí: http://www.brittanyrust.com