Má Ṣe Rẹ̀wẹ̀sìÀpẹrẹ
![Don't Give Up](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F11747%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Ọjọ́ Kẹ́fà—Obìnrín Opó Alátẹnumọ́
Obìrin opó alátẹnumọ́ nnì máa ń fún mi ní ìwúrí àti ìgboyà láti tẹ̀síwájú nínú gbogbo ìdánwò mi. Mo rántí ìpinnu àti ìdúróṣinṣin rẹ̀ ní àwọn ìgbà tí èmi ti fẹ́ẹ̀ sọ̀gọ nù. Ìtàn rẹ̀ ló ń fún mi ní ìrètí nígbà tí ìrètí mi bá fẹ́ pin.
Nínú òwe tí Jésù pa, obìnrin opó kan wà tí ó ń bèèrè fún ìdájọ́ lọ́wọ́ adájọ́ aláìláànú kan. Ní ìbẹ̀rẹ̀, ó fi ìdájọ́ dù ú— ní tẹ̀lé n tẹ̀lé, ó kọ̀ láti yí ọkàn rẹ̀ padà sí obìnrin yìí. Ṣùgbọ́n obìnrin opó yìí kò sọ̀gọ nù. Lẹ́hìn ọ̀pọ̀ ìgbà tó ti ń bèèrè fún ìdájọ́, adájọ́ náà wá dá a lóhùn. Kínni ìdí? Nítorí kí obìnrin yìí lè fi í lọ́rùn sílẹ̀!
Jesù tẹ̀síwájú pẹ̀lú ẹ̀kọ́ nà wípé tí aláìsòdodo adájọ́ bá lè gbọ́ ìpẹ̀ obìnrin opó, ẹni tí kò bìkítà fún bí kìí bá ṣe àtẹ́númọ́ rẹ̀, báwo ni Ọlọ́run kò ṣe ní dáhùn ìpẹ̀ tí àwọn ọmọ Rẹ̀ bá mú wá s'ọ́dọ̀ Rẹ̀.
Ọlọ́run dára o sì ṣe gbẹ́kẹ̀le. Olódodo ni Ó sì ń gbọ́ àdúrà àwọn ènìyàn rẹ̀ ní tòótọ́. Ìgbà míràn lè wà tó lè dàbíi pe àdúrà rẹ kò gbà, tàbí pé Ọlọ́run kò fẹ́ràn rẹ tó àwọn ẹlòmíràn. Ó ti ṣe èmi náà rí, mo sì mọ̀ pé ipò tí ó nira ní. Ṣùgbọ́n oò gbọdọ̀ sọ̀gọ nù
Obìnrin opó yìí kò tẹ̀tì láti lọ sọ́dọ̀ adájọ́ tí kò ṣòotọ́. Pẹ̀lú òye yìí lọ́kàn rẹ, gbá iyànjú áti tẹ̀síwájú ní wíwá Ọlọ́run olódodo fún àwọn nnkan wọ̀nnì t'ó ṣe pàtàkì si ọ. Dájúdájú, Ó ńgbọ́ tìrẹ. Ó le má dáhùn bí o ṣe fẹ́ tàbí nígbà tí o wùn ọ, ṣùgbọ́n ní gbógbó ìgbà l'Ó máa dáhùn lọ́nà to tọ́ àti nígbà tó yẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
![Don't Give Up](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F11747%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Ṣé ìgbà kan wà tí ó rẹ̀ ọ́ tàbí tí làálàá ayé ti lù ọ́ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó dàbí kí o kọ ohun gbógbó sílẹ̀? Bíbélì kún fọ́fọ́ fún ìgbani-níyànjú láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú àforítì! Ètò kíkà ọlọ́jọ́-méje yìí yóò tù ọ́ lára ní ìmúrasílẹ̀ fún ìrìn-àjò iwájú rẹ.
More