Aláìjuwọ́sílẹ̀ Pèlú Lisa Bevere Àpẹrẹ
Àwọn ènìyàn fún ẹgbẹ̀rún ọdún ti ńwá ǹkan tí wọ́n ń pè ní 'ádámà'òkúta tíó farasin yìí jẹ́ ohun tí ó ní agbára, mágínẹ̀tì, óní ìtàná ó sì jẹ́ ǹkan tí kò lè bàjẹ́. Àwọn olórí lérò wípé tí àwọn bálè wáa, wọ́n máa lè lò ó fún ohun-ìjà àti ìhámọ́ra láti lè ní agbára tí kò ṣeé borí. Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún àwọn akọni máa ń jáde láti wá òkúta onídán yìí.
Mo fẹ́ràn èrò tí ó ń wá sọ́kàn yí. Ǹkankan wá tó máa ń fanimọ́ra nípa lílépa àti àwọn òkúta agbára, ṣùgbọ́n kò sí eni tó ń lépa fún òkúta tí kòyéwa yìí mọ́. Ní báyìí, ìwádìí ti yàtọ̀. Aráyé kò wá àlùmọ́ọ́nì tí kò ṣeé fọwọ́kàn mọ́, ṣe ni wọ́n ń wá òtítọ́ tí kò ṣeé fọwọ́kàn tí kòsì ṣeé yí padà.
Ní oókan àyàa wa, afẹ̀ ǹkan tó ṣeé gbá mú, tó sì dúróṣinṣin. Kódà, Pọ́ntíù Pílátù bèrè lọ́wọ́ Jésù wípé, "Kí ni òtítọ́?" Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, èyí jẹ́ ìbéèrè tóle-bẹ́ẹ̀ni fún ìgbà tó ti pẹ̀, lati ńfi ìdáhùn rẹ̀ falẹ̀.
À ń gbé ní ìgbà tí a nílò àṣàrò tó jinlẹ̀, ìbárẹ́ tó jinlẹ̀ àti ìbásopọ̀ tó jinlẹ̀ pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó jẹ́ òtítọ́. A jẹ́ ìran tí ati gba ìyàlẹ́nu rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni lọ̀pọ̀ ìgbà a kìí ní ju ìlépa òfìfo, tí wọ́n ti dà kiri nínú odòo irọ́-bí-òtítọ́.
Ṣùgbọ́n ojúlówó òtítọ́ kìí ṣe odò, àpáta niíṣe.
Láàrín gbogbo ìpòrúru àti àfiwé yìí, a ní láti kojú sí Jésù. Òhun ni àpáta wa, ìtára wa; tí kò ṣeé gbé, tí kò ṣeé mì. A pè wá láti fi ayée wa sínúu rẹ̀- kìí ṣe lára Rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ní inúu rẹ̀-gẹ́gẹ́ bíi ìpìlẹ̀ wa tíó dúró ṣinṣin. Òhun nìkan ni ìdánilójú ṣinṣin nínú ayé tó kún fún òkúta.
Nígbà tí a bá ṣe eléyìí, Ó ma jẹ́kí a dúró ṣinṣin, gẹ́lẹ́ bíi Rẹ̀. Òhun ni òkúta igunlé, ṣùgbọ́n àwa pẹ̀lú jẹ́ òkúta ààyè, tí a kọ́pọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ sínúu ilé-ẹ̀mí tíó sì jẹ́ orígun àti ilé-àbò fún gbogbo àwọn tí ayé yìí ti gbò gidigidi.
Èyí wà lára ìpè wa gẹ́gẹ́ bíi Krìstẹ́nì-láti dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, kìí ṣe fún ara wa nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn tó ń wá ǹkan tí wọ́n lè kọ́ ìgbésí ayé wọn lé lórí.
Kíni ó túmọ̀ sí fún ọ wípé Jésù ni Àpáta? Kíni àwọn ọ̀nà tí òtítọ́ ti di yẹpẹrẹ nínú ayéè rẹ?.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Kíni òtítọ́? Àṣà ń gba irọ́ náà wọlé pé òtítọ́ jẹ́ odò, tó ńru tó sì ń ṣàn lọ pẹ̀lú àkókò. Ṣùgbọ́n òtítọ́ kìí ṣe odò-àpáta ni. Nínú rírú-omi òkun àwọn èrò tó fẹ́ bòwá mọ́lẹ̀, ètò yìí yóò rán ìdákọ̀ró-okàn wa lọ́wọ́ láti lè múlẹ̀-yóò sì fún ọ ní ìtọ́sọ́nà tó yanjú nínú rúkè-rúdò ayé.
More