Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Fún Gbogbo ÀìníÀpẹrẹ
ÌFẸ́RẸ́RẸ̀ TÓ WÉRÉ
"Bàbá nífẹ̀ẹ́ rẹ"
Ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn kó tó kú, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé Baba òun nífẹ̀ẹ́ wọn. Ọ̀rọ̀ náà "ìfẹ́" tá a lò níhìn-ín kò túmọ̀ sí pé kéèyàn kàn máa ṣe ohun tó wù ú tàbí kéèyàn máa fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Ọlọ́run. Ó ní ìtumọ̀ "ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí a fi hàn" ìfẹ́ tó kún fún ìyọ́nú tí a sì fi hàn ní gbangba. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká lóye èyí. Ìfẹ́ tí Bàbá ní sí wa kì í ṣe ìfẹ́ àtọkànwá. Rárá o, ohun tí ọ̀rọ̀ Jésù túmọ̀ sí níbí yìí ni pé "Baba nífẹ̀ẹ́ yín gan-an, ó nífẹ̀ẹ́ yín gidigidi, ó sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ yín". Ìfẹ́ ńlá mà lèyí o! Ọ̀pọ̀ bàbá tó jẹ́ èèyàn ni kì í fi bẹ́ẹ̀ sí lọ́dọ̀ wọn, yálà nípa tara tàbí nípa tẹ̀mí. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀ràn Baba wa ọ̀run; nígbà tí Jésù kú tó sì jíǹde, ó gòkè re ọ̀run, ó sì tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ibẹ̀. Ó kún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ pẹ̀lú Ẹ̀mí ìsọdọmọ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde pé "Baba! Láti ìgbà náà lọ, wọ́n mọ̀ pé Bàbá nífẹ̀ẹ́ wọn pẹ̀lú ìfẹ́ tí ó hàn kedere, pẹ̀lú àwọn apá ìfẹ́ Rẹ̀ tí ó lágbára tí ó sì ń tù wọ́n nínú. Ohun tí Jésù fẹ́ fún àwa náà nìyẹn. Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀ ẹ́ kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti mọ èyí nínú ọkàn wa, kì í ṣe nínú orí wa nìkan. Ẹ jẹ́ ká rí bí Baba wa ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wa.
ADURA
Jesu Oluwa mi, mo bèèrè fún ọ láti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè mọ̀ nínú ọkàn mi pé Baba fúnra rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ mi jinlẹ̀jinlẹ̀, lọ́nà tó ṣe kedere. Ní orúkọ rẹ. Àmín.
Learn more at Destiny Image Publishers, or learn more about the book at Amazon or Barnes and Noble.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Gbígbé inú ayé lè lé, nígbàti ó bá sì d'ojúkọ àwọn ìṣòro tí o sì níílò ìmúlọ́kànle, ibi tí ó dára jù láti lọ ní inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣúgbọ́n a máa ṣòro ní ìgbà míràn láti mọ ibi tí kí a yí sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Fún Gbogbo Àìní ṣe àmúlò àwọn ẹsẹ ìwé-mímọ́ tí ó ṣe pàtàkì fún gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ náà láti ṣe àwárí wọn ní àsìkò hílàhílo ilé-ayé. Da ara dé Ọlọ́run láti ràn ọ́ lọ́wọ́ la àkókò ìṣòro kọjá.
More