Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Fún Gbogbo ÀìníÀpẹrẹ

God's Word For Every Need

Ọjọ́ 2 nínú 5

ÌDÁNIMỌ̀ WA TÒÓTỌ́

"Ẹ̀yin yíò jẹ́ ọ̀dọ́-mọkùnrin àti ọ̀dọ́-mọbìnrin mi"

Gbogbo bàbá rere fẹ́ ohun tí ó dára fún àwọn ọmọ wọn. Nínú ìfọkànsìn tí ìṣáájú a rí apá kan nínú ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún wa: "Èmi yíò jẹ Baba fún yín. "Èyí ni ó ti jẹ ètò Rẹ̀ kí a tó fi ìpilẹ̀ ayé lélẹ̀. Ṣùgbọ́n kò tán síbẹ̀. Kí ì ṣe pé Ọlọ́run fẹ kí a mọ ìdánimọ̀ Rẹ̀ gidi nìkan; Ó fẹ́ kí àwa náà mọ ohun tí ó jẹ́ ìdánimọ̀ wa tòótọ́ pẹ̀lú. Bí Òun bá jẹ Bàbá wa, kíni ìyẹn ṣọ wá da? Bí a bá yàn láti tẹ̀lẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, èyí sọ wá di àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Rẹ̀. Eléyìí jẹ ayọ̀ tí ó tóbi julọ nínú gbogbo rẹ—láti mọ̀ pé Ọlọ́run ni Bàbá tí a tí ń retí, àti láti ṣ'ayọ̀ nínú àǹfààní wípé a di ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Rẹ̀ nípa ìsọdọmọ. Eléyìí ni ìrètí Rẹ̀ fún ìgbésí ayé wa. Ẹ jẹ́ kí a mú bíi àfojúsùn wá ti o ga julọ láti wọ inú ohun tí ó túmọ̀ sí ní kíkún láti jẹ àwọn ọmọkùnrin àti omobinrin ẹni tí ó ju gbogbo Bàbá lọ. Ẹ jẹ́ kí ó jẹ́ àfojúsùn ìgbé ayé wa làti jẹ́ ọmọkùnrin tí ó dára julọ àti ọmọbìnrin tí ó dára julọ tí a lè jẹ́ sì Bàbá wa tí ń bẹ ni Ọ̀run. Eléyìí ni ohun tí ó wá ní ọkàn Bàbá wa fún ìgbé ayé wa. Ẹ jẹ́ kí a jẹ́ kí o jẹ èrò ọkàn wa pẹ̀lú!

ÀDÚRÀ

Bàbá mi ọ̀wọ́n, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ pé Ó pè mí láti di ọmọ Rẹ̀ nípa ìsọdọmọ. Ràn mí lọ́wọ́ láti lè mú ìdánimọ̀ mi dúró lórí ìyanu ọlá ńlá yí. Ní orúkọ Jésù. Àmín.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

God's Word For Every Need

Gbígbé inú ayé lè lé, nígbàti ó bá sì d'ojúkọ àwọn ìṣòro tí o sì níílò ìmúlọ́kànle, ibi tí ó dára jù láti lọ ní inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣúgbọ́n a máa ṣòro ní ìgbà míràn láti mọ ibi tí kí a yí sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Fún Gbogbo Àìní ṣe àmúlò àwọn ẹsẹ ìwé-mímọ́ tí ó ṣe pàtàkì fún gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ náà láti ṣe àwárí wọn ní àsìkò hílàhílo ilé-ayé. Da ara dé Ọlọ́run láti ràn ọ́ lọ́wọ́ la àkókò ìṣòro kọjá.

More

A fẹ́ láti dúpẹ lọ́wọ́ Destiny Image Publishers fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú sí jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sì: http://www.destinyimage.com