Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Fún Gbogbo ÀìníÀpẹrẹ

God's Word For Every Need

Ọjọ́ 4 nínú 5

ÀWỌN ỌMỌ ỌLỌ́RUN

Ẹ wò ó ná, ọmọ Ọlọ́run ni a pè wá!

Nínú ẹ̀kọ́-ìfọkànsìn tí ó ṣáájú a rí i pé Ọlọ́run ni Baba tí ó fi ìfẹ́ àgbàyanu Rẹ̀ hàn sí wa. Lẹ́yìn tí Àpọ́sítélì Jòhánù ti tẹnu mọ́ kókó yìí, ó rán wa létí pé bí á bá yàn láti tẹ̀lé Jésù, a ó pè wá ní "ọmọ Ọlọ́run." Irú ẹni tí a jẹ́ gan-an nìyí. Èyí gan-an ìdánimọ̀ wa nítòótọ́. Kì í ṣe iṣẹ́ tí à ń ṣe ní ó ń fi irú ẹni tí a jẹ́ hàn. Iyì wa kò sí nínú ohun tí a bá gbé ṣe. Rárá o, ìdánimọ̀ wa dá lé orí ohun tí ó pẹ́ títí, tí ó sì dájú. Ìpìlẹ̀ wo ni ó dára ju ìfihàn pàtàkí ti Májẹ̀mú Titun lọ—pé àwọn tí ó mọ Jésù ni a sọ dí ọmọkùnrin àti ọmọbìrin Baba? Ṣé bí o ṣe rí ara rẹ nìyìí? Bí kò bá rì bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí n rọ̀ ọ́ pé kí o gbé ìdánimọ̀ ara rẹ ka orí òtítọ́ yìí. Jẹ́ kí n gbà ọ́ ní ìyànjú láti ṣe ohun tí Àpọ́sítélì Jòhánù sọ níbí yìí kí o sì "wòó wò." Ronú nípa òtítọ́ yìí, ṣe àṣàrò lé e lórí, kí o sì gbádùn rẹ̀. Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá ní ìdánilójú tí o lágbára ní gbogbo ìgbà pé ààbò rẹ wà nínú ipò rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run, kìí ṣe nínú iṣẹ́ rẹ.

ÀDÚRÀ

Baba ọ̀wọ́n júlọ, mo fẹ́ fi ìyìn fún Ọ pé Ọ fẹ́ràn mi fún ẹni tí mo jẹ́—ọmọ Ọlọ́run. O ṣeun fún ọlá yìí. Ní orúkọ Jésù. Àmín.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

God's Word For Every Need

Gbígbé inú ayé lè lé, nígbàti ó bá sì d'ojúkọ àwọn ìṣòro tí o sì níílò ìmúlọ́kànle, ibi tí ó dára jù láti lọ ní inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣúgbọ́n a máa ṣòro ní ìgbà míràn láti mọ ibi tí kí a yí sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Fún Gbogbo Àìní ṣe àmúlò àwọn ẹsẹ ìwé-mímọ́ tí ó ṣe pàtàkì fún gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ náà láti ṣe àwárí wọn ní àsìkò hílàhílo ilé-ayé. Da ara dé Ọlọ́run láti ràn ọ́ lọ́wọ́ la àkókò ìṣòro kọjá.

More

A fẹ́ láti dúpẹ lọ́wọ́ Destiny Image Publishers fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú sí jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sì: http://www.destinyimage.com