Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Fún Gbogbo ÀìníÀpẹrẹ

God's Word For Every Need

Ọjọ́ 1 nínú 5

ÌPÈ TI Ọ̀RUN

“Èmi yíó jẹ́ Baba fún ọ’.”

Ẹsẹ wó ló ṣe pàtàkì jú nínú Bíbélì? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní yíó dáhún wípé, “Jòhánú 3:16: Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Ó fi Ọmọ bíbí Rẹ kanṣoṣo fún ni.” Ẹ̀wẹ̀, ẹsẹ yìí láti inú ìwé kejì Pọ́ọ̀lù sí ìjọ sí Kọ́ríntì náà lè fi ọwọ́ ẹ̀ s'ọ̀yà bẹ́ẹ̀. Ní ọ̀nà kan, gbogbo ètò àti ète Ọlọ́run ní a lè kó pọ̀ sínú ọ̀rọ̀ yìí, “Èmi yíó jẹ́ Baba fún ọ.” Ètò Ọlọ́run ní èyí láti ìgbà tí Ádámú àti Éfà ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ọgbà Édẹ́nì. Ní ìgbà tí èyí ṣẹlẹ̀, a ya ènìyàn ní ipa kúrò nínú ìfẹ́ Baba. Ohun tí èyí já sí ní wípé a dí ọmọ òrukàn tí ẹ̀mí—a kò lè bá Ọlọ́run ṣe mọ́ gẹ́gẹ́ bíi Bàbá wa. Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Jésù, gbogbo èyí ló ti yí padà! Jésù ní ìdáhùn sí ipò ọmọ òrukàn tí a wà. Ó wá sí ayé yìí láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa àti láti rà wá padà sí inú ẹ̀bí Baba ní orí ilẹ̀ ayé. Ní báyìí a lè pe Ọlọ́run ní “Baba” kí a sì sinmi lé apá ìfẹ́ Rẹ̀. Nínú ìwé àyọkà ìfọkànsìn yìí, Jésù ń pè wá láti dáhùn sí àwọn ọ̀rọ̀ ayérayé yìí: “Èmi yíó jẹ́ Baba fún ọ.”

ÀDÚRÀ

O ṣeun, Ọlọ́run fún ìpè tí O pè láti mọ̀ Ọ́ gẹ́gẹ́ bí Baba. Pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, mo ní “Bẹ́ẹ̀ni,” bí mo ti ń bẹ̀rẹ̀ àwọn àyọkà ìfọkànsìn yìí. Ní orúkọ Jésù. Àmín.

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i ní Destiny Image Publishers, tàbí mọ̀ sí í nípa ìwé náà ní Amazon or Barnes and Noble.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

God's Word For Every Need

Gbígbé inú ayé lè lé, nígbàti ó bá sì d'ojúkọ àwọn ìṣòro tí o sì níílò ìmúlọ́kànle, ibi tí ó dára jù láti lọ ní inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣúgbọ́n a máa ṣòro ní ìgbà míràn láti mọ ibi tí kí a yí sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Fún Gbogbo Àìní ṣe àmúlò àwọn ẹsẹ ìwé-mímọ́ tí ó ṣe pàtàkì fún gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ náà láti ṣe àwárí wọn ní àsìkò hílàhílo ilé-ayé. Da ara dé Ọlọ́run láti ràn ọ́ lọ́wọ́ la àkókò ìṣòro kọjá.

More

A fẹ́ láti dúpẹ lọ́wọ́ Destiny Image Publishers fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú sí jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sì: http://www.destinyimage.com