Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Fún Gbogbo ÀìníÀpẹrẹ

God's Word For Every Need

Ọjọ́ 3 nínú 5

ÌFẸ́ TÓ GA JU GBOGBO ÌFẸ́

Irú ìfẹ́ àgbàyanu tí Bàbá fi ṣe ọwọ síwa!

Kò sí ayọ̀ ní ayé tí ó ju mímọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ Bàbá tí ó ní ìfẹ́ wa, Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan àwọn tó wà nínú ìjọ, kò tíì ní irú ayọ̀ tí kò ṣeé fẹnu sọ yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn bàba wọn ti orí ilẹ̀ ayé ti ṣe léṣe, nítorí náà, wọ́n gbé ìrírí won nípa jíjẹ́ bàbá fún Ọlọ́run baba. Wọ́n á wá dá Ọlọ́run ní àwòrán bàbá wọn ti orí ilẹ̀ ayé—wíwo Ọlọ́run bí òbí tí kò sí nítòsí tàbí òbí tí kò bìkítà. Àwọn kan ní àwòrán Ọlọ́run bíi Bàbá tí ó jìnà sí wọn tí ó sì máa ń gba ẹ̀san. Kò sí èyí tí ó jẹ́ ìfiwéra tí ó péye fún àwòrán tí Jésù ń yà. Jésù wá láti ṣe ìfihàn ìfẹ́ àgbàyanu ti Bàbá. Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ni Ọba. Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ni Olúwa. Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ni Onídàájọ́. Ṣùgbọ́n ní pàtàkì, òun ni bàbá tí ó ní ìfẹ̀ ayé tí ó jẹ́ ọmọ òrukàn yìí gan-an débi pé ó rán ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo láti sọ àwọn ẹrú di ọmọ àti àwọn ọmọ òrukàn di alájogún. Èyí jẹ́ Ìbùkún tó ga jù lọ—láti mọ̀ pé Ọlọ́run ni Bàbá tó ga jù lọ láyé. Bí ìwọ bá ti ṣe àìní bàbá rere ní ayé, mọ èyí: ìwọ́ ní Bàbá tí ó péye ní ọ̀run ó sì ti na owọ́ ìfẹ́ àgbàyanu rẹ̀ sí o nínúu Jésù.

ÀDÚRÀ

Bàbá modúpẹ́ wípé O jìnà ṣùgbọ́n O jẹ́ alábasẹ. Ràn mí lọ́wọ́ láti gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ẹ bímo ti ń ka àwọn ìfọkànsìn wọ̀nyí. Ní orúkọ Jésù. Àmín .

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

God's Word For Every Need

Gbígbé inú ayé lè lé, nígbàti ó bá sì d'ojúkọ àwọn ìṣòro tí o sì níílò ìmúlọ́kànle, ibi tí ó dára jù láti lọ ní inú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣúgbọ́n a máa ṣòro ní ìgbà míràn láti mọ ibi tí kí a yí sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Fún Gbogbo Àìní ṣe àmúlò àwọn ẹsẹ ìwé-mímọ́ tí ó ṣe pàtàkì fún gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ náà láti ṣe àwárí wọn ní àsìkò hílàhílo ilé-ayé. Da ara dé Ọlọ́run láti ràn ọ́ lọ́wọ́ la àkókò ìṣòro kọjá.

More

A fẹ́ láti dúpẹ lọ́wọ́ Destiny Image Publishers fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú sí jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sì: http://www.destinyimage.com