Ọjọ́ Mẹ́fà lóríi Orúkọ Ọlọ́runÀpẹrẹ

Six Days Of The Names Of God

Ọjọ́ 6 nínú 6

Ọjọ́ Kẹfà: EL SIMCHATH GILI – ỌLỌ́RUN Ẹ̀KÚNRẸ́RẸ́ AYỌ̀ MI

Ronú ayọ̀ tó kún ọkàn rẹ nígbàtí ó oun kan ṣe dájúdájú fún ìgbà àkọ́kọ́. Bóyá o tilẹ̀ kọ́ èdè titun kan dáadáa tó bẹ́ẹ̀ tí o fi le bá àwọn elédè sọ̀rọ̀ bíi wọn nílùú òmíràn. Tàbí ò ún lọ láti máyìlì kan sí èyí tó tele títí o fi parí eré ìje ọlọ́nà jíjìn. Yálà o tin ń gbìyànjú lọ́dún pípẹ́ láti gba oyè ilè ẹ̀kọ́ gíga, nígbẹ̀yìn o rìn kọjá lati gba ẹ̀rí ìkẹko jáde. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmọ̀lára ní yíò oó fò kiri ní ọkàn re, èyí tí ayọ̀ ṣáájú gbogbo wọn.

Oun dídára gbogbo ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, Òun sì ma ń ṣògo nínú oun gbogbo tó dára. Òun nìkan ni orísun ayọ̀, tí a bá sì fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Rẹ̀, a lè ni ayọ̀ nínú ohunkóhun tí à ń là kọjá. A leè ní ayọ̀ nínú ìlàkàkà, tí a bá fi ìrètí wa sínú Olúwa.

Àṣìṣe wa ni ọ̀pọ̀ ìgbà ni pé a máa ń wá ayọ̀ láì fi ti Ọlọ́run ṣe. Nígbàtí tí a bá díwọ̀n ara wa nínú àsọjẹ ẹlòmíràn nípa wa tàbí iye owó oṣù wa tàbí ipò wa láwùjọ, a ó pàdánù ayọ̀ tòótọ́. A ó pàdánù ayọ̀ nínú ìrìn àjò náà, ayọ̀ àwárí, ayọ̀ ọkàn tó ṣí sí Ọlọ́run. Bákannáà ni à ń pàdánù àǹfààní tó làpẹẹrẹ láti ayọ̀ Olúwa pẹ̀lú àwọn míràn. Ṣùgbọ́n nígbàtí a bá kún fún ayọ̀ tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, a ó máa bì fún ìfẹ́ àti adùn sí àwọn tó yi wa ká a ó sì mọ ayọ̀ tòótọ́.

Tí o bá ríi pé ètò wíwá ojú Ọlọ́run yí ni túmọ̀, a ṣe tán láti fún ọ ní ìwàásù àká sílẹ̀ tó dá lórí orúkọ Jehovah Jireh. Bèèrè fún ẹkùn rẹ́rẹ́ ìwàásù láti ọwọ́ Tony Evans níbí

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Six Days Of The Names Of God

Láti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orukọ Ọlọ́run, Ó ti fi àwòrán dí ẹ̀ hàn wá bí Òun ṣe jẹ́ àti àbùdá Rẹ̀. Ju ìwọ̀n Baba, Ọmọ, Ẹ̀mí Mímọ́ lọ, Bíbélì fi ọgọ́rin ó lé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ orúkọ Ọlọ́run hàn. Ẹ̀kọ́ yìí ṣe ìtọ́ka sí mẹ́fà àti ìtumọ̀ wọn láti ran onígbàgbọ́ lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run Olóòtítọ́ kan ṣoṣo. Àyọkà láti inu ìwé tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́, Experience the Power of God's Names: A Life-Giving Devotional (Níní Ìrírí Agbára Orúkọ Ọlọ́run: Ẹ̀kọ́ Wíwá Ojú Ọlọ́run ti n Fún ni Ní Ìyè), làti ọwọ́ Ọmọwé Tony Evans. Eugene, tàbí: Harvest House Publishers, 2017.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́, The Urban Alternative àti Tony Evans fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://tonyevans.org/

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ