Ọjọ́ Mẹ́fà lóríi Orúkọ Ọlọ́runÀpẹrẹ
Ọjọ kẹta: Jehovah Jireh – Olupese ní Olúwa
Kòsí ìdánilójú fún ọ ibití owó tí ó máà fí ṣe awọn ìnáwó ti ó dojukọ ọ ní oṣù yí yíò tí wá. Ipò tí ìbáṣepọ̀ rẹ wà pẹlu awọn míràn kò fí bẹẹ dọ́mọ́rán. Bẹẹ o sí tún tí gbọ pé ètò láti dá àwọn oṣiṣẹ silẹ níbi iṣẹ rẹ nbọ lọnà dẹdẹ, àti pé àyè tí ó wà níbí iṣẹ rẹ kò fí ẹsẹ múlẹ̀ daradara. Nígbàtí àwọn ohun tí ó jẹ ìpìlẹ ìgbé ayé wá dúró lé lórí bá dojúrú- bí ìlera, ètò ìnáwó, ibùgbé, ounjẹ, ìdílé, àti iṣẹ - eléyi jẹ ohun tí ó lè mú ìpayà wá, á sí dàbí ẹni pé a tí sunmọ ògiri. Irú àsìkò bayi ní á níláti ké pé Jehovah Jireh. Orúkọ Ọlọrun Olubukun yí túmọ sí "Olúwa yóò pèsè", ó jẹ orúkọ tí ó kún fún agbára àti ipá.
Nígbàtí ẹrù bá wà ní ọkàn wa nítorí ọjọ ọla wa, ó dì dandan fúnwa láti yípadà sí Ọlọrun kí a sì ké pé orúkọ Rẹ. Gbogbo ẹbùn rere àti pípé ọdọ Rẹ̀ ní o tí ńwá, kòsí sí òpin fún àwọn ẹbùn àti ìbùkún tí ó ńpese fúnwa. Nipa níní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ lè jẹ́ ọnà kanṣoṣo láti fi wá lọkàn balẹ kí èrò rere sí sọ síwa lọkàn
Eléyi lè jẹ́ ẹkọ tí ó lè láti kọ, ṣugbọn awọn àdánwò tí ó ńdojúkọwá níhìn yí á máà fún iṣan ẹ̀mí wa ní agbára, á sí máà mú wa sunmọ Ọlọrun. Nípasẹ̀ ìtiraka wa, Ó fí hàn wa kedere bí afẹfẹ ṣe ńwọ̀ inú ẹ̀dọ̀fóró wa láti jẹ kí a lè mi àti imọlẹ fún ojú wa láti ríran. Ó máà ńfún wa ní ohun tí á nilo ní pàtó láti mú ìdàgbàsókè tí ó tayọ bá wa àti láti mú ipa tí ó ga jùlọ dé bá ìjọba Rẹ. Òun a sì máà fí fún wa nípa ẹ̀mí ìfẹ.
Nípa Ìpèsè yìí
Láti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orukọ Ọlọ́run, Ó ti fi àwòrán dí ẹ̀ hàn wá bí Òun ṣe jẹ́ àti àbùdá Rẹ̀. Ju ìwọ̀n Baba, Ọmọ, Ẹ̀mí Mímọ́ lọ, Bíbélì fi ọgọ́rin ó lé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ orúkọ Ọlọ́run hàn. Ẹ̀kọ́ yìí ṣe ìtọ́ka sí mẹ́fà àti ìtumọ̀ wọn láti ran onígbàgbọ́ lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run Olóòtítọ́ kan ṣoṣo. Àyọkà láti inu ìwé tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́, Experience the Power of God's Names: A Life-Giving Devotional (Níní Ìrírí Agbára Orúkọ Ọlọ́run: Ẹ̀kọ́ Wíwá Ojú Ọlọ́run ti n Fún ni Ní Ìyè), làti ọwọ́ Ọmọwé Tony Evans. Eugene, tàbí: Harvest House Publishers, 2017.
More