Ọjọ́ Mẹ́fà lóríi Orúkọ Ọlọ́runÀpẹrẹ

Six Days Of The Names Of God

Ọjọ́ 4 nínú 6

Ọjọ kẹrin: ESH OKLAH – INÁ AJÓNIRUN

Njẹ ó tí rí ìparun tí iná igbó tí mú wá rí? Ohun gbogbo tí o wà ní ipa ọna rẹ ní ó máà ń jó gúruguru, á sí máà ré fò ọna, afárá, àti odò pàápàá kọjá sí òdìkejì wọn. Nisisiyi fí ojú inú wò iná nlá tí ó tóbi jù àgbànlá ayé lọ, àtipé iwọ yóò wá ní àǹfààní láti mọ bí agbára Ọlọrun ṣe tó.

A gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún agbára Ọlọrun tí ó tóbi lọpọlọpọ, ṣugbọn á tún ní láti rántí pé O jẹ Ọlọrun ẹnikọọkan tí ó sí bìkíta fúnwa ní gbogbo ọnà. Àtipé nítorí èyí Ó jẹ́ Ọlọ́run tí á ní láti máà fí ìyìn àti ìjọsìn dá lọ́lá nígbà gbogbo. A kò gbọdọ̀ fí ọwọ yẹpẹrẹ mú U, ṣugbọn ní bákan náà á kò gbọdọ bẹrù láti kígbe pé kí a sì wà ní ìbáṣepọ̀ tí ó dọ́nmọ́rán pẹlú Rẹ̀.

Títóbi Ọlọrun lè ṣòro diẹ láti gbé lé ìṣirò, gẹgẹbi àkíyèsí Rẹ̀ sí ohun tí ó kéré jù ní ìgbé ayé wa. Báwo ní ẹ̀dá alágbára ńlá bayi ṣe lè ṣàníyàn tó bẹ́ẹ̀ lóríi àwọn ohun tí ó dàbí pé àwọn nkán tí á kò nàani ní ìgbésí ayé wa? Ìdí nipé O fẹ́ràn wa dénú dénú. Ìdí nìyí tí a fi gbọ́dọ̀ gba iná Rẹ̀ láàyè láti máà jó lóókan àyà wa.

Òun ní Esh Oklah-, iná ajónirun, ṣùgbọ́n iná tí ó kún fún ore-ọ̀fẹ́, sùúrù àti ìkáàánú ni. A máa fà wa mọra sí ọdọ Rẹ̀ pẹlu àfojúsùn wípé a máa fi Òhun ṣe ìṣáájú nínú ọkàn, èrò, àti ìṣẹ̀dá wa. Àti wípé láàrín iná, A máa ìfẹ́ gbilẹ̀ si ní oókan àyà wa.

Ìwé mímọ́

Day 3Day 5

Nípa Ìpèsè yìí

Six Days Of The Names Of God

Láti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orukọ Ọlọ́run, Ó ti fi àwòrán dí ẹ̀ hàn wá bí Òun ṣe jẹ́ àti àbùdá Rẹ̀. Ju ìwọ̀n Baba, Ọmọ, Ẹ̀mí Mímọ́ lọ, Bíbélì fi ọgọ́rin ó lé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ orúkọ Ọlọ́run hàn. Ẹ̀kọ́ yìí ṣe ìtọ́ka sí mẹ́fà àti ìtumọ̀ wọn láti ran onígbàgbọ́ lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run Olóòtítọ́ kan ṣoṣo. Àyọkà láti inu ìwé tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́, Experience the Power of God's Names: A Life-Giving Devotional (Níní Ìrírí Agbára Orúkọ Ọlọ́run: Ẹ̀kọ́ Wíwá Ojú Ọlọ́run ti n Fún ni Ní Ìyè), làti ọwọ́ Ọmọwé Tony Evans. Eugene, tàbí: Harvest House Publishers, 2017.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́, The Urban Alternative àti Tony Evans fún ìpèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí https://tonyevans.org/

Awọn Ètò tó Jẹmọ́ọ