Ọjọ́ Mẹ́fà lóríi Orúkọ Ọlọ́runÀpẹrẹ
![Six Days Of The Names Of God](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F8726%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Ọjọ́ 5: ELOHE TSADEKI – ỌLỌ́RUN ÒDODO MI
Gbogbo ìgbà ni a má ń ṣàfẹ́rí nnkan ńlá tó kàn láyé wa. Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò ayé ẹni. Kọ́kọ́rọ́ bí ara wa ṣe lè pé síi. Ọ̀nà tí kò l'ẹ́ja n bákàn tí ìsúná wa yó fi dúró ṣinṣin. A máa ń ka ìwé, à ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìṣítí nínú fọ́nrán tí a ká sílẹ̀ a sì tún máa ń forúkọ sílẹ̀ láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé tó létò, ara tó pé àti ètò ìṣúná tó dúró ṣinṣin ṣe pàtàkì láti fọkàn sí, a nílò láti ríi dájú pé a f'iyè sí ohun tí yó jẹ́ àbáyọrí gbogbo wọn lákóòpọ̀ bí a ṣe ń ṣàfẹ́rí ohun nnla tó kàn tí yó ṣẹlẹ̀ nínú ayé wa..
Ìdí pàtàkì ayé wa ni láti tẹ̀lé Ọlọ́run, kí á dàbíi Rẹ̀ kí ìgbé ayé wa sì wà fún Un. Dídàbí Ọlọ́run túmọ̀ sí pé kí á dàgbà nínú oore àti nínú òdodo. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni àánú, oore ọ̀fẹ́, ipa àti agbara ti ń ṣàn wá—a sì nílò àwọn àmúyẹ yì nínú aye wa. Láti inú Ọ̀rọ̀ àti È̩mí Rẹ̀, Ọlọ́run ń fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò láti gbé ayé tó kún fún ayọ̀. Nígbà tí a bá gbé ìfẹ́ Rẹ̀ lékè tiwa, tí a sì ń làkàkà láti dàbí Rẹ̀, á máa tọ́ wa sọ́nà á sì máa darí wa.
Títẹ̀lé ètò Ọlọ́run lè má rọrùn bíi ìgbà tí a bá fún wa ní ìgbésẹ mẹ́fà tó rọrùn láti mu kí ara le síi tàbí ọ̀nà mẹ́wà tí a fi lè tún ilé wa tò. Ṣùgbọ́n èrè rẹ̀ pọ̀. Nígbà tí a bá yí padà si Ọlọ́run tí a sì fi ayé wa lé E lọ́wọ́, yóò dáríjì wá yóò fún wa ní ẹ̀bùn àánú Rẹ̀. Yóò ràn wá lọ́wọ́ láti tún àwọn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ènìyàn ṣe, yóò sì fi òdodo, oore ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà kún ọkàn wa. Títẹ̀lé Ọlọ́run àti gbígba òdodo Rẹ̀ láàyè láti tọ́ ìṣíṣẹ̀ wa máa ń mú èso réré jáde.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
![Six Days Of The Names Of God](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fyvplans%2F8726%2F1280x720.jpg&w=3840&q=75)
Láti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orukọ Ọlọ́run, Ó ti fi àwòrán dí ẹ̀ hàn wá bí Òun ṣe jẹ́ àti àbùdá Rẹ̀. Ju ìwọ̀n Baba, Ọmọ, Ẹ̀mí Mímọ́ lọ, Bíbélì fi ọgọ́rin ó lé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ orúkọ Ọlọ́run hàn. Ẹ̀kọ́ yìí ṣe ìtọ́ka sí mẹ́fà àti ìtumọ̀ wọn láti ran onígbàgbọ́ lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run Olóòtítọ́ kan ṣoṣo. Àyọkà láti inu ìwé tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́, Experience the Power of God's Names: A Life-Giving Devotional (Níní Ìrírí Agbára Orúkọ Ọlọ́run: Ẹ̀kọ́ Wíwá Ojú Ọlọ́run ti n Fún ni Ní Ìyè), làti ọwọ́ Ọmọwé Tony Evans. Eugene, tàbí: Harvest House Publishers, 2017.
More