Àwọn Ará KólósèÀpẹrẹ

Àwọn Ará Kólósè

Ọjọ́ 4 nínú 4

Paulu àpọ́sítélì parí ìwé kíkọ rẹ̀ sí àwọn ará Kólósè pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ láti tẹnu mọ́ àwọn kókó mẹ́ta tó ti mẹ́nu bà tẹ́lẹ̀

Ní ẹsẹ díè sẹ́yìn Paulu rọ àwọn ẹrú/òṣìṣẹ́ láti ṣiṣẹ́sìn tọkàntọkàn bí ẹni pé wọ́n ń sin Jésù. Ó sì tún sọ fun àwọn agbanisíṣẹ́ náà pé ẹrú/òṣìṣẹ́ ni àwọn náà jẹ́ sí Olúwa wọn, ìyẹn Ọlọ́run. Nítorí náà Paulu ṣàfihàn alábáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ Tychicus àti ẹrú tó sá tó ń jẹ Onesimus. Àwọn ìjọ Kólósè pàdé ni ilé olúwa Onesimus, wọ́n sì mọ̀ pé Omesimus ti sá lọ rí. Síbẹ̀síbẹ̀, Paulu ni ki ìjọ gba Onesimus padà sí àárín wọn, bí Onesimus náà ṣe ṣe tán láti padà bíi ẹrú/òṣìṣẹ́. Nínú ìfáárà yìí, Paulu gbìn ín sọ́kàn ìjọ Kólósè láti ló ìfẹ́ bíi ọmọ-ìyá nínú ìbáṣepọ̀ yòówù ju pé kí wọ́n máa lépa àtigbẹ̀san lọ.

Ṣáájú, Paulu gbìyànjú lọ́pọ̀lọpọ̀ láti fihán pé kò sí ọ̀nà Júù tàbí ti Kèfèrí láti tẹ Ọlọ́run lọ́rùn. Gbogbo ènìyàn ló wà ní ìṣọ̀kan bíi ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, gbogbo ènìyàn sì ni Jésù nìkan gbàlà. Nítorí náà Paulu dárúkọ Júù mẹ́ta àti gíríìkì mẹ́ta tí wọ́ jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ ìkíni wọn síbẹ̀. Orúkọ àwọn mẹ́fà yìí ń rán àwọn ará Kólósè létí pé wọ́n wà nínú ètò Jésù láti jẹ́kí gbogbo ènìyàn wà ní ìṣọ̀kan nínú ìgbàlà rẹ̀.

Nínu ìwé tí Paulu kọ láti ìbẹ̀rè é òpin Paulu tenu mọ́ ìdí tí àwọn ara Kólósè ṣe nílò láti dàgbà sí i nínú ẹ̀kọ́ Jésù. Nípa wíwalẹ̀jìn nínú ẹ̀kọ́ Jésù, Paulu mọ̀ pé àwọn ará Kólósè ó ní ìrísí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run tí wọn ó sì gbé ìgbé ayé tó ṣàfihàn Jésù. Nítorí náà, Paulu dárúkọ Epaphras, olùdásílẹ̀ ìjọ Kólósè. Epaphras rin lọ bá Paulu ní túbú, láti lọ gbà á ní ìyànjú àti láti lọ gba àmọ̀ràn nípa ìjọ rẹ̀. Ní àkókò yìí, Paulu rí ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Epaphras ní sí àwọn ará Kólósè, àti bí ó ṣe gbàdúrà pé kí wọ́n dàgbà sí i nínú ifarajìn wọn fún Jésù. Gẹ́gẹ́ bíi àpọ́sítélì, Paulu pín ojúṣe yìí. Mímẹ́nu bá àdúrà Epaphras fún ìdàgbàsókè yìí jé ọ̀nà gbòógì láti parí ìwé - kíkọ rẹ̀ àti láti rán àwọn ará Kólósè létí bí o ṣe ṣe pàtàkì sí fún wọn láti walẹ̀jìn nínú òtítọ́ àti ìgbé ayé tí Jésù.

Ọmọlẹ́yìn Jésù tó ti dàgbà nínú èmi Jésù nìkan ló gba òun là, yo sì ní ìfẹ́ ìfararúbọfúnni kódà nígbà tó ní ẹ̀tọ́ láti gbẹ̀san. Àwọn ẹ̀kọ́ yìí nira láti mú lò, ṣùgbọ́n ìwé Kólósè parí pẹ̀lú ìrètí - ìrètí pé ó ṣeé ṣe láti dàgbà sí i bii ọmọlẹ́yìn Jésù.

A lè nírètí láti dàgbà sí i nínú ìwà bíi Ọlọ́run nítorí ohun gbogbo tí Paulu ti kọ ṣáájú àwọn ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ yìí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára Ọlọ́run ń gbé nínú wa. Ìgbé ayé ẹsẹ̀ àtijọ́ wa ni a ti kàn mọ́ àgbélébùú. A ti dárí gbogbo àìṣedéédé wa jìn wá pátápátá. A sì ti bọ́ lọ́wọ́ ojú tì ti a à bá mọ̀ mọ̀ wá nítorí ninu Jésù gbogbo ìdójútì wa ni a ti jíǹde kúrò nínú rẹ̀.

Nínú Jésù, à ń dàgbà sí i lójoojúmọ́, díè díè títí a á fi dàbíı Jésù. Ní ìgboyà, o ń dàgbà ní gbogbo igba tí o bá ń rántí ohun ti Jésù ti ṣe fún ọ. O ò rí bákan náà bí ìgbà tí o ṣe wà tẹ́lẹ̀. Bí o tilẹ̀ ń rò pé nǹkan kan ò yí padà pé bí o ṣe wà ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn náà ni o wà. Kò rí bẹ́ẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí o bá ń tẹjú mọ́ Jésù, ó ṣe ìlérí láti ọ dàgbà sí i.

Mo gbàdúrà pé ẹ̀mí mímọ́ yó ṣí yín lójú láti Ọlọ́run tí ó ṣe ìràpadà wa. Ẹ ẹ sì le rí Jésù tó mú yín dàgbà sí i láti dàbíı rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá ń rántí ohun gbogbo tí ó ti ṣe fún yín.

Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Àwọn Ará Kólósè

Ètò ìwé-kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yànnàná ìwé tí Paulu kọ sí àwọn ará Kólósè, níbi tí ó ti tako ẹ̀kọ́ òdì tó fi ń rán wa létí pé Jésù - ẹni gíga jùlọ àti alóhun-gbogbo lódùlódù - ṣẹ̀dá àgbáyé, ó sì gba aráyé là. Paulu tún ṣètò ọgbọ́n ìṣàmúlò lórí ìbáṣepọ̀ láàárín ẹbí, àdúrà, ìgbé-ayé ìwà mímọ́, àti ohun tó túmọ̀ sí láti wà ní ìṣọ̀kan nínú ìfẹ́.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/