Àwọn Ará KólósèÀpẹrẹ
Àwọn adarí kan nínú ìjọ Kólósè ṣiyèméjì bóyá alàgbà Paulu ti sọ gbogbo òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà fún wọn tán. Wọ́n bèrè sí ní kọ́’ni ní àwọn ìṣe ti ẹ̀mí mìíràn ní àfikún sí gbígbẹ́kẹ̀lé Jésù láti ní ìrírí ìwàláàyè Ọlọ́run ní èkúnrẹ́rẹ́. Ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ká lára, Epaphra, olùdásílẹ̀ ìjọ Kólósèbẹ Paulu ní ẹ̀wọ̀n fún ìmọ̀ràn. O sọ àwọn iṣé rere tó rí nínú ìjọ wọn fún Paulu, ó tún sọ nípa ẹ̀kọ́ tí àwọn adarí wọn ń tàn kálẹ́ bákan náà. Èsì Pualu ló wà ní ìwé Kólósè.
Sùgbọ́n kí ó tó mẹ́nu lé ìṣòro àwọn ará Kólósè, Paulu kọ́kọ́ tẹmpẹlẹ mọ́ ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wọn, ó sìyàwòrán rẹ̀ sí wọn lọ́kàn. Paulu dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́rún fún ìgbàgbọ́ àwọn ará Kólósè. Wọ́n jẹ́ olóòótọ́, wọ́n ní ifẹ́, wọ́n sì tún ní ìrètí nínú ìhìnrere náà pé Jésù kú, ó jíǹde àti pé Ó ń padà bọ̀ láìpẹ́. Dípò kí àwọn ará Kólósè máa gbé ìgbé-ayé tó kún fún wíwá ọ̀nà tuntun mìíràn láti tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn, Paulu gbàdúrà pé kí wọ́ kún fún ẹmí mímọ́ ti Ọlọ́run. Paulu, ẹni tó kún fún agbára Ọlọ́run ní ìgboyà pé wọ́n máa gbé ìgbé-ayé tí yó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ní kíkún.
Dípò tí wọ́n o fi máa dán ẹkúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run wò ní ọ̀nà mìíràn, ó yẹ kí àwọn ara Kólósè rántí, kí wọ́n sì máa dúpẹ́ pé Ọba ni Jésù. Jésù ti gbà wọ́n nínú ìjọba òkùnkùn, ó sì ṣèlérí pé àwọn ará Kólósè ní ajogún tí ó tọ́ fún ìjọba ìmọ́lẹ̀. Jésù ọba tún dárí àìṣedéédé wọn àtẹ̀yìnwá jìn wọ́n. Títí di àkókò yìí, àwọn ará Kólóse kò tíì ṣe nǹkan kan láti ní ìrírí kíkún ohun tí Jẹ́sù ọba ń pèsè, wọn ò sì nílò láti bẹ̀rẹ̀ báyìí.
Dípò dídán àwọn ọnà mìíràn wò láti wà ní kíkún, ó yẹ kí àwọn ará Kólósè rántí pé aṣẹ̀dá aláṣẹ ni Jésù. Òhun ni ajogún tòótọ́ àti alákòóso ohun gbogbo tí a dá. Jésù dá òfurufú àti ilẹ̀. Jésù dá agbára ìṣèlú àti ti ẹ̀mi, gbogbo agbára lórun àti láyé ló sì ń ṣiṣẹ́ fún Un. Jẹ́sù ní àsẹ lórí ohun gbogbo tó ń mí, àjíǹde rẹ̀ sì tún ṣàfihàn pé Ó lágbára lórí ikú. Jẹ́sù ni ẹni gíga júlọ ní gbogbo àgbáyé, nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ àto àgbélèbú Ó ti da ìṣẹ̀dá rẹ tó ṣàjèjì ní ìgbà kan mọ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ìṣẹ̀dá rẹ.
Ní ìyàtọ̀ sí nǹkan tí àwọn kàn gbàgbọ́, ẹkúnrẹ́rẹ́ agbára Ọlọ́run àti àṣẹ Rẹ̀ ní a fí fúni lọ́fẹ̀ẹ́. Àwọn ará Kólósè tí mọ èyí tẹ́lẹ̀ nítorí wọ́n mọ̀ pé wọ́n ti fí ìgbà kan jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run. Wọ́n mọ̀ pé Jésù fi àṣe Rẹ pa àṣìṣe wọn àtẹ̀yìnwá rẹ́, wọ́n sì mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ti fún wọn lágbára lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ láti tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Èyí ni ẹ̀kọ́ kan ṣoṣo tó ń fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fún’ni, tí àwọn ará Kólósè bá sì wà nínú ẹkọ́ yìí nìkan ní wọ́n ṣe le tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn.
Paulu mọ pé iṣe òun gẹ́gẹ́ bíi àpóstélì ni láti kọ́kọ́ ṣàlàyé ìhìnrere Jésù lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́; pàápàá jùlọ ìhìnrere pé ìwàláàyè lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ń gbé nínú gbogbo ènìyàn tó gbàÁ gbọ́.
Ojúṣe Paulu ni láti ṣàlàyé pé kòsí ìgbésẹ̀, ẹ̀kọ́ àti ìṣe ẹ̀sìn kankan mọ́, tó lé jẹ́ kí a ní ìmọ̀ kíkún nípa Ọlọ́run ju bí a ti ní lọ báyìí nípasẹ Jẹ́sù.
Paulu sọ pé ojúṣe òun tó jọ mọ́ ọn, èyí ni láti rọ àwọn ènìyàn tó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run pé kí wọ́n dàgbà nínú rẹ kí ó le di ìdánimọ̀ wọn, kí wọ́n sì gbé ìgbé-ayé tó tẹ Ọlọ́run lọ́run.
Ṣùgbọ́n ìdàgbàsókè yìí kò ní wá ní ọ̀nà tí à ń retí. Àwọn olùkọ́ni ti ìlú Kólósè ro pé ìdàgbàsókè ní tòótọ́ túmọ̀ sí nǹkan mìíràn jú ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jésù lọ. Ṣùgbọ́n kókó tí Paulu mẹnu bà ní orí àkọ́kọ́ ìwé Kólósè ní pé o ò lè gbàgbà tayọ Jẹ́sù ayérayé lọ. O ò lè tayọ ẹ̀mí mímọ́ èyí tó n gbé nínú rẹ. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù kò dàgbà tayọ ìhìnrere náà.
Bíi ọba, Jésù ti dárí gbogbo àìṣedéédé wa jìn wá, Ó sì fún wa ìjọba ìmọ́lẹ̀ láti ṣàkóso. Gẹ́gẹ́ bíi aṣẹ̀dá, Jẹ́sù ti da àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ìṣẹ̀dá Rẹ. Gẹ́gẹ́ bíi alákóso lórí ikú, Ó fún’ni ní àjíǹde. Nítorí náà, gba ìmọ̀ràn Paulu. Má ṣe tayọ ìhìnrere. Kàkà bẹ́ẹ̀, dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé o máa ní ìrírí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Jésù jinlẹ̀ sí í bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́.
Kí ẹ̀mí mímọ́ ṣí yín lọ́jú láti rí Ọlọ́run tó rán Jésù sí wà. Ẹ ẹ́ sì lè rí Jésù bíi ẹni tó ti ṣàṣeparí iṣẹ́ gbogbo láti fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ètò ìwé-kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yànnàná ìwé tí Paulu kọ sí àwọn ará Kólósè, níbi tí ó ti tako ẹ̀kọ́ òdì tó fi ń rán wa létí pé Jésù - ẹni gíga jùlọ àti alóhun-gbogbo lódùlódù - ṣẹ̀dá àgbáyé, ó sì gba aráyé là. Paulu tún ṣètò ọgbọ́n ìṣàmúlò lórí ìbáṣepọ̀ láàárín ẹbí, àdúrà, ìgbé-ayé ìwà mímọ́, àti ohun tó túmọ̀ sí láti wà ní ìṣọ̀kan nínú ìfẹ́.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/