Àwọn Ará KólósèÀpẹrẹ
Àwọn adarí kan ń dá ìyapa sílẹ̀ láàrin ìjọ Kólósè nípa kíkọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ pé ìhìnrere tí Paulu kọ́’ni ti rọrùn jù. Tí àwọn ara Kólósè bá fẹ ní ìrírí ẹkúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run lóòótọ́, tí wọ́n sì fẹ́ ni òmìnira tòótọ́ lórí àìṣedéédé àtẹ̀yìnwá, wọ́n nílò láti yá lára iṣe ẹ̀sìn agbègbè wọn. Ṣùgbọ́n Paulu tẹnu mọ́ ọn láìmọye ìgbà pé nínú ohun gbogbo wọ́n nílò láti tẹ̀lé Jésù, ní ìrírí Ọlọ́run, kí wọ́n sì ní òmìnira kúrò nínú àìṣedéédé bí a ti fún wọn nípasẹ̀ Jésù.
Àwọn igun kan gbà pé ṣíṣìpẹ̀ sí àwọn agbára ẹ̀mí ní àfikún sí Jésù yó fún’ni ní ìgbé-ayé ti ẹ̀mí lẹ́kùn-únrẹ́ré yíkayíka. Paulu sọ pé àwọn tó àfikún àgbára yìí ń fí ara wọn sí abẹ́ ìdèkùn tàbí ìjẹgàba ẹ̀mí. Àtipé, a tilẹ̀ ti fún àwọn ará Kólósè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára àtí àṣẹ̀ Ọlọ́run. Jésù ń gbé inú wọn. Kò nílò láti máa wa ìṣe agbárá ẹmí mìíràn láti ní ẹkúnrẹ́rẹ́ ìrírí ìwàláàyè Ọlọ́run.
Àwọn igun ti Júù gbà pé o le fíhàn fún Ọlọ́run pé o ti pínyà pẹ̀lú ìwà ibi re nípa dídi ẹni ìkọlà. Ṣùgbọ́n Paulu sọ pé Jésù ti ṣàṣepé iṣé ìkọlà to ga jù. A ti sin gbogbo ara wọn pọ̀ mọ́ Jésù nípasè ìrìbọmi, gbogbo iṣẹ́ ibi àti ìwà ibi wa ni a sì ti fi sí ibojì nígbà tí Ọlọ́run jíwa dìde láti ipò òkú. Kìí ṣe ọ̀bẹ ni a fi gé ìṣẹ́ àti ìwà ibí wa dànù ṣùgbọ́n nípa àgbélèbú Jésù. A ti dáríjìn wá a ò sì nílò láti fi nǹkankan hàn fún Ọlọ́run.
Síbẹ̀ àwọn kan gbà pe Kristẹ́ni gidi jẹ Kosher tí wọ́n sì sinmi ní ọjọ́-ọ̀sẹ̀/ọjọ́-ìsinmi. Kristẹ́ni tó dára jùlọ ní èrò kan pàtó nípa ètò òṣèlú. Kristẹ́nì tòótọ́ gba ààwẹ̀, wọ́n sì ní ìran. Sùgbọ́n Paulu sọ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan yìí mú ọgbọ́n wà, wọ́n máa ń da ìyapa sílẹ̀ láàrín wa, wọn o sì ní ipá láti gbà wá lọ́wọ́ àìṣedéédé àtẹ̀yìnwá tàbí kí wọ́n fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run. Àtipé gbogbo ohun tí wọ́n ń wá ní ètò òṣèlú, ìlànà iṣẹ́ ọjọ́-ọ̀sẹ̀/ọjọ́-ìsinmi àti ìran ni a ti fún wọn. Àjíǹde Jésù ti gba agbára ètò-òṣèlú. Ọjọ́-ọ̀sẹ̀/ọjọ́-ìsinmi wà nípa Jésù. Ìran tí a gbé sórí kò le yí wa padà, ṣùgbọ́n olórí ìjọ le jí wa dìde nínú àwòrán rẹ̀.
Dípò wíwá ojú ènìyàn fún ìmọ̀ ọgbọ́n orí ènìyàn, agbára àti ìṣẹ̀ṣe, àwọn ènìyànn Ọlọ́run yẹh kí wọ́n máa wo Jésù tó jínde tí ó sì jókòó sí ọ̀run, kí wọ́n sì máa gbé ìgbé-ayé tuntun nínú Rẹ. Jẹ́sù níkàn ló ń mú àwọn ènìyàn rẹ̀ wà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti òmìnira. Igbé-ayé àwọn ará Kólósè wà ní ọ̀run pẹ̀lú Jésù, èyí tó túmọ̀ sí pé wọ́n ti ní ohun gbogbo tí wọ́n nílò láti pa ohun ayé tó wà nínú wọn run, kí wọ́n sì gbé ìṣẹ̀dá tuntun wọ̀ bíi ẹni tí a ti túndá. Dípò ọkàn tó kún fún owú àti ìyapa, wọ́n le gbé ìwà ìṣoore àti ìdáríjì wọ̀. Jésù nìkan ni wọ́n nílò láti ní ìgbé-ayé ẹ̀mí kíkún, kí wọ́n sì ní òmìnira kúrò lọ́wọ́ àìṣedéédé àtẹ̀yìnwá.
Paulu parí abala ìwé rẹ̀ yìí pẹ̀lú rírọ àwọn ará Kólósè láti wà ní ìṣọ̀kan. Ó tẹnu mọ́ ọn pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run àti òmìnira lówọ́ ibi àti ìwà búburú ni a ti pèsè nínú Jésù nìkan tí ó sì ń mú ìsọ̀kan wà láàárín àwọn ènìyàn tí ò wà ní ìrẹ́pọ̀. Nínú Jésù, kò sí ọ̀nà Júù tàbí òmíràn tí a fi ń tẹ Ọlọ́run lọ́rùn. Kò sí ọ̀nà ìkọlà tàbí àìkọlà láti fí ijólóòótọ́ wa hàn. Jẹ́sù nìkan ni. Nínú rẹ̀ a kú, nínú rẹ̀ náà ni a ti jí wa dìde.
Àgbélèbú Jésù àti àjíǹde rẹ̀ ti dá ayé ọ̀tun àti àwọn èèyàn Ọlọ́run jákè-jádò sílẹ̀ tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan nínú ìrètí kàn náà pé Jésù nìkan fún wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run ̀ti ọ̀mìnira.
Bí a bá ṣe gba òtítọ́ ỳí láàyè sí ní a ó dúró nínú rẹ̀ sí láti sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmííràn, tí a ó sí le wà ní ìsọ̀kan láti fí ọpẹ́ fún Ọlọ́run tó gbà wá là.
Báyìí, kò sí ohun tó burú tí a bá pinnu láti jẹ kosher tàbi láti pa ọjọ́-òsẹ̀ mọ́. Kò sí ohun to burú tí o bá fẹ́ kí ọ̀rẹ́ rè ní ìrírí ìjìnlẹ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run nínú ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú Ọlọ́run nípa ààwẹ̀ àbí àwọn ìrírí ẹ̀mí. Kò sí sí ohun to burú tí o bá fara mọ àwọn èrò ètò òṣèlù kan. Ohun tí kò tọ̀nà ni kíkọ́’ni, níní èrò tàbí ṣiṣe bíi pé àwọn ohuntí o gbàgbọ́ yìí le fún ẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run àti òmìnira ju àgbélèbú Jésù lọ. Irúfẹ́ ìjẹgàba yìí kìí mú ìṣọ̀kàn wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí a ti gbàlà nípa oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú Jésù máa ṣe ohun gbogbo ní orúkọ Oluwa, ẹni to sọ wọ́n di ọ̀kan. Kí a sì dúpẹ́ pé agbára Jésù lọ́ gbà wá là, kìí ṣe àwọn ohun tí a gbàgbọ́ nínú wọn.
Mo gbàdúrà pé ẹ̀mí mímọ́ á ṣí yín lójú láti rí Ọlọ́run tó fi Jésù fún wa. Ẹ ẹ́ sì rí Jésù bíi ẹnìkan ṣoṣo tí a nílò láti ní ìrírí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run àti omìnira kúro lọ́wọh ìbi àti ìwà búbúrú.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ètò ìwé-kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yànnàná ìwé tí Paulu kọ sí àwọn ará Kólósè, níbi tí ó ti tako ẹ̀kọ́ òdì tó fi ń rán wa létí pé Jésù - ẹni gíga jùlọ àti alóhun-gbogbo lódùlódù - ṣẹ̀dá àgbáyé, ó sì gba aráyé là. Paulu tún ṣètò ọgbọ́n ìṣàmúlò lórí ìbáṣepọ̀ láàárín ẹbí, àdúrà, ìgbé-ayé ìwà mímọ́, àti ohun tó túmọ̀ sí láti wà ní ìṣọ̀kan nínú ìfẹ́.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/