Àwọn Ará KólósèÀpẹrẹ
Paulu aposteli ṣèsẹ̀ sọ fún àwọn ará Kólósè pé a ti sọ wọn di ẹdá ọtun nípasẹ̀ Jésù. Wọ́n ti kún fún agbára Ọlọ́run, wọ́n sì ti di òmìnira kúrò lọ́wọ́ agbára àti ipá tó ń darí wọn tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n òmìnira yìí ipò àwùjọ, ìgbéyàwó àti àgbékalẹ̀ ẹ̀kọ́ wọn padà. Àwọn onígbàgbọ́ yìí ṣì jẹ́ ẹni tó ti gbéyàwó, wọ́n ṣì ní ọmọ, àwọn kàn tiẹ̀ jẹ́ ẹrú, àwọn kan sì jé amúnisìn. Ṣùgbọ́n Paulu sọ pé àwọn ipò tí wọn dìmú nínú ilé yìí jẹ́ àǹfàní láti fi agbára ìràpadà Jésù hàn kí wọ́n sí gbé e wọ Romu tí wọ́n ń gbé inú rẹ̀.
Kí àwọn aya má ló òmìnira wọn nínú Jésù bíi àwáwí láti kọ́ ọkọ̀ sílẹ̀ tàbíṣe lòdì tàbí dìtẹ̀ sí ọkọ wọn, ṣùgbọ́ kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí wọn. Àwọn ọkọ ò gbọdọ̀ máa lo ìyàwó wọn láti tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́run, ṣùgbọ́n kí wọ́n fẹ́ran aya wọn kí wọ́n sì máa tẹ́ ìfẹ́ aya wọn náà lọ́rùn torí ó ṣe pàtàkì bí ìfẹ́ ara tiwọn náà. Kí àwọn ọmọ má ló òmìnira wọn nínú Jésù bíi àwáwí láti ṣe àìgbọràn sí òbí wọn, sùgbọ́n kí wọ́n máa ṣe ìfé wọn kánmọ́-kánmọ́. Kí àwọn òbí máa kọ́’ṣe bàbá wọn tí ń bẹ ní ọ̀run kí wọ́n máa lo agbára àti ipò láti gba àwọn ọmọ níyànjú. Àwọn ẹrú tí ó ṣeése fún láti gba òmìnira wọn nítorí Jésù, gbọ́dọ̀ gbọ́ràn sí olúwa wọn lẹ́nu – kìí ṣe láti tẹ wọn lọ́rùn, bíkòṣe láti tẹ́ Ọlọ́run lọ́run ẹni tó ń jẹ́ kí ẹrú di ajogún ìjọba Rẹ̀. Ọlọ́run lò yàn ààyò láàárin ẹrú tàbí olúwa ẹrú. Nítorí náà kí àwọn olúwa ẹrú máa rántí pé wọ́n ní Olúwà kàn náà pẹ̀lú àwọ̀n ẹrú tí wọ́n fí ń ṣiṣẹ́. Wọn ò jú àwọn ẹru wọn lọ, a ó sì dá wọn lẹ́jọ́ tí wọ́n ba kùnà láti tọ́jú àwọn tí wọ́n gbà síṣe bí ó ti yẹ ní idájọ́ òtítọ́ àti àìṣe ẹlẹ́yàmẹ̀yà.
Paulu fẹ́ kí ilé àwọn ará Kólósè jẹ́ àwòkọ́ṣe ìhìnrere fún àwùjọ. Ṣùgbọ́n Paulu mọ̀ pé gbígbé ìgbéayé bíi ti Jésù nínú ìgbeyàwó, bí ọmọ, àtí ní sísin ẹnìkejì máa nira. Yó nílò àdúrà àti ìdúpẹ́. Àwọn ẹ̀kọ́ tí Paulu kọ́ ní túbú nìyí, síbẹ̀ ó sì yẹ kí ó ṣì máa kíyèsárá. Gbogbo wọn nílo àdúrà láti le farada ìnira. Gbogbo wọn sì gbọdọ̀ ní ìrètí kí wọ́n sì máa dúpẹ́ pé Ọlọ́run ń lo ẹbí àti ìdílé láti ṣàfihàn agbára Jésù àti ipá rẹ láti gba ayé là.
Ibáṣepọ̀ tó ṣe pàtàkì jùlọ ní ìgbésí ayé wa ń pèsè àwọn àǹfàní tó ga jù láti ṣàfihàn ìfẹ́ àti agbára Jésù sí ayé. Bí àwọn aya ṣe ń tẹríba fún ọkọ tó ń farajìyà lórí wọn, àwọn méjèèjì jọ jùmọ̀ jẹ́ àwòrán ìyè ìjọ àti ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ Jésù. Bí àwọn ọmọ ṣe ń gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn, wọ́n ń ṣàfihàn ìgbọ́ràn Jésù sí bàbá rẹ̀. Bí àwọn òbí ṣe ń sùúrù kọ àwọn ọmọ wọn, wọ́n ń ṣàfihàn sùúrù Ọlọ́run sí ayé àìgbọràn. Àwọn tó ń sin àwọn ẹlòmíràn yó gbé àgọ́-ara ìfara-ẹni-rúbọ sin’ni Jésù láti gba wá là wọ̀. Àwọn agbanisíṣẹ́ oníwà-bí-Ọlọ́run ń ṣàfihàn ọ̀nà tí Ọlọ́run fi ń lo àṣe àti agbara rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ òdodo. Ìgbéyàwó, ìgbà èwe, ṣíṣìṣe òbi àti iṣẹ́ ṣíṣe (díẹ̀ lára rẹ) wà láti yàwòrán ìhìnrere Jesù ní àwùjọ.
Ìbáṣepọ̀ tí a ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn kìí kàn ṣe ìṣàfihàn agbára àti ìfẹ́ Jésù, ó ní àwọn ọnà tí à ń gbà kópa níbẹ̀. Bí a ṣe fẹ́ràn àwọn tó báwa tan yìí, à ń fún’ni a sì ń gba ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìgbéyàwó, ẹbí àti iṣẹ́ jẹ́ ibi ọ̀wọ̀ níbi tí a ti ń bá Jésù pàdé lójúkojú. Ní ọ̀pọ̀ ibi ni ìwé mímọ́ ti ṣàpéjúwe Jésù bíi ọkọ, ọmọ, bàbá, arákùnrin, ẹrú àti olúwa. Jésù tìkalára rẹ ṣàpéjúwe ararẹ̀ bíi ìyá, ìyá adìyẹ tó ń dáàbòbò àwọn ọmọ rẹ̀. Ìgbéyàwó, inú ẹbí àti ibi-iṣẹ́ jẹ àwọn ibí gbòógì tí a ti ní ìrírí ìfarahàn ìfẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tí a bá farajìn, nífẹ̀ẹ́, ṣiṣẹ́sìn, gbọ́ràn tí a sì jẹ́ olóòótọ́ sí àwọn tó tan mọ́ wá tàbí tí nǹkan jọ dàwá pọ̀, à ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí fún Jésù. Nígba tí àwọn mìíràn bá sì ṣe é sí wa, ó jásí pé Jésù náà fẹ́ràn wa.
Níbòmíràn, Paulu ṣàpéjúwe àwọn ọmọ ìjọ Ọlọ́run bíi ara Jésù. Títí tí Jésù yó sì fi padà wá, ọ̀nà tí ayé yó fi rí i, tí wọn ó si máa ní ìrírí ara Jésù tí a fi rúbọ fún wọn bí àwọn ọkọ, àwọn aya, òbí, àwọn ọmọ àti àwọn òṣìṣẹ́ bá fẹ́ràn ara wọn tí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn.
Mo gbàdúrà pé ẹ̀mí mímọ́ yó sí yín lójú láti rí Ọlọ́run tọ fún wa ni òmìnira àti ìyè. Ẹ ẹ́ sì le rí Jésù bí ẹni tó lo ìbáṣepọ̀ wa tó ṣe pàtàkì jù láti ṣàfihàn ìfẹ́ àti agbára rẹ sí ayé.
Nípa Ìpèsè yìí
Ètò ìwé-kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yànnàná ìwé tí Paulu kọ sí àwọn ará Kólósè, níbi tí ó ti tako ẹ̀kọ́ òdì tó fi ń rán wa létí pé Jésù - ẹni gíga jùlọ àti alóhun-gbogbo lódùlódù - ṣẹ̀dá àgbáyé, ó sì gba aráyé là. Paulu tún ṣètò ọgbọ́n ìṣàmúlò lórí ìbáṣepọ̀ láàárín ẹbí, àdúrà, ìgbé-ayé ìwà mímọ́, àti ohun tó túmọ̀ sí láti wà ní ìṣọ̀kan nínú ìfẹ́.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/