2 PeteruÀpẹrẹ
Nígbà tí ọjọ ikú Peteru dé. Ìwé Peteru kejì jẹ́ àkóónú ọ̀rọ̀ tí ọ̀kan nínú ọmọ ẹ̀yìn tí ó súnmọ́ Jesu típẹ́ típẹ́ sọ gbẹ̀yìn. Ó sọ pẹ́, Jesu ni Ọlọ́run àti Olùgbàlà wa. Ní ìgbà aye Peteru, ọ̀pọ̀ ènìyàn ní kò gba ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lé àyọrísírẹ̀ ṣùgbọ́n Peteru se àtúnṣe sí ẹ̀kọ́ èké yìí nínú ìwé tí ó kọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Báyìí, Peteru kàn fẹ́ ṣe ìwàásù kan tí ó gbẹ̀yìn kí ó tó kú.
Kókó ìwàásù rẹ̀ náà ní pé, Jesu ti sètò agbára ńlá rẹ̀ láti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ìgbéayé ìwà bí Ọlọ́run. Ìgbé ayé ìwà bí Ọlọ́run yìí wá nípaṣẹ Jesu. Mímọ̀ Jesu ni Olúwa àti Olùgbàlà wa kò túmọ̀ sí pé a mọ nípa Jesu ṣùgbọ́n kíkópa nínú ìwàláàyè Ọlọ́run ni. Peteru túmọ̀ síàdìjọpín, ìdàpọ̀ tí ó kú fún ìwà mímọ́ tàbí òdodo Ọlọ́run. Ó sọ wí pé ìkópa nínú ohun ti Ọlọ́run jẹ́ ìṣe rere Ọlọ́run lórí ìlérí rẹ̀. Peteru kò ṣàlàyé ohun tí ìlérú náà jẹ́ ní pàtó, ó kàn sàlàyé ohun tí wọ́n ń ṣe ni. Ìlérí Ọlọ́run ń múni hùwà tó tọ, èyí sì ni ó ń mú wa bọ́ lọ́wọ́ ìwá àìtọ̀.
Ìwà àìtọ́ ní ó bá ayé jẹ́.Ìbásepọ̀ láàrin ara wa, a rí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí i aláìmọ̀kan-mọ̀kan,aláìkọ́ra-ẹni níjánu, asiyèméjì, oníríra àti akórira. Ṣùgbọ́n Jesu pé wá sí òdodo rẹ̀ tó lógo. Nípa agbára ńlá rẹ̀ ní a ń ṣe alábápín ìwà pípé. Nínú Jesu, a bọ́ lọ́wọ́ ìwá àìtọ̀.
Yíyọ nínú ìwá àìtọ̀ yìí jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan àti ìrìnàjò kan. Jesu gbà wá nípaṣẹ̀ ìgbàgbọ, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ gbìyànjú lati fi ìwà tó dára kún ìsòtítọ́ wa. Ọlọ́run pèṣè agbára ńlá rẹ̀ láti fi wá sínú òye pípé rẹ̀, ìkóra-ẹni-níjánu, ìsòtítọ́, ìfà ọkàn àti ìfẹ́. Ní ìdáhùn sí ìṣe Ọlọ́run lórí ẹ̀dá ènìyàn nípa ìwà pípé. A ń kópa nínú ohun ti Ọlọ́run nípa wíwà títẹ̀síwájú nínú ìwà rere àti ìwà bí Ọlọ́run. Àwọn tí wọ́n mọ Jesu gẹ́gẹ́ bí i Oluwa àti Olùgbàlà máa ń dàgbà ní ọ̀nà yìí.
Ìròyìn ayọ̀ tí Peteru mú lọ sí iṣà òkú ni pé Jesu gbàwálà kí a le kópa nínu ìwà pípe Ọlọ́run, kí á sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú Rẹ̀ lórílẹ̀ ayé. Àìsàfihàn ìwà rere, àìkọ́ni, àti àìní ìfẹ́, tí ó mú kí á gbàgbé ìdí tí a fi gbà yín là.Ṣùgbọ́n àwọn tí ó kópa nínú ohun ti ọrun yóó ní ìgboyà púpọ̀ nínú ìgbàlà, wọn yóó sì ríìwà bí Ọlọ́run nínú ayé wọn.
Nígbà tí Peteru kú,ó mọ̀ pé kíkópa nínú ẹ̀dá Jesu gbàwá lọ́wọ́ ìwà àìtọ́, tí ó sì jẹ́ kí a ni ìdàgbàsókè nínú ìwà tí ó tọ́ bí a se ń gbé ayé wa.Ṣùgbón ìrètí Peteru tàn kọjá ayé yìí. Kíkópa nínú ohun tí ọ̀run kò túmọ̀ sí pé kí a di olótìítọ́ nìkan nígbà tí ó bá yá; ṣùgbọ́n ó tún túmọ̀ sí kíkopa nínú ohun àìdíbàjẹ́ tí ọ̀run. Jesu ti so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ wa, yóò sì kí wa káàbọ̀ sínú ìjọba ayérayé rẹ̀. Ní ìparí lẹ́tà Peteru, ó fi kún un pé Jesu yóò kí wa káàbọ̀ sí ìgbéayé ọ̀tun níbi tí òdodo yóò wà títí láé.
Ní ìgbẹ̀yìn ayé Peteru, Ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀ fún wa pé Olùgbàlà àti Olódodo wa tí pin ẹ̀dá òdodo rẹ̀ pẹ̀lú wa torí náà, a le gbé ìgbéayé òdodo tí yóò yọrí sí òdodo ayérayé.Ìwàkiwà tí ó gbòdebáyìí yóò pòórá, gbígbèrú wa nínú ìwà rere yóò dàgbàsóké sí ìwà pípé títí láé.
Ọ̀run àpáàdì ni ayérayé tí ìwá ìbàjẹ́ wa tí jẹ gàba lé lórí. Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, àwọn tí wọ́n mọ̀ Jesu ní ìrírí ìwà òdodo Ọlọ́run bàyìí àti títí ayérayé. Àwọn olódod wọ̀nyí ni Peteru fi ìwé tí ó kọ gbẹ̀yìn kan sáárá sí.Mo lérò pé Jesu yóó pé ọ sí inú ògo àti ìtayọ rẹ̀. Mo pé Jesu le pè ọ́ jáde kúro nínú ìwà ìbàjẹ́ lọ sínú ìwà pípé.
Ẹ̀mí mímọ́ yóò sí ọ lójú láti rí Ọlọ́run tí i se Olódodo. Ìwọ ó sì rí Jesu gẹ́gẹ́ bí i Olùgbàlà watí ó ńpín ẹ̀dá òdodo rẹ̀ pẹ̀lú wa kí a le ní ìrírí ògo Rẹ̀ títí ayé.
Nípa Ìpèsè yìí
Ìwé Peteru kejì (2 Peter) yóò jẹ́ kí o nífẹ̀ẹ́ sí i láti dàgbà nínú ẹ̀mí, yóò jẹ́ kí o kọ ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn, tí ìwọ yóò sì máà gbé ìgbé ayé ìwà mímọ́. Bí o ṣe ń retí bíbọ̀ Jesu, mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ń pèsè gbogbo ohun tí o nílò láti gbé ìgbéayé ìwà bí Ọlọ́run.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/