2 PeteruÀpẹrẹ

2 Peteru

Ọjọ́ 3 nínú 3

Nígbà tí Peteru ń parí lẹ́tà rẹ̀ kejì lọ, ó fẹ́ jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ ránti pé Jesu ń padà bọ̀, ó sì ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́ngbá ìgbé ayé ìwá bí Ọlọ́run.Ṣùgbọ́n ìránilétí yìí kì í ṣe ohun tí ó di mímọ̀ láàrin àwọn olùkọ́ni èké. Wọ́n ń siyèméjì pé Jesu yóò padà wá, kò sì sí ìdánilójú fún wọ pé bóyá kí wọ́n dẹ́kun ifẹ̀ ọkàn wọn.

Olùkọ́ni èkè ní àríyànjiyàn mẹ́jì.Àkọ́kọ́,láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé ní Ọlọ́run ti kọ̀ láti dá sí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ó sì se ìdájọ́ ìwà rere. Ọjọ́ ìdájọ́ ìwà búburú wa tí a sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kò tí i dé, torí náà bí a se ń hùwà kò jẹ́ nǹkankan sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Peteru fi yé wa pé wọ́n kọ òdodo.

Peteru sọ pé Ọlọ́run tí dásí ọ̀rọ̀ ènìyàn. Ọlọ́run sẹ̀dá ilẹ̀ láti inú omi ìgbààní nípaṣẹ̀ ọ̀rọ̀ kan. Nípaṣẹ̀ ọ̀rọ̀ mìíràn ó mú ilẹ̀ dúró lábẹ́ omi gẹ́gẹ́ bí i ìdáhun sí ìwà àìtọ́ àwùjọ. Àwọn olùkọ́ni èkè kò mọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dunjú dunjú,Ọlọ́run máa ń dá sí ọ̀rọ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ènìyàn, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń dúró láti se ìdájọ́ ayé.

Àríyànjiyàn kejì tí àwọn Olùkọ́ni èkè ní ni pé Ọlọ́run tí pẹ́.Jesu sọ pé Òun yóò dé láìpẹ́, ṣùgbọ́n kò tí ì dé. Peteru fi yé wa pé Ọlọ́run wa tí kìí díbàjẹ́ kìí se àmúlò àkókó wa láti gbé ìgbéṣẹ̀. Fún Ọlọ́run, àkókò rẹ̀ le yàtọ̀ sí tí wa. Yàtọ̀ sí èyí,Ọlọrun kò pé, ó ń ní sùúrù ni. Ọlọrun kò fẹ́ kí ẹni kankan kú, bẹ́ẹ̀ ni kò fẹ́ kí a fojú winá ìdájọ́ rẹ̀. Pípẹ́ Ọlọ́run kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run kò náání wa, ṣùgbọ́n ó ń fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Òun ní àánú àwọn ènìyàn tí wọn kò tíì ronúpìwàdà ni. Sùúrù Ọlọ́run ni pípẹ́ rẹ̀. Sùúrù Ọlọ́run nìkan ni ìrètí ìgbàlà àwọn tí ń siyèméjì àkókò rẹ̀. A mọ̀ pé Jesu ń bọ̀. Ní ọjọ́ náà, èsù àti ẹ̀ṣẹ̀ yóò di aláìlágbára. Ohun tí ó dára tí o tọ́ ni yóó kù. Torí náà, ó dára kí a máà gbé ìgbéayé wa bí ẹni pé ìjọba ọrun yóò dé ní kíákíá. Kí a máa gbé ìgbé ayé tí ó kún fún ìwà pípé àti ìwà títọ́, èyí yóò sì wà títí ayé. A ní láti sọ́ra fún àwọn olùkọ́ni tí wọ́n ń jẹ́ kí a siyèméjì nípa ìdájọ́ Jesu tó ń bọ̀ tàbí tí wọ́n ń jẹ́ kí a siyèméjì nípa líloye àwọn òfin rẹ̀.Ọlọ́run ń sàníyàn nípa wa. A mọ́ pé ọjọ́ bíbọ̀ Jesu kò ní jẹ́ ọjọ́ ìdájọ́ fún àwọn tí wọ́n mọ̀ pé Jesu ń bọ̀, ṣùgbọ́n ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìrètí.

Ọlọ́run ń bọ̀, kìí ṣe láti wá sèdájọ́ níkan ṣùgbọ́n láti wá ṣẹ́dá ayé òdodo titun, ìwà tí ó tọ́ àti àlááfíà. Ìdúrópẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú sùúrù kì í ṣe nítorí pé Ọlọ́run kò lánìíyàn wa ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyan ronú pìwàdà. Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wọ ayé titun tí ó sẹ̀sẹ̀ pèṣè níbi tí ìwà ibi àti ìdíwọ́ kò sí, níbi tí kò sí ààyè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Dídé Ọlọ́run kù sí “dẹ̀dẹ̀” torí náà gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ wà nínú ìmúnisìn ẹ̀ṣẹ̀, tí ẹ sí ń ké pé Ọlọ́run le ronú pìwàdà, kí ẹ le ní òmìnira nínú ayé titun tí ń bọ̀..

Ọlọ́run ti se ìdájọ́ lẹ́ẹ̀kan rí, yóó sì tún se ìdájọ́ títun mìíràn. Ma se rí sùúrú Ọlọ́run nínú ayé ènìyàn gẹ́gẹ́ bí i àìlákàsí, ṣùgbọ́n kí o rí i gẹ́gẹ́ bí i ìgbàlà. Mo fẹ́ kí o rí ìdúró pípẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ìpè fún gbogbo ènìyàn. Ìjọba Ọlọ́run tí ó kún fún oore ọ̀fẹ́,agbára, ire àti ẹwà ń bọ̀. Ọjọ́ ń bọ̀ tí gbogbo wa pátá yóó bọ́ lọ́wọ́ àìsòdodo àti ìwa búburú tí à ń hù sí àwọn mìíràn

Kí Ọlọ́run sí ọ lójú láti rí Ọlọ́run tí ó sẹ̀dá, tí yóó sì sèdájọ́ ayé. Ìwọ ó sí rí Jesu gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń bọ̀ láti sèdájọ́ ìwà búburú, tí yóó sì pèṣè ayé òdodo titun fún gbogbo ènìyàn.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

2 Peteru

Ìwé Peteru kejì (2 Peter) yóò jẹ́ kí o nífẹ̀ẹ́ sí i láti dàgbà nínú ẹ̀mí, yóò jẹ́ kí o kọ ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn, tí ìwọ yóò sì máà gbé ìgbé ayé ìwà mímọ́. Bí o ṣe ń retí bíbọ̀ Jesu, mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ń pèsè gbogbo ohun tí o nílò láti gbé ìgbéayé ìwà bí Ọlọ́run.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/