2 PeteruÀpẹrẹ

2 Peteru

Ọjọ́ 2 nínú 3

Peteru ń ṣe ohun tí ó tọ, Ṣùgbọ́n àwọn olùkọ́ni èké ń fi sùn pé ó ń kọ nípa ìtàn pé Jesu yóó padà wá láti wá sèdájọ́ ìwà èèrí àti ìwà ìmọ̀ ara ẹni nìkan. Àwọn olùfisùn yìí kò fi ààyè gba Jesu láti sàkóso wọ́n, wọ́n kọ wíwá tí yóò wá láti se ìdájọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n kò gbà pé Kristẹ́nì gbọ́dọ̀ pa òfin kan mọ́. Ní ọ̀nà mìíràn, bí Ọlọ́run kò bá ní i ṣe ìdájọ́, a le se ohun tí a bá fẹ́. Ṣùgbọ́n Peteru kò gba gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ yìí.

Ní àkọ́ka, nípa tí àgbára Jesu, Peteru sọ wí pé kìí ṣe ìtàn ni oun àti àwọn Aposteli yòókù ń sọ nípa ìparadà Jesu.Ìparadà Jesu nínú ìyìnrere yóò wayé ní kètè tí àwọn Apostẹ́lì bá ti mọ̀ pé Jesu ní àgbára láti se ìjọba ayé. Ọlọ́run sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá péJesu ni àyànfẹ́ ọmọ Rẹ̀. Ó sì ti wà pẹ̀lú Mose, Ọba àkọ́kọ́ ní ilẹ̀ Ìsreali, àti Elija Olúrapadà, ẹni àkọ́kọ́ nínú Bíbélì tó jí òkú dìde. Ó ní àwọn Olùkọ́ni èké kùnà. Ìparadà sàfihàn rẹ̀ pé a tí fún Jesu ní àṣẹ lórí ayé, lórí òkú àti ní gbogbo ayé, Peteru sì ni ẹlẹ́rìí.

Ìwé Peteru kejì sọ nípa ọjọ́ ìdájọ́.Lára àríyàjiyàn àwọnolùkọ́ni èké ni pé ọ̀rọ̀ nipà àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ ìdájọ́ jẹ́ èrò láti ọwọ́ ènìyàn kìí ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run. “Ìdájọ́ jẹ́ ohun èlò tí ẹ̀sin ń lò láti mú ènìyàn ní ìbẹ̀rù, kí ó sì hùwà tí ó tọ́”. Ṣùgbọ́n Peteru jẹ́ kí ó di mímọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀nípa ọjọ́ ìdájọ́ wá láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́, kìí se láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn. Ẹ̀mí Mímọ́tí wọ́n kọ̀ gan an ní ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ìdájọ́, kì í se èrò ẹnikẹ́ni.

Kíkọ ọjọ́ ìdájọ́ tí kò le yẹ̀ yí jẹ́ ohun tí ó ti wà tipẹ́, ó sì ní àyọrísí. Peteru fi ìdí èyí múlẹ̀ nípa sísọ ìtàn ìdájọ́ mẹ́ta tí a mọ̀ nínú Májẹ̀mu láéláé: ìsubú àwọn ọmọ Ọlọ́run, òjò Noah, àti Sodomuòhun Gomorrah. Nìnú àwọn ìtàn yìí, ènìyàn bí i Ańgẹ́lì, àwọn ènìyàn Noah àti àwọn ọmọ ìlú méjì ni wọ́n kọ àṣẹ Ọlọ́run, wọ́n ń tẹ̀síwájú nínú ìwà èèrí àti nínú ohun ayé, wọ́n sì jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí yóò sẹlẹ̀ sí gbogbo ẹni tí ko hu ìwà bí Ọlọ́run.

Ní ìparí, Peteru sọ̀rọ̀ nípa ohun tí àwọn olùkọ́ni èké ń sọ nípa sísàkópọ̀ ìwà rere nípaṣẹ̀ fífi ìdájọ́ ohun tí kìí se ìfẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú ìkóniyo ìwà rere tí kò le yẹ̀ wé ara wọn. Noah àti Lọ́ọ̀tì jẹ́ olótìítọ́ ènìyèn,ṣùgbọ́n ìwà èérri àti ẹ̀mí èsù tí ó yi wọn ká mú wọn bínú ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì di ẹni ìgbàlà. Òtítọ́ se pàtàkì. Nípa sísọ pé Jesu kò ní dé àti nípa kíkéde ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà rere, àwọn olùkọ́ni èké kò tako Jesu nìkan, wọ́n tún tako ohunkóhun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú gbígbani lọ́wọ́ ewu ayé.

Peteru pé èrò yìí ní èrò ẹranko. Awọn olùkọ́ni èkè yìí tinú ìpalébi bọ́ sínú ìpalébi. Wọ́n ń gbó lásán lórí ohun tí wọ́n kọ̀ láti mọ̀. Ìfẹ́ owó ń gbé wọn lọ, wọ́n sì dàbí Balaamu, Wòlíì ìgbàanì, tí ó taọ̀rọ̀ ní owó gọbọi, tí ara ẹrànko rẹ̀ sì dá ju ti olówó rẹ̀ lọ. Ó dàbi orísun tí kò ní omi, ó ń wàásù òmìnira nígbà tí títakò ìpadàbọ̀ Jesu kò já mọ́ nǹkan, tí kò sì bójúmu. Torí náà, bíbẹ̀rù àṣẹ Ọlọ́run, wọ́n kóra wọn lẹ̀rúsínu ìtara àtijọ́ tí wọ́n ní sí ara wọn. Wọ́n dàbi aja àti ẹlẹ́dẹ̀, wọn kò le se ìrànwọ́ ṣùgbọ́n ń jẹ èérí ara wọn.

Níbo ni Ìyìnrere Wà?

Peteru tọ̀nà, a sì le sọ bẹ́ẹ̀. Ó ń báwa sọ̀rọ̀ nípa títako àwọn olùkọ́ni èkè, Ọ̀pọ̀ nínú wa le nílò láti gbọ́ bí ó se ń ṣe ìbáwí rẹ̀ kíkan kíkan nípa ìdájọ́ Ọlọ́run tí kó le yẹ. Ọ̀pọ̀ le sọ nípa àìní ìgbàgbọ́ àwọn olùkọ́ni èké nípa ìpadàbọ̀ Jesu, tí wọ́n sì ń fi àìní ìgbàgbọ́ wọn dìtẹ̀.Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín ní láti gbọ́ ìkìlọ̀ Peteru lóri ìparun ayé tí ebi ń ṣe àkóso rẹ̀, tí ó sì wà ní abẹ́ olùsàkóso kan dípo ara rẹ

Ṣùgbọ́n gbogbo wa ló yẹ kí à gbọ́ ìròyìn ayọ̀ tí ó ń gbani, ìtúsílẹ̀ sì jẹ́ ohun kòseémánìí fún olódodo. Peteru pílẹ̀ ti sọ pé àwọn tí ó mọ Jesu ni wọ́n pin nínú òdodo ńlá rẹ̀.Ìgbàlà wá dájú! Gẹ́gẹ́ bí i Noah, a lè wàásù ìyìnrere pẹ̀lú ìgboyà fún àgbáyé. Bí i Lọ́ọ̀tì, a le gbàgbé ìwá èérí ayé yìí. Bí i àwọn méjéèjì, a le ní ìgboyà ní ìkọ̀kọ̀ pé a ó ní ìrírí ìdájọ́ tí ó ń sọ nípa rẹ̀. Ọlọ́run mọ bí yóó se gba olòdodo là, yóò sì se é fún gbogbo àwa tí ó mọ̀ ọ́n, tí ó sì gba ọmọ rẹ̀ Jesu ọba gbọ́.

Kí Ẹ̀mí Mímọ̀ si yín lójú láti rí Ọlọ́run tí ó ń ṣe ìdájọ́ ìwà búburú. Ìwọ yóò sì rí Jesu gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń sàkóso ayé, tí ó sì ń gba olódodo là nínú ìdájọ́.

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

2 Peteru

Ìwé Peteru kejì (2 Peter) yóò jẹ́ kí o nífẹ̀ẹ́ sí i láti dàgbà nínú ẹ̀mí, yóò jẹ́ kí o kọ ẹ̀kọ́ ẹ̀tàn, tí ìwọ yóò sì máà gbé ìgbé ayé ìwà mímọ́. Bí o ṣe ń retí bíbọ̀ Jesu, mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ń pèsè gbogbo ohun tí o nílò láti gbé ìgbéayé ìwà bí Ọlọ́run.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/