SIMONI Peteru, iranṣẹ ati Aposteli Jesu Kristi, si awọn ti o ti gbà irú iyebiye igbagbọ́ kanna pẹlu wa, ninu ododo Ọlọrun wa ati ti Jesu Kristi Olugbala: Ki ore-ọfẹ ati alafia ki o mã bisi i fun nyin ninu ìmọ Ọlọrun, ati ti Jesu Oluwa wa, Bi agbara rẹ̀ bi Ọlọrun ti fun wa li ohun gbogbo ti iṣe ti ìye ati ti ìwa-bi-Ọlọrun, nipa ìmọ ẹniti o pè wa nipa ogo ati ọlanla rẹ̀: Nipa eyiti o ti fi awọn ileri rẹ̀ ti o tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa: pe nipa iwọnyi ni ki ẹnyin ki o le di alabapin ninu ìwa Ọlọrun, nigbati ẹnyin bá ti yọ kuro ninu ibajẹ ti mbẹ ninu aiye nipa ifẹkufẹ. Ati nitori eyi nã pãpã, ẹ mã ṣe aisimi gbogbo, ẹ fi ìwarere kún igbagbọ́, ati ìmọ kún ìwarere; Ati airekọja kún ìmọ; ati sũru kún airekọja; ati ìwa-bi-Ọlọrun kún sũru; Ati ifẹ ọmọnikeji kún ìwa-bi-Ọlọrun; ati ifẹni kún ifẹ ọmọnikeji. Nitori bi ẹnyin bá ni nkan wọnyi ti nwọn bá si pọ̀, nwọn kì yio jẹ ki ẹ ṣe ọ̀lẹ tabi alaileso ninu ìmọ Oluwa wa Jesu Kristi. Nitori ẹniti o ba ṣe alaini nkan wọnyi, o fọju, kò le riran li òkẽre, o si ti gbagbé pe a ti wẹ̀ on nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ atijọ. Nitorina, ará, ẹ tubọ mã ṣe aisimi lati sọ ìpe ati yiyàn nyin di dajudaju: nitori bi ẹnyin ba nṣe nkan wọnyi, ẹnyin kì yio kọsẹ lai.
Kà II. Pet 1
Feti si II. Pet 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Pet 1:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò