II. Pet 1:1-10

II. Pet 1:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Èmi, Simoni Peteru iranṣẹ ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn tí wọn ní irú anfaani tí a níláti gbàgbọ́ bíi tiwa, nípa òdodo Ọlọrun wa ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia pọ̀ sí i fun yín nípa mímọ Ọlọrun ati Jesu Oluwa wa. Nípa agbára Ọlọrun tí kì í ṣe ti eniyan, ó ti fún wa ní ohun gbogbo tí yóo jẹ́ kí á gbé irú ìgbé-ayé tí ó dára ati ti ìwà-bí-Ọlọrun, nípa mímọ ẹni tí ó fi ògo ati ọlá rẹ̀ pè wá. Nípasẹ̀ èyí ni a ti gba àwọn ìlérí iyebíye tí ó tóbi jùlọ, tí ó fi jẹ́ pé ẹ ti di alábàápín ninu ìwà Ọlọrun, ẹ sì ti sá fún ìbàjẹ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti mú wọ inú ayé. Nítorí èyí, kí ẹ ní ìtara láti fi ìwà ọmọlúwàbí kún igbagbọ yín, kí ẹ sì fi ìmọ̀ kún ìwà ọmọlúwàbí. Ẹ fi ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀, kí ẹ fi ìgboyà kún ìkóra-ẹni-níjàánu, kí ẹ sì fi ìfọkànsìn kún ìgboyà. Ẹ fi ìṣoore fún àwọn onigbagbọ kún ìfọkànsìn, kí ẹ sì fi ìfẹ́ kún ìṣoore fún àwọn onigbagbọ. Nítorí tí ẹ bá ní àwọn nǹkan wọnyi; tí wọn ń dàgbà ninu yín, ìgbé-ayé yín kò ní jẹ́ lásán tabi kí ó jẹ́ aláìléso ninu mímọ Jesu Kristi. Afọ́jú ni ẹni tí kò bá ní àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ kò ríran jìnnà, kò sì lè ronú ẹ̀yìn-ọ̀la. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti gbàgbé ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́. Ẹ̀yin ará, ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹ fi gbọdọ̀ túbọ̀ ní ìtara láti fi pípè tí a pè yín ati yíyàn tí a yàn yín hàn. Tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi, ẹ kò ní kùnà.

II. Pet 1:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Simoni Peteru, ìránṣẹ́ àti aposteli Jesu Kristi, Sí àwọn tí ó gba irú iyebíye ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú wá nínú òdodo Ọlọ́run wa àti ti Jesu Kristi Olùgbàlà. Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jesu Olúwa wa. Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀. Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere; àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù. Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì. Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́. Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsimi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú: nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò ṣubú.