RúùtùÀpẹrẹ
Ilẹ̀, ogún àti gbígbé ilé ayé Náómì wà lọ́rùn Búásì. Òun ni olùràpadà rẹ̀ tó dájú, Rúùtù sì ti dẹnu ]ifẹ́ kọ ọ́. Olùràpadà ni ẹni tí ó ṣetán àti gbé ojúṣe tí ó jẹ mọ́ òfin, ìdílé, àti ìsúná mọ̀lẹ́bí tí ó jẹ́ òtòsì pàápàá opó.
Búásì gbà láti fẹ́ Rúùtù ṣùgbọ́ ìsòro kan wà. Búásì kò lè ṣe olùràpadà Náómì nítorí pé mọ̀lẹ́bí mìíràn tí ó súnmọ́ Náómì ju òun lọ ni ó yẹ kí á kọ́kọ́ fún ní àǹfààní yìí.
Búásì kò fi àkókò sòfò rárá. Àárọ̀ ọjọ́ kejì àbá, ó lọ sí ẹnu bodè ìlú títí tí ó fi rí olùràpadà tí ó yẹ náà. Láì mẹ́nu ba Rúùtù, Búásì ṣàlàyé fún olùràpadà tí wọn ò dárúkọ yìí pé Náómì ti gbé ilẹ̀ ọkọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ fún títà, ó sì ní agbara àti kọ̀ láti rà á..
Ó ronú nípa ewu tí kò tó nǹkan àti èrè púpọ̀ tí ó wà níbi oko òwò náà, kíákíá ó ní bẹ́ẹ̀ ni, òun ṣetán àti rà á. Ṣùgbọ́n lọ́gán tí ó ronú dé ibi pé bí òun bá ra ilẹ̀ náà, òun ní ojúṣe àti máa tọ́jú àwọn opó tí i ṣe Náómì àti Rúùtù, ó kọ̀ láti rà á. Láti ra ilẹ̀ yẹn jẹ́ ọ̀kan, ṣùgbọ́n láti gbé Rúùtù ní ìyàwó, tí ó sì ṣe é ṣe kí ó pín ogúnn tí òun tìkalára, kí ó sì pàdánù ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ tí Rúùtù bá bí, jẹ́ ewu ńlá.
Nítorí náà, Búásì ṣe ohun tí ọkùnrin yìí ò ṣe. Ó gba ewu náà mọ́ ogún rẹ̀, ó sì ṣetán àti gbé gbogbo ojúṣe ogún Náómì àti ti ilẹ̀.
Gbogboèrò òǹwòran ló mọ̀ pé Rúùtù, opó, àjèjì àti aláìlọ́mọ pẹ̀lú Náómì opó ni ìpèsè wà fún ní àrà ọ̀tọ̀. Wọ́n gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ṣe Rúùtù bí àwọn ìyá ńlá Isírẹ́lì – Résẹ́lì, Líhà, àti Támà. Lẹ́yìn ọ̀rẹyìn, Ọlọ́run dáhùn àdúrà wọn, Rúùtù bímọ tí otúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Óbédì lẹ̀yìn tí ó ti yàgàn fún ọdún mẹ́wàá.
Ariwo sọ nílùú fún ayọ̀. Ní báyìí, kìí kan ṣe inú Búásì ni Náómì ti ní olùràpadà, ó tún ní in nínú ọmọ tuntun yìí. Nígbpa Óbédì bá dàgbà, yóó tọ́jú Náómì bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ogún rẹ̀ kò ní kú.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé náà, wọ́n rán wa létí pé Rúùtù gbé nígbà tí àwọn onídàájọ́ ń ṣe ìjọba, kò sì sí ọba ní Isírẹ́lì. Ṣùgbọ́n ìwé náà parí pẹ̀lú àkọsílẹ̀ ìran ọba. Óbédì jẹ́ bàba bàbáỌba Dáfídì (Rútù 4:22).
Èyí túmọ̀ sí pé Rúùtù kò kàn jẹ́ aláàńú. Búásì kò kàn jẹ́ olùfarajìn. Kìí kàn ṣe pé ìsófo Náómì ti kíkún. Àwọn ẹ̀dá yìí fi hàn wá bí Ọlọ́run ṣe ṣètò ìràpadà fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Nípasẹ̀ ojú rere àti ìfarajìn Rúùtù àti Búásì Ọlọ́rùn pèsè olùràpadà fún Náómì àti Isírẹ́lì..
Óbédì lọ́jọ́ kan yóó di bàbá ọba Dáfídì, tí òun náà yóo gorí ìtẹ́ lọ́jọ́ kan. Dáfídì yóó gbé gbogbo ojúse ajẹmọ́ ogún àti ilẹ̀ Isírẹ́lì bí i baba ńlá rẹ̀ Búásì ṣe gbé ojúṣe ogún àti ilẹ̀ Náómì. Bí ìyanu ìbí Óbédì ṣe mú ìtẹ̀síwájú bá ìran Náómì, Ọlọ́run lọ́nà ìyanu sọ fún Dáfídì pé irán rẹ̀ yóó máa jọba títí láé. Ọlọ́run ṣelérí fún ọmọ ọmọ Rúùtù pé ọmọ Dáfídì ni yóó ṣe ìjọba títí ayérayé
Olùkọ̀wé ìwé ìhìnrere Mátíù sọ fún wa pé Rúùtù àti Búásì kìí kan ṣe Baba ńlá Dáfídì, wọ́n tún jẹ́ ti Jésù náà. Ìran Óbádì àti Dáfídì ni Jésù ti wá. Gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá rẹ̀ ojú rere rẹ̀ àti ifara-ẹni-rúbọ rẹ̀ ni yóó gbà ìdílé rẹ̀ là lọ́wọ́ ìparun. Lórí igi àgbélébùú, Jésù di olùràpadà wa ìkẹhìn. Ó gbé gbogbo ojúṣe ìparun wa ti ara àti ti ẹ̀mí kí lè máa ní ogún, ilẹ̀ àti ìgbé-ayé.
Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe ṣe ìlé rí fún Dáfídì, Jésù wà láàyè, ó ń jọba, ó sì jíndé títí ayé. Gẹ́gẹ́ bí i Rúùtù àti Náómì, àwa náà lè gbé ìsófo wa wá bá a. A lè sọ fún un kí ó rà wá padà. A lè sọ fún Jésù kí ó gba ojúṣe ẹ̀sẹ̀ tí a sẹ̀, àti àìnírètí, kí ó sì ṣe nǹkan lórí wọn. Ìròyìn ayọ̀ ìwé Rútù ni pé Jésù yóó gbà wá gẹ́gẹ́ bí mọ̀lẹ́bí tó sún mọ́ ni àti Ọba alágbára!
Kí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣí ojú rẹ láti rí Ọlọ́run tí kìí fi àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ láì ni Olùràpadà. Kí o sì rí Jésù olùfararẹ̀rúbọ láti gbà wá ẹni tí ó kú láti gba gbogbo wa là.
Nípa Ìpèsè yìí
Ètò kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí jẹ́ awílé fún ìwé Rúùtù, ó sì ń ṣe àfihàn ìjólótìítọ́, ìwàláàyè, ìràpadà, àti àánú Ọlọ́run. Tí o bá rò pé o ti sọnù, tàbí o wà lẹ́yìn odi tí ò ń yọjú wọlé, ìtàn Rúùtù yóó ru ọ́ sókè, yóó sì gbé ẹ̀mí rẹ ró láti rán ọ létí pé Jésù, Olùràpadà wa tú oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ jade sórí àwọn tí wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/