RúùtùÀpẹrẹ
Rúùtù ti jẹ́jẹ̀ẹ́ àtìlẹyìn fún Nàómì opó aláìlọ́mọ. Ní àwọn ọnà kan, ó túmọ̀ sí pé, Rúùtù ti ṣetan láti ṣe bí ọmọ tàbí ọkọ fún Nàómì. Ó ti gba ojúse láti tọ́jú ìyakọ rẹ̀, ní bàyìí, àwọn méjéèjì ń febi panú. Nítorí náà, Rúùtù, ẹni tí ó ti mọ ìtàn ilẹ̀ ibí rẹ̀ tuntun ṣe àmúlò àwọn àǹfààní òfin inú Májẹ̀mú láéláé tí ó fàyè gba òtòsì láti sa ràlẹ̀rálẹ̀ erè oko ní àkókò ìkórè. Ní àìròtẹ́lẹ̀, Rúùtù bá ara rẹ̀ ní oko ọkùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Búásì.
Búásì gbọ́ nípa ìdojúkọ Rúùtù àtí pé gbogbo bí ó ṣe ń siṣẹ́ takuntakun láti ìgbà tí ilẹ̀ ti mọ́ ni wọ́n sọ fún un. Ó tún gbọ́ pé kìí kan ṣe ibi ràlẹ̀rálẹ̀ nìkan ni kí ó ti máa sa ohun tí ó fẹ́ (èyí tí i ṣe àlàkalẹ̀ òfin); ó tún lè mú nínú ẹ̀bìtì erè oko tí àwọn òsìṣẹ́ rẹ̀ kó kalẹ̀. Èyí ti kọjá àlàkalẹ̀ òfin ṣùgbọ́n ìjólótìítọ́ Rúùtù sí ìyakọ rẹ̀ Nàómì àti ọkàn akin tí ó fi béèrè ìtọ́jú tí ó yàtọ̀ kó Búásì ní papámọra láti lawọ́ ara ọ̀rọ̀ sí i. Ó wá pè é fún ouńjẹ ọ̀sán, ó sì pàṣẹ fún àwọn òsìṣẹ́ rẹ̀ láti fi ààyè gba Rúùtù kí ó mú ohunkóhun tí ó fẹ́. Rúùtù parí iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ouńjẹ tí ó tó iṣẹ́ oṣù kan.
Ó ya Nàómì lẹ́nu fún ojú àánú Búásì, Ó tún wá rántí pé ìbátan ni ó jẹ́ sí ọkọ òun tí ó ti di olóògbé àti pé “olùràpadà” ni. Ní ilẹ̀ Isírẹ́lì, olùràpadà kìí kan ṣe ọ̀rọ̀ lásán. Olùràpadà ẹbí kan ni ojúṣe ajẹmọ́ àwùjọ àti òfin láti tọ́jú àwọn ìbátan tí wọ́n jẹ́ òtòsì tí wọ́n sì wà ní ipẹkun àti pàdánù ilẹ̀ tàbí ogún wọn, pàápàá tí ọkọ wọn bá ti ṣe aláìsí.
Kìí kàn ṣe pé àìní Nàómì àti Rúùtù ti di bíbá pàdé nípasẹ̀ ọkunrin aláàánú náà ṣùgbọ́n Búásì gan-an jẹ́ àpọ́n (ẹni tí kò láya). Nínú Búásì ìrètí wà pé gbogbo ohun tí Nàómì àti Rúùtù padánù nínú ọkọ àti àwọn ọmọ ni yóó di gbígbà padà.
Ìgbé-ayé Náómì àti Rúùtù yí padà sí rere pẹ̀lú igboyà, ọkàn akin àti sísiṣkẹ́ kárakára Rúùtù. Búásì pe Rúùtù ní obìnrin rere nípasẹ̀ bí ó ṣe tẹ̀lé òfin Ọlọ́run àti ìtọ́jú Náómì.
Ní ìlànà àṣà, ìwé Rútù ni wọ́n gbé sí ẹ̀yìn ìwé Òwe Orí 31, tí a ṣe àpèjúwe obìnrin ọlọgbọ́n àti oníwà rere. Síṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí a rí Rúùtù gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n nínú àwọ̀ ènìyàn. Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìwé Òwe 31, ó máa ń jí ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti siṣẹ́ kárakára. Ó máa ń pèsè fún aláìní, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run.
Nígbà tí Rúùtù jẹ́ ọlọgbọ́n àti olóòótọ́, olùràpadà fi tọkàntọkàn pèsè. Èyí gan-an ni iṣẹ́ tí ìwé Òwe ń jẹ́. Nígbà tí a bá bẹ̀rù Ọlọ́run, tí a sì gbé ìgbé-ayé tí ó mú ọgbọ́n dání, Ọlọ́run yóó sán wá lẹ́san, yóó sì gbà wá.
Gẹ́gẹ́ bí i Rúùtù, Jésù náà jẹ́ ọgbọ́n nínú àwọn ènìyàn. Bí bí ọgbọ́n Rúùtù ṣe jẹ́ àfihàn ìfara-ẹni-rúbọ àti ìfaraẹnijìn fún Nàómì, bẹ́ẹ̀ náà ní Àpọ́sitélì Pọ́ọ̀lù náà ṣo fún wa nipa ọgbọ́n Jésù tí ó ṣe àfihàn ìfara-ẹni-fúbọ rẹ̀ nipa kíkú. Jésù lo ọgbọ́n rẹ̀ láti lọ sorí ige àgbélébùú fún wa, gẹ́gẹ́ bí Rúùtù ṣe lọ sí oko fún Náómì.
Gẹ́gẹ́ bí Búásì ṣe fi ojú-àánú wo Rúùtù tí ó kọjá ìkọsílẹ̀ òfin, Jésù náà fi ojú-àánu wò wá tí ó kọjá òfin. Òfin sọ pé Rúùtù ní ẹ̀tọ́ sí ràlẹ̀rálẹ̀ ààlà oko, kò sì lẹ́tọ̀ọ́ láti mú nǹkankan ní àárín oko. Bẹ́ẹ̀ náà ni òfin sọ pé ẹlẹ́sẹ̀ bí wa yẹ kí ó jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa nipa ikú, a kò sì ní ẹ̀tọ́ láti bá Ọlọ́run jẹun ni inú àwo kan náà.
Bẹ́ẹ̀, Jésù nínú ọgbọ́n rẹ̀ fún wa ju ohun tí òfin sọ pé a ní ẹ̀tọ́ sí lọ. Gbogbo ohun tí a ní láti ṣe láti gba ojú-àánú yìí ni kí a fi ọgbọ́n bèèrè, gẹ́gẹ́ bí Rúùtù ṣe ṣe.
Kí Ẹ̀mí Mímọ́ sí ojú rẹ l’sti rí Ọlọ́run tí ó máa ń pèsè. Kí o sì rí Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni tí fi ìjólótìítọ́, ọgbọ́n, ìfiara-ẹni-rúbọ sọ wá di ìdílé rẹ.
Nípa Ìpèsè yìí
Ètò kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí jẹ́ awílé fún ìwé Rúùtù, ó sì ń ṣe àfihàn ìjólótìítọ́, ìwàláàyè, ìràpadà, àti àánú Ọlọ́run. Tí o bá rò pé o ti sọnù, tàbí o wà lẹ́yìn odi tí ò ń yọjú wọlé, ìtàn Rúùtù yóó ru ọ́ sókè, yóó sì gbé ẹ̀mí rẹ ró láti rán ọ létí pé Jésù, Olùràpadà wa tú oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ jade sórí àwọn tí wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/