RúùtùÀpẹrẹ
Rúùtù mú wan í ìrètí nínú ọbá tí ó lè mú rírí jade nínú àìrí.
Kí ìtàn Rúùtù tó wáyé, a jẹ́ ká mọ pé Isírẹ́lì wà ní àkókò àwọn onídàájọ́. Ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ àkókò tí ó polúkúnusu jù fún Isírẹ́lì, èyí tí ó kún fún ìfìyàjobìnrin àti àìní adarí tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run. Rúùtì àti Nàómì, àwọn olú ẹ̀dá ìtàn, yàtọ̀ gédégédé láàrín àwọn obìnrin gẹ́gẹ́ bí olótìítọ́ obinron láàrín ìràn àwọn ọkunrin tí ò lóòtọ́. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù, ayé wọn kún fún ìdààmú àti ikú. Ísírílẹ́lì wa nínú ìyàn. Ọkọ àti ọmọkunrin Nàómì méjéèjì tik ú. Nàómì kò ní ìgbésí-ayé kankan mọ́ ní Ísírẹ́lì; ó ń jìṣẹ́ ní Móábù tíi ṣe ọ̀tá pípẹ́ fún Ísírẹ́lì. Àwọn olùtùnú tí ó kù kù ú ni àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjéèjì tí wọ́n yàgàn, Rúùtù àti Ọ́pà.
Ipò Nàómì dàbí ipò àìnírètí. Nínú àṣà yìí, ìrètí kan soso tí ó kù fún àwọn obìnrin mẹ́tẹ̀ta ni kí wọ́n yálà ni ọmọkpunrin tàbí kí wọ́n fẹ́ olówó. Kò sí ]eyí tí ó ṣe é ṣe nínú méjéèjì fún àwọn àjèjì, arúgbó obìnrin tó tún yàgàn.
Nàómì ṣàkíyèsí pé ìrètí kan tí ó kù ni kí òun padà sí ìlú abínibí rẹ̀ tíi ṣe Bẹtilẹhẹ́mù. Nàómì kò fún àwọn aya-ọmọ rẹ̀ Rúùtù àti Ọ̀pà ní ìwúrí láti tẹ̀lé e. Gẹ́gẹ́ bí ọbìnrin aráa Múabù, ohun tó dájú ni pé ìkórìíra yóó pọ̀ fún wọn gẹ́gẹ́ ẹ̀yá tí ó kéré ní Ísírẹ́lì. Nítorí náà, Ọ́pà padà sílé, ṣùgbọ́n Rúùtù fi àtilẹ́yìn tí ó gbópan hàn sí Nàómì. Dípò kí ó padà, Rúùtù kéde pé Ọlọ́run Nàómi ni Ọlọ́run òun àti pé àwọn ènìyàn Nàómì ti di àwọn ènìyàn òun. Kàkà kí òun padà, òun yóó yà kú pẹ̀lú Nàómì ni.
Nítorí náà, wọ́njọ kúrò ni Móábù. Rúùtù àti Nàómì, àwọn obìnrin tí wọ́n yàgàn tí ebi sì t;un pa dé Bẹtilẹ́hẹ́mù. Ṣùgbọ́n bí ìtasínilétí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún wọn ati fún Isírẹ́lì, àkókò tí wọ́n dé sí ni ìkórè báli ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ (Rútú1:22). Ní àìpẹ́ ìsófìfo wọn yóó di kíkún, a ó sì bí ọba kan.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìtàn Ísírẹ́lì, àwọn ìyá ńlá wọn, Sérà, Rèbékà àti Réṣẹ́lì kò tètè rọ́mọ bí. Ọlọ́run ní ọ̀nà ìyanu sí inú wọn fún ọmọ, ó sì pèsè adarí tuntun fún àwọn ènìyàn rẹ̀.À ń retí kí ìtàn tún ṣẹlẹ̀ níbí, ṣùgbọ́n dípò ríbẹ́ẹ̀ bí àwọn ìtàn yẹn, kò sí ọkunrìn tí yóó ṣe ìrànlọ́wọ́ ọmọ bíbí. Rúùtù kan dá wà ni, opóbinrìn tí ó tún yàgàn ní ilẹ̀ agègì.
Ìfarajìn Rúùtù láti fi ara rẹ̀ rúbọ fún ìyakọ rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì fún Ọlọ́run láti pèsè ọba tuntun fún Ísírẹ́lì, a ó sì lórí rẹ̀ ní Rútù Orí Kẹrin.
Gẹ́gẹ́ bí Rúùtù, Màríà jẹ wúndíá tí k[po yẹ kí ó tíì lọ́mọ. Àmọ́, ìfarajìn Màríà láti sin Olúwa túmọ̀ sí pé nipa Màríà, a ó bí Ọba tí yóó bùkún gbogbo ayé nipa ìjọba rẹ̀. Jésù jẹ́ ọmọ ìjólótìítọ́ Rúùtù àti Màríà. A ó sì bí Jésù sí ìlú abínibí Nàómì tí I ṣe Bẹtilẹ́hẹ́mù! Ó jẹ́ Ọba ní tòótọ́, tí kìí ṣe fín Ísírẹ́lì nìkan, ṣùgbọ́n fún gbogbo ayé. A bí kí ó lè kún ìsófìfo wa nipa ìjọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba.
Nítorí náà, bí ìwọ náà bá ya àgàn bí I Rúùtù, bí o bá di opó bí i Nàómì, bí o kò bá ní adarí bí i Ísírẹ́lì, bí ebi bá ń pa ọ́, tàbí o ya òtòsì, síbẹ̀ bó yá ó dàbí ẹni pé kò sí ọgbọ́n tàbí ìmọ̀ tí ó lè jẹ́ kí ó dábí òpin kò ní dé bá ìsófo rẹ, ìwé Rúùtù wà fún ọ. A ti bí ọmọ kan, orúkọ rẹ̀ sì ni Jésù. Bí ìwọ náà ba fi ara rẹ jìn bí i Rúùtù sí Jésù Ọba, gbogbo ohun tí o fẹ́ ni yóó pèsè.
Kí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣí ojú rẹ láti rí Ọlọ́run Ọba, kí o sì rí Jésù gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ tí ó tó fẹ̀yìntì tó yóó tán gbogbo òǹgbẹ rẹ.
Nípa Ìpèsè yìí
Ètò kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí jẹ́ awílé fún ìwé Rúùtù, ó sì ń ṣe àfihàn ìjólótìítọ́, ìwàláàyè, ìràpadà, àti àánú Ọlọ́run. Tí o bá rò pé o ti sọnù, tàbí o wà lẹ́yìn odi tí ò ń yọjú wọlé, ìtàn Rúùtù yóó ru ọ́ sókè, yóó sì gbé ẹ̀mí rẹ ró láti rán ọ létí pé Jésù, Olùràpadà wa tú oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ jade sórí àwọn tí wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/