RúùtùÀpẹrẹ
Rúùtù àti Náómì sẹ̀sẹ̀ mọ̀ pé Búásì jẹ́ ọ̀kan nínú mọ̀lẹ́bí wọn tí ó lè ṣe ìràpadà. Ní Isírẹ́lì, olùrapadà ní ojúṣe ajẹmọ́ àwùjọ àti òfin láti tọ́jú àwọn ẹbí tí wọ́n jẹ́ òtòsì pàápàá àwọn opó. Nínú ipò rẹ̀ lọ́wọ́ báyìí, Náómì yóó nílò láti ta ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ láti wà láàyè. Ṣùgbọ́n bí Búásì bá lè fẹ́ Rúùtù, ìsòro wọn yóo di yíyanjú. Nípasẹ̀ Búásì, ó dà bí ẹni pé ìsófo wọn ti wá dópin. Ṣùgbọ́n Rúùtù náà jẹ́ opó tí ó sì tún jẹ́ òtòsì, àgàn, àti àjèjì. Kò dájú pé Búásì yóó gba Rúùtù gẹ́gẹ́ bí ẹnìkejì rẹ̀.
Nítorí náà, Náómì dágbọ́n tí ó léwu láti pete ìgbéyàwó fún Búásì. Rúùtù nílò láti múra, kí ó wọsọ, kí ó sì lo tùràrí olóòórùn dídùn, kí ó sì dúró títú orun yóó fi kun Búásì lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jẹun ńlá tán. Kí ó wá sí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀, kí ó sì sùn sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Náómì fi làákáyè gbé ètò rẹ̀ kalẹ̀ nítorí pé ó dúró títí Búásì fi jẹun yó, tí inú rẹ̀ sì dùn. Sísí asọ lẹ́sẹ̀ Búásì túmọ̀ sí pé ní àkókò kan lóru, Búásì yóó jí pẹ̀lú àtútù, yóó sì yá á lẹ́ láti rí Rúùtù àrẹwà lẹ́sẹ̀ rẹ̀ tí òun náà rọra sùn jẹ́jẹ́. Ètò yìí wà ní bèbè àìbójúmu: kí ọkùnrin kan àti obìnrin kan wà papọ̀ nínú òkùnkùn lálẹ́, kí wọ́n jọ sùn sí ibìkan náà, ní ibi tí ojú ò ti lè rí wọn. Rúùtù tilẹ̀ sí aṣọ lára rẹ̀. Ewu ìbálòpọ̀ rẹ̀ pọ̀ bí àtunbọ̀tán rẹ̀ bí Búásì bá gbé èrò náà gba ibi tí kò dára. Ṣùgbọ́n Búásì gbà láti tẹ̀lé àbá Náómì.
Ṣùgbọ́n Rúùtù kò ṣe bí a tifẹ́. Nígbà tí Búásì jí, tí ó sì rí I, Rúùtù kò dúró kí ó fọhùn. Dípò bẹ́ẹ̀ Rúùtù dábàá ìràpadà, kìí kan ṣe ìgbéyàwó nìkan nítorí Náómì àti ogún rẹ̀. Rúùtù pe Búásì ní “olùràpadà”. Ó fẹ́ kí Búásì gbé òun ní ìyàwó ṣùgbọ́n kìí ṣe fún àǹfààní ara rẹ̀ nìkan bí kò ṣe ti Náómì. Òpó ìdìlé yóó parẹ́ bí Búásì ò bá ràn wọ́n lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n bí Búásì bá fẹ́ ẹ, ọmọ tí Rúùtù bá bí jẹ́ ọmọ ọmọ Náómì, ilẹ̀ ìdílé Náómì yóó sì wà fún wọn.
Àtìlẹyìn Rúùtù sí Náómì ya Búásì lẹ́nu púpọ̀. Kìí kan ṣe pé ó fi ilẹ̀ abínibí rẹ̀ sílẹ̀, ó tún ṣetán àti fi ìgbéyàwó rẹ̀ tẹ́ Náómì lọ́rùn dípò ìfẹ́ in;u tara rẹ̀ nìkan.
Búásì fẹ́ jọ́hẹn ṣùgbọ́n ìsoro kan tún kù. Olùrapadà mìíràn wat í òun náà lẹ́tọ̀ọ́ sí i.
Nínú gbogbo ìtàn Rúùtù àti Náómì, ọ̀rọ̀ Hébérù kan ṣe pàtàkì tí ó yẹ kí ó yé wa. Ó ṣe é ṣe kí ó jẹ́ pé òun ni wọ́n túmọ̀ sí ojú-àánú nínú Bíbélì rẹ.
Wọ́n sọ fún wa pé Rúùtù ní Inú rere sí Náómì nípaa kíkúrò ní ilẹ̀ìbí rẹ̀. Búásì ṣe inú rere sí Rúùtù nípà fífún Rúùtù àti Náómì ní ọ̀pọ̀ ouńjẹ. Búásì pe àbá ìgbéyàwó Rúùtù gẹ́gẹ́ bí inú rere pẹ̀lú. Inú rere ti Rúùtù mà kúrò ní ìwà rere ṣùgbọ́n níní àtìlẹyìn tó nípọn. O gba Rúùtù ní ohun tí ó pọ̀ láti fi ilẹ̀ ìbí rẹ̀ sílẹ̀. Àbá ìgbéyàwó tí Rúùtù dá fún Búásì pè fún jíjọ́wọ́ ìgbéyàwó fún ìfẹ́ àti owó. Bí a ó sì ti rí I ní orí tó kan, gbígbà àbá ìgbéyàwó yìí ná Búásì ní owó púpọ̀ láì sọ àwọn ohun mìíràn tí ó ná an láwùjọ nipa fífẹ́ àgàn tí ó tún jẹ́ àjèjì.
Ìgbà àkọ́kọ́ tí a ó gbọ́ nipa inú rere yìí ni ìgbà tí Ọlọ́run ;n júwe ara rẹ̀ fún àwọn ará Isírẹ́lì lórí òkè Síónì. Olọ́run ni. Ọlọ́run ni òun ni olótìítọ́ àti onínú rere tí ó dájú. Òun yóó nífẹ̀ẹ́ Isírẹ́lì lábẹ́ bí ó ti wù kó rí. Nínú Rúùtù àti Búásì, a rí àwòrán ìwàláàyè ojú rere Ọlọ́run, a sì tún rí àwòrán ìwàláàyè ìfẹ́ Jésù sí wa.
Nínú ìjẹ́-olótìítọ́ ilérí Ọlọ́run fún ojú rere tí ó gbangbọ́n, Jésù fi ilẹ̀ abínibí rẹ̀ sílẹ̀ láti fẹ́ aya tí ó ná an ní owó iyebíye fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni bí Rúùtù ò ṣe dá Búásì lóhùn nítorí pé ó rẹwà tàbí nítorí pé ó jẹ́ olówó, Jésù kò da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ wa nítorí pé àwa ni a dára jù tàbí gbọ́n jù, Jésù kú fún wa nítorí ojú àánú àti ijẹ́-olótìítọ́ rẹ̀ fún wa. Àánú tí ó ní fún àwọn aláìní, àti ìjẹ̀-olótìítọ́sí ilérí tí ó ṣe.
Nitorí náà, ǹjẹ́ o nílò ojú rere láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ o fẹ́ àgbà ìyànu àánú áti bá gbogbo ohun tí o nílò pàdé? Lọ́rọ̀ kan, dàbí Rúùtù. Sùn sí ẹsẹ̀ rẹ̀, kí ìwọ náà dábàá. Yanya yàǹyà ni kí o sọ fún ewu tí ó wà níbẹ̀ bí kò bá dáhùn, kí ni ìgboyà nínú Ọlọ́run tí àánú rẹ̀ pọ̀ ju ti Búásì lọ, yóó sì fún ọ ní gbogbo ohun tí o fẹ́.
Wo ara rẹ
Kí Ẹ̀mí Mímọ́ sí ọ lójú ;ati rí Ọlọ́run tí ó máa ń fi apá rẹ̀ bò wá. Kí ó sì rí ìjẹ́-olótìítọ́ àti ojú rere Jésù bí ó ṣe ń sọ ara rẹ̀ di òfo kí àwa kí ó lè kún.
Nípa Ìpèsè yìí
Ètò kíkà ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí jẹ́ awílé fún ìwé Rúùtù, ó sì ń ṣe àfihàn ìjólótìítọ́, ìwàláàyè, ìràpadà, àti àánú Ọlọ́run. Tí o bá rò pé o ti sọnù, tàbí o wà lẹ́yìn odi tí ò ń yọjú wọlé, ìtàn Rúùtù yóó ru ọ́ sókè, yóó sì gbé ẹ̀mí rẹ ró láti rán ọ létí pé Jésù, Olùràpadà wa tú oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ jade sórí àwọn tí wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀.
More
A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Spoken Gospel fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: http://www.spokengospel.com/