Kristi Imole t‘o da wa sileÀpẹrẹ

Kristi Imole t‘o da wa sile

Ọjọ́ 5 nínú 7

Kristi oni Kọọ Sílẹ

Ọkàn ninu awọn ileri Ọlọrun to gajulo sí ọ ni;

"...Nitori on tikalarẹ ti wipe, Emi kò jẹ fi ọ silẹ, bẹni emi kò jẹ kọ ọ silẹ". Heberu 13:5.

Ọlọrun aṣi mā s'olotọ nigbati àwa bá ṣ'alaiṣõtọ. Kini idi? Ọlọrun amā dúró tí ọrọ Rẹ, otitọ ni Ọlọrun kò ní dá ọrọ Rẹ.

Kristi ni Ọlọrun otitọ kan ṣoṣo. O s'olõtọ to bẹ̀ ..."ti npa majẹmu mọ́ ati ãnu fun awọn ti o fẹ́ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ́ dé ẹgbẹrun iran" Diutaronomi 7:9.

Tani ẹni tó lè borí ipele iṣotitọ bi eleyii? Títóbi ni otitọ Ọlọrun, kìí yẹ̀ lailai nitori Ọlọrun olè ku'na.

Nigbati gbogbo ènìyàn bá kọọ, Ọlọrun olè kọọ. Isaia 49:15-16.

Ni akoko ipọnju, ìṣokúnkun, akoko Aini, akoko éwu ati ikú Ọlọrun le wa pẹlu rẹ lati tú ọ nínú

Oluwa mo gbagbọ pe olóòtọ ni Ẹ, iwọ kiõ fimi silẹ tabi kọmi silẹ.

Ìwé mímọ́

Day 4Day 6

Nípa Ìpèsè yìí

Kristi Imole t‘o da wa sile

Fun gbogbo àkókò òkunkun - ibẹrubojo ati sáà ìyè meji, àkò le ṣe alaimanilo imọlẹ gidgidi ni oniruru ọna. Láti fún wa ní Òye nípa ipò tí a wá tabi ọgbọn fún ìyípadà ilakọja ti ko dára fún réré. Eleyi ni jesu wá sí ayé láti musẹ. O sọ nínú ọrọ iṣẹ rẹ wípé "Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun Johanu 8:12.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Adeoye Gideon fún pípèsè ètò yìí. Fún ìsọfúnni síwájú sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.facebook.com/gideon.adeoye?mibextid=ZbWKwL