Fi ise Re le OluwaÀpẹrẹ

Commit Your Work to the Lord

Ọjọ́ 4 nínú 4

Dídúró Déédéé


Láàárọ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, mo máa ń ronú nípa ohun tí mo fẹ́ ṣe lọ́jọ́ náà.

Kíni mo fẹ́ ṣe lónìí? Báwo ni mo ṣe lè ṣe é?

Ohun tí mo rí ni pé kí n tò lè gbé àwọn ètò mi kalẹ̀, mo gbọ́dọ̀ je kí iṣẹ́ ojoojúmọ́ mi bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.

Mo ti gbìyànjú láti ṣe àwọn ohun kan ní ọ̀nà mi, àti àwọn ohun mìíràn pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, mo sì lè fi ìdánilójú sọ pé ọ̀nà Rẹ̀ dára ju t'èmi lọ!

Síbẹ̀, ó wà nínú ìwà àwa ènìyàn láti gbé ara lé òye wa tí kò kún tó. A ó rí apá kékeré kan nínú àwòrán náà, a ó sì ṣe àwọn ìpinnu tí ń yí ìgbésí ayé wa padà ní ìbámu pẹ̀lú ohun kíńkíń tí a rí. O ò ṣe gba ìmọ̀ràn Ọlọ́run, tí Ó rí ohun gbogbo?

Fífi iṣẹ́ ẹni lé Olúwa lọ́wọ́ kò rọrùn. Ìpinnu ojoojúmọ́ tí ó sáábà máa ń pọn dandan pé kí a fi ipá mú ara wa ṣe ni, bíótilẹ̀ jẹ́ pé a kò ní òye rẹ̀ ní ìgbà náà. Ìfarajì gba ìkóra-ẹni-níjàánu, a sì gbọ́dọ̀ dàgbà nínú ìkóra-ẹni-níjàánu yìí. A gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìgbésí ayé wa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Àwọn ìpinnu tí á ń ṣe lónìí ṣe pàtàkì. Ìpinnu láti fetí sí ìtọ́sọ́nà Rẹ̀ tàbí láti tẹ̀lé òye ara wa a máa w'áyé ní gbogbo ìgbà.

Mo rọ̀ ọ́ láti gbé ìgbé ayé tí ó kún fún ìfarajî. Ìdúróṣinṣin wa yóò mú kí àwọn àlá àti ìpọ̀ǹgbẹ tí Ọlọ́run fún wa wá sí ìmúṣẹ. Nípa fífi iṣẹ́ wa lé Olúwa lọ́wọ́, áti títẹ̀lé ìtọ́ni Rẹ̀, àwọn ètò wa yóò fi ìdí múlẹ̀.

Ọlọ́run rí àwọn àlá rẹ.
Ó rọra ṣe ẹ̀dá rẹ̀ ní ọ̀nà tí ìwọ yóò fi mú wọn wá sí ìmúṣẹ.
Ó ti fi ara Rẹ̀ fún ọ.

Nísinsìnyí, fi iṣẹ́ rẹ lé E lọ́wọ́.

Láti lè bá David Villa sọ̀rọ̀ pọ̀, Tẹ Ibi yìí!

Láti lè fi orúkọ s'ílẹ̀ fún àkáálẹ̀ ẹ̀rọ-agbagbe David, Tẹ Ibi yìí!

Ìwé mímọ́

Day 3

Nípa Ìpèsè yìí

Commit Your Work to the Lord

Darapọ̀ mọ́ David Villa nínú ètò ìfọkànsìn rẹ̀ àjáàbalẹ̀ bí ó ti ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ipa tí ó jinlẹ̀ tí fífi iṣẹ́ wa lé Olúwa lọ́wọ́ ń kó nínú ayé wa.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ David Villa fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, kàn sí: https://davidvilla.me/