Fi ise Re le OluwaÀpẹrẹ

Commit Your Work to the Lord

Ọjọ́ 2 nínú 4

Àwọn Èrò Òdí àti Òye Kooro


Bíótilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpinnu wa sáàbà máa ń dá lórí àwọn àfojúsùn ọlọ́jọ́ gbọọrọ àti àwọn ètò wa fún ọjọ́ iwájú, kò tó láti kàn fi àwọn ètò wa fún ọjọ́ iwájú lé Ọlọ́run lọ́wọ́ nìkan.

Dípò bẹ́ẹ̀, a ní láti yọ̀ǹda àwọn ìgbésẹ̀ wa ojoojúmọ́ àti àwọn ojúṣe wa fún Ọlọ́run.

A gbọ́dọ̀ máa ṣe èyí ní ojoojúmọ́, láì ka bóyá a ní èrò rere tàbí a kò ní sí.

O ò rí i, ó wọ́pọ̀ láti tọ Ọlọ́run lọ ní ìgbà tí a bá wà nínú ìṣòro, ṣùgbọ́n ó tún yẹ kí a máa rántí láti bá A sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́. Yálà a fẹ́ béèrè fún ìrànlọ́wọ́, ìtọ́sọ́nà, tàbí òye, tàbí a kàn fẹ́ mọ bí nǹkan ṣe ń lọ, bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ ń jẹ́ kí á lè máa ṣe ohun tí ó bá ìfẹ́ Rẹ̀ mu. Ní ìgbà tí a bá ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́, a ń fún Un ní àǹfààní láti ṣe àtúnṣe pẹ̀lẹ́kùtù àti àyípadà nínú ìrìn àjò wa, kí a lè dúró ní ipa ọ̀nà náà kí a sì mú àwọn ètò Rẹ̀ fún wa ṣẹ.

Ìtumọ̀ òdì tí àwọn ènìyàn sáàbà maá ń fún Òwe 16:3 ni pé ó yẹ kí á fi ètò wa lé Olúwa lọ́wọ́. Bí èyí tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹsẹ yìí yànàná pé a gbọ́dọ́ fi iṣẹ́ wa lé Olúwa lọ́wọ́.

Kíni èyí túmọ̀ sí?

Èyí túmọ̀ sí pé bíótilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa ní ìgbà gbogbo, tí Ó sì ń fẹ́ ohun tí ó dára fún wa ní ìgbà gbogbo, Òun náa ń retí pé kí á sa ipa tiwa!

Ẹni tí ó ń gbèrò tí kò sì gbé ìgbésẹ̀ kò ní í rí àwọn èrò rẹ̀ kí ó wá sí ìmúṣẹ. Ọlọ́run kò fẹ́ kí a jókòó tẹtẹrẹ, kí á máa retí pé kó dá sí ọ̀ràn wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Olúwa, kí a máa fi iyè sí ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà Rẹ̀, kí á sì máa tẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ tí ó ti pinnu fún wa. Rántí pé, bíótilẹ̀ jẹ́ pé ipò tí a wà nísinsìnyí nìkan ni a mọ̀, Ọlọ́run mọ ohun gbogbo tí yíó ṣẹlẹ̀ sí wa. Ìdí nìyìí tí Ó fi maá ń gbé wa sí àwọn ipò tí a kì í sábà ní òye rẹ̀. Ìdí ni pé ó ní òye àti ọgbọ́n láti mọ̀, kìí ṣe ibi tí a wà nìkan, ṣùgbọ́n ìdí tí a fi à ní ibẹ̀!

Bí a bá fẹ́ fi iṣẹ́ wa lé Olúwa lọ́wọ́ nítòótọ́, a gbọ́dọ̀ máa fetí sí àṣẹ Rẹ̀.

A kò lè tẹ̀síwàjú pẹ̀lú àwọn ètò ti ara wa àyàfi bí a bá sọ fún Un, tí a sì bèèrè fún ọgbọ́n Rẹ̀ láti rí i pé a mú wọn wá sí ìmúṣẹ.

Ìwé mímọ́

Day 1Day 3

Nípa Ìpèsè yìí

Commit Your Work to the Lord

Darapọ̀ mọ́ David Villa nínú ètò ìfọkànsìn rẹ̀ àjáàbalẹ̀ bí ó ti ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ipa tí ó jinlẹ̀ tí fífi iṣẹ́ wa lé Olúwa lọ́wọ́ ń kó nínú ayé wa.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ David Villa fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, kàn sí: https://davidvilla.me/