Fi ise Re le OluwaÀpẹrẹ
Gbígbé Ìgbésí Ayé Ìfarajì
Ní ìgbà tí á bá fi gbogbo ìgbésí ayé wa sin Ọlọ́run nínú ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́, agbára kan wà tí kì í ṣe àwa nìkan ni ó ń rí i, àwọn tí ó wà ní àyíká wa náà ń rí i pẹ̀lú.
Ìyípadà yìí ni ó yí ohun gbogbo padà. A máa mú kí àwọn ènìyàn máa béèrè ohun tí ó yàtọ̀ nípa rẹ, a sì fún ọ ní ìgboyà láti ṣiṣẹ́ kárakára láti mú àwọn àlá rẹ ṣẹ. Ní ìgbà tí Ọlọ́run bá wà nínú ìgbésí ayé wa, ìgbésí ayé wa yíó ní ipa rere. Àwọn ìṣe wa yío kọja iṣẹ́ ojoojúmọ́ lásán.
Ní ìgbà tí a bá yọ̀ǹda ara wa gẹ́gẹ́ bí ohun èlò fún ògo, Ọlọ́run yíó lò wá bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Rántí pé Ọlọ́run tí á ń sìn ẹni tí kìì yí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ padà ni, Ó sì ti ṣe ìlérí fún wa wípé bí á bá fi àjọṣe wa pẹ̀lú Òun sí ipò àkọ́kọ́, Òun yóò mú àwọn ètò wa ṣẹ.
Gbígbé ìgbé ayé ìfarajì kò túmọ̀ sí pé a ò ní rí ìṣòro. Èyí kò túmọ̀ sí pé a ó jí tayọ̀tayọ̀ pẹ̀lú ara yíyá gágá lójoojúmọ́ ayé wa. Àmọ́, ó ń fúnni ní ìṣírí ńláǹlà àti ìpinnu láti borí àwọn àkókò tí ó le koko. Ìgbésí ayé ìfarajì ní ìtọ́sọ́nà, nítorí a mọ̀ pé a kò ṣiṣẹ́ fún ara wa nìkan, ṣùgbọ́n a ń ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run áti pẹ̀lú ìbùkún Ọlọ́run.
Ọlọ́run fẹ́ kì á ní àlá ńlá kì á sì mú àwọn àlá náà ṣẹ. Ọlọ́run tún mọ ipa ọ̀nà tí ó yẹ kí á tọ̀ kí èyí tó lè wá sí ìmúṣẹ. L'ọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ènìyàn máa ń rò pé àwọn ń dúró de Ọlọ́run, ní ìgbà tí ó jẹ́ pé, Òun ní Ó ń dúró dè wá! Ó ń dúró dè wá láti gbé ìgbésẹ̀, láti mú àwọn àlá tí ó fi sínú ọkàn wa wá sí ayé. Ní ìgbà tí á bá ṣè ìpinnu láti gbé ìgbé ayé tí ó fi ara jì fún Olúwa, ní a ó bẹ̀rẹ̀ sí máa ro oko mọ́ àwọn àlá wọ̀nyí.
Láìsí ìfarajì fún Ọlọ́run, níṣe ni à ń rìn gbéregbère láì sí ìdarí. Àìsí àfojúsùn yóò mú wa gbá káàkiri.
Ìgbésí ayé ìfarajì máa ń fún wa ní àǹfààní lári t'ukọ̀ dé èbúté yíyanjú.
Fi ara rẹ jì fún Olúwa, yóò sì darí rẹ sí ọ̀nà ìsọnidińlá.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Darapọ̀ mọ́ David Villa nínú ètò ìfọkànsìn rẹ̀ àjáàbalẹ̀ bí ó ti ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ipa tí ó jinlẹ̀ tí fífi iṣẹ́ wa lé Olúwa lọ́wọ́ ń kó nínú ayé wa.
More