Fi ise Re le OluwaÀpẹrẹ
Ríru Ìrètí àti Àlá S'ókè
Ǹǹkankan kan wà nípa ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun tí ó maá ń rú àwọn èrò kan pàtó s'ókè.
Ọ̀pọ̀ nínú wa ni a ti la àwọn ìpinnu wa kalẹ̀, a sì ti gbìyànjú láti rí i dájú pé àwọn ìyípadà náà yọrí sí rere. Kódà, mo máa ń sọ pé à ń lo èyí tí ó pọ̀ jù nínú oṣù mẹ́rin àkọ́kọ́ nínú ọdún láti fi ṣe àtúntò àwọn ìrètí àti àlá wa, tí a sì ń mú wọn kúrò nínú ìpamọ́ tí a fi wọn sí ní ìgbà tí ǹǹkan lọ'jú pọ̀.
Ìwà ẹ̀dá ni pé kí á máa ronú lórí ohun tí à ń fẹ́, ohun tí à ń gbèrò àti ohun tí à ń lépa ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun. Ìgbésẹ̀ yìí wọ́pọ̀, nípa pé à ń retí ìyípadà àti àtúnṣe, a sì ń nàgà láti rí i pé Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn náà, kí Ó sì ràn wá lọ́wọ́ nínú ìsapá wa. A máa ń wéwèé bí a ó ṣe máa jẹun ní ọ̀nà tí ìlera, bí a ó ṣe jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò t'ọ̀nà, bí a ó ṣe fi owó pamọ́ tàbí bí a ó ṣe ṣe àwọn nǹkan tí a ti patì tipẹ́tipẹ́.
Ó bani nínú jẹ́ pé, ìwádìí ti fi hàn léraléra pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìpinnu wọ̀nyí ni wọn kìí ní ìparí. Ọ̀pọ̀ ni wọ́n yíó ti gbàgbé nípa wọn kí oṣù Ṣẹ́rẹ́ tó parí. Báwo ni a ṣe lè rí i dájú pé àwọn ìpinnu wa, àwọn àfojúsùn wa, àti àwọn àlá wa wá sí ìmúṣẹ láàrin ọdún yìí?
Ó bẹ̀rẹ̀ nípa pé kí a fí iṣẹ́ wa lé Olúwa lọ́wọ́.
Ìwé-òwe 16:3 sọ fún wa pé bí a bá fi iṣẹ́ wa lé Olúwa lọ́wọ́, a ó fi ìdí ìrò-inú wa kalẹ̀. Nítorí náà, kì í ṣe pé a ní láti pe Ọlọ́run sínú ètò ìpinnu wa nìkan, ṣùgbọ́n a tún ní láti fi etí sí ìtọ́ni Rẹ̀ kí a lè mú àwọn ètò náà ṣẹ ní kíkún. Ní ìgbà tí a bá rí i pé ọwọ́ wa dí gan-an, a lè bẹ Ọlọ́run pé kí ó fún wa ní okun àti ìmúlọ́kànle láti tẹ̀síwájú nínú ìlépa àwọn àfojúsún wa tí a lá kalẹ̀. A gbọ́dọ̀ jọ̀wọ́ àwọn ìgbésẹ̀ wa, èrò wa, àti ojúṣe wa fún Ọlọ́run.
Nípa pípè Ọlọ́run láti darapọ̀ mọ́ ìrìn àjò wa, a kò ní tètè di ẹni tí àwọn ìdènà tí ó ń bọ̀ ń dí lọ́wọ́.
Ní ìgbà tí a bá sinmi lé agbára ara wa, a lè já ara wa kulẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.
Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí a bá gbé ara lé Ọlọ́run, kò ní í já wa kulẹ̀ láí.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Darapọ̀ mọ́ David Villa nínú ètò ìfọkànsìn rẹ̀ àjáàbalẹ̀ bí ó ti ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ipa tí ó jinlẹ̀ tí fífi iṣẹ́ wa lé Olúwa lọ́wọ́ ń kó nínú ayé wa.
More