Àdúrà 5 ti Ìrẹ̀lẹ̀Àpẹrẹ

5 Prayers of Humility

Ọjọ́ 5 nínú 5

Àdúrà 5: “Olúwa, Fún Mi Ní Ọkàn Tí O Gb'ọgbẹ́ Tí Ó Sì K'áàánú. ”

Orin Dáfídì 51 jẹ́ Sáàmù tí mo fẹ́ràn jùlọ láti máa kà nígbà tí mo bá mọ̀ pé mo ti ṣẹ̀ sí Ọlọ́run.

Ó hàn pé, èmi kò fẹ́ ṣẹ̀ rárá. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo wa, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan mo máa ń dá ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà tí ó sì jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni mo máa ń bẹ́ Ọlọ́run pé kí ó má jẹ̀ kí n jìnnà sí Òun, ìdálẹ́bi ọkàn Rẹ̀ máa ń bẹ̀rẹ̀ ní kété tí mo bá ti ṣẹ̀ sí I.

Nígbà tí mo bá ṣẹ̀. nígbà míràn mo máa ń ní ìrònúpìwàdà ọkàn láti ìbẹ̀rẹ̀ gan-an.

Ní irú àwọn àsìkò báyìí, mo kàn máa ń ronúpìwàdà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni nnkan á sì padà bọ́ sípò pẹ̀lú Ọlọ́run. Àwọn ọjọ́ tí ó rọrùn nìyí, nítorí pé Ó máa ń dáríjì wá lẹ́sẹ̀kẹ́sẹ̀ tí a bá ti jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. (See 1 John 1:9.)

Àmọ́, ní àwọn ọjọ́ mìíràn, mo nílò kí Olúwa yí ọkàn mi padà. Inú lè bí mi lórí nnkan kan dé ibi pé n kò ní ké àbámọ̀ fún ọ̀nà tí mo gbà hu ìwà. Ní irú àwọn àkókò wọ̀nyẹn, màá bẹ Ọlọ́run pé kí ó yí ọkàn mi padà—kí ó sì jẹ́ kí n ronú pìwàdà nítòótọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.

Olúkúlùkù wa ní láti gbàdúrà fún ọkàn tí ó gb'ọgbẹ́ tí ó sì káàánú.

Níní ọkàn tí ó gb'ọgbẹ́ tí ó sì káànú túmọ̀ sí pé ọkàn rẹ yóò máa rọ̀ mọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà. Kò túmọ̀ sí pé kí o jóko kalẹ̀, kí o ká'rí sọ, "kí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn wá máa pa ọ kú lọ."

Kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí pé wàá àti pé wàá dúró sínú ipò àárò ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí Jésù. Àti pé nínú ipò àárò ìfẹ́ sí Olùgbàlà wa, wàá máa jẹ́wọ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Rẹ̀ nígbà gbogbo. Ọkàn rírọ̀ sí Jésù yìí máa ń yọrí sí ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ tí yóò kún ọ pẹ̀lú ayọ̀ tí ẹnu kò leè sọ tí ó sì kún fún ògo.

Nítorí náà, gbàdúrà yìí lónìí:

"Olúwa, fún mi ní ọkàn tí ó gb'ọgbẹ́ tí ó sì káàánú tí Ìwọ kò ní k'ẹ́gàn!"

Máa gba àdúrà yẹn lójoojúmọ́, kí o sì tẹ̀síwájú láti máa wá Olúwa bí o ṣe ń gbà á. Òun nìkan ni ó lè yí ọkàn rẹ padà kí ó sì sọ ọ́ di onírẹ̀lẹ̀ tòótọ́ níwájú Rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí Ó ṣe ń bá ọ rin ìrìn àjò láti di onírẹ̀lẹ̀ yìí, Òun yóò san án fún ọ lọ́pọ̀lọpọ̀—oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ yóò sì fi ara hàn ní ọ̀nà tí ó ní agbára nínú ayé rẹ.

Njẹ́ È̩kọ́ Bíbélì yìí ràn ọ́ lọ́wọ́? Tí o bá fẹ́ àwọn àfikún èlò àti orísun síi, ṣe àyẹ̀wò ojú òpó àkójọpọ̀ àwọn àdúrà ìtọ́nisọ́nà ọ̀fẹ́ níbí lórí FromHisPresence.com!

Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

5 Prayers of Humility

Nilo diẹ sii ti oore-ọfẹ, ojurere, ati ibukun Ọlọrun? Lẹhinna gbadura awọn adura irẹlẹ marun marun wọnyi ti irẹlẹ, beere lọwọ Oluwa lati ṣe ojurere fun ọ ati iranlọwọ fun ọ. On o dahun adura rẹ; O fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ! Ati pe ti o ba rẹ ara rẹ silẹ niwaju Oluwa, Oun yoo gbe ọ soke.

More

A fẹ́ dúpẹ́ ní ọwọ́ From His Presence Inc. fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí iwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.fromhispresence.com