Àdúrà 5 ti Ìrẹ̀lẹ̀Àpẹrẹ

5 Prayers of Humility

Ọjọ́ 2 nínú 5

Àdúrà kejì: "Bá mi wí bí ó ṣe wú Ọ" Ní Ìgbà míràn ó nira fún ẹran ara wa lati mọ àwọn nkankan, ṣugbọn Bíbélì fi ye wá pé àtúnṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run jẹ́ àpẹẹrẹ ìfẹ́ tí Ó ní sí wa. Kí ì ṣe nítorí ìkórira tàbí èmi yẹpẹrẹ ni Ọlọ́run ṣe ń tún wà ṣe. Òun kò tilẹ̀ ni ìmọ̀lára yẹn sì wá rárá! Òun jẹ aláànú, olóore-ọ̀fẹ́, àti Bàbá to ní ìfẹ́ tí Ó sì mọ wípé a nílò ìbáwí láti dàgbà —àti kí a lè dá bí Jésù pàápàá.

Ọlọ́run a máà ṣe àtúnṣe wá nítorí pé Ó fẹ́ràn wa.

Nítorí náà, ní ìwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ wípé ọwọ́ ìbáwí Rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ ìfẹ́ tí Ó ní sí wa, ṣe kó yẹ kí a gba ìbáwí Rẹ̀. Ṣé kò yẹ kí a wa ọ̀pá olùsọ àgùntàn Rẹ̀ sì ọwọ́ ọ̀tun àti ọwọ́ òsì wá, láti fí ẹsẹ̀ wá lè ipa ọ̀nà dáradára?

Ọ̀rẹ́, ṣe ìwọ kò fẹ́ ni ìmọ̀lára ọwọ ẹ̀rọ̀ Olúwa tí Ó fí fà ọ mọ́ra láti tọ́ ọ sona ki Ó sì mú ọ lọ nípa ọ̀nà tí Ó fẹ̀ mú ọ láti lọ? Ká Orin Dáfídì 32:8 láti rí kini ìlérí tí Ó ṣe fún wa.

Dájúdájú ó yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́

Ọ̀rẹ́, tí ó bá jẹ wípé ó fẹ́ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tòótọ́ níwájú Olúwa, tẹ́ síwájú kí ó sibéèrè fún ìbáwí Rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ kí a ṣe àápọn nípa rẹ. Ohun tí ó dára ni láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa, "Jọ̀wọ́, Jesu, bá mi wí bí ó bá ṣe wù Ọ̀"

Ìbáwí rẹ yíò tún ayé wa se. Ni àfikún, igbesi ayé wa yíò rọrùn ti a ba béèrè síwájú, pẹ̀lú ìtara fún àtúnṣe àti ìbáwí Rẹ̀, dípò títẹ̀ si ọna tiwa ati gbigba awọn abajade àìròtẹ́lẹ́ (tabi ohun tí a kò fẹ́)ni ìyọrísí ṣiṣe awọn ipinnu búburú .

Ọ̀rẹ́, a ní olùfẹ́ Bàbá tí ó múra tán láti ṣe àtúnṣe tí ó sì ń tọ́ wa sọ́nà nígbà tí a bá ṣe àṣìṣe, tabi nígbàtí a ba wa ninu ewu ti a ń rin ni ọna ti o lewu. Ṣe ìwọ kò ni béèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ loni láti tún ọ se ni ọna eyikeyi ti O nilo, nitorina kí o le duro ni ọna titọ Rẹ̀ tí ó jẹ́ tóóró pẹ̀lú?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

5 Prayers of Humility

Nilo diẹ sii ti oore-ọfẹ, ojurere, ati ibukun Ọlọrun? Lẹhinna gbadura awọn adura irẹlẹ marun marun wọnyi ti irẹlẹ, beere lọwọ Oluwa lati ṣe ojurere fun ọ ati iranlọwọ fun ọ. On o dahun adura rẹ; O fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ! Ati pe ti o ba rẹ ara rẹ silẹ niwaju Oluwa, Oun yoo gbe ọ soke.

More

A fẹ́ dúpẹ́ ní ọwọ́ From His Presence Inc. fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí iwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.fromhispresence.com