Àdúrà 5 ti Ìrẹ̀lẹ̀Àpẹrẹ

5 Prayers of Humility

Ọjọ́ 1 nínú 5

Àdúrà Kínní: “Olúwa, ṣe mí ní onírẹ̀lẹ̀.”

Ìrẹ̀lẹ̀ níwájú Ọlọ́run ṣe pàtàkì; àdúrà ìrọ̀rùn ti " Olúwa, ẹ ṣe mí ní onírẹ̀lẹ̀!" le yí ayé rẹ̀ padà.

Ṣùgbọ́n, bí ó ti ṣe rí pẹ̀lú gbogbo ǹkan, a kò lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ láì sí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run! A kò lè ṣe ohunkóhun rárá láì sí ìrànlọ́wọ́ Ọlórun. Rántí ohun tí Jésù sọ nínú ìwé Jòhánù 15:5: láì sí Òhun a kò le ṣe ohunkóhun!

Kíni ìdí tí ó yẹ kí á bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wípé kí Ó ṣe wá ní onírẹ̀lẹ̀?

Ìwé Pétérù Kínní 5:5-6 sọ fún wa pé Ọlọ́run kọjú ìjà sí àwọn agbéraga, ṣùgbọ́n Ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú fi hàn wá wípé Jésù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀; ó sì yẹ kí àwa náa fara wé E.

Nínú ìrìn àjò sí Ìrẹ̀lẹ̀, ipa tiwa ni kí á jọ̀wọ́ ara wa fún Jésù ní ọ̀tun àti ní titun ní ojoojúmọ́. Bí a ṣe ń ṣe èyí, kí á máa fojú sí gbígbé nínú Kristi ní àsìkò sí àsìkò, Òhun yíò ṣe ipa tirẹ̀—yíò yí ọkàn wa padà kí Ó sì ṣe wá ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Rẹ̀. Ọlọ́run nìkan ni ó ní agbára láti yí ọkàn wa padà.

Ọlọ́run yíò fún ọ ní ọwọ́ tuntun àti ọkàn mímọ́ tí o bá lè bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀.

Mo fẹ́rẹ̀ má n bèèrè nnkan yìí ní ojoojúmọ́. (Mo fẹ́ láti máà bèèrè ní ojoojúmọ́, ṣùgbọ́n mo máa ń gbàgbé ní ìgbà míràn). Ṣùgbọ́n ní gbogbo ìgbà tí mo bá bèèrè pé kí Ó ṣe mí ní onírẹ̀lẹ̀, mo máa n ní ìmọ̀lára pé Ó fà mí díẹ̀ sún mọ́-On.

Òhun yíò ṣe ohun kànnà fún o. Tí ìwọ́ bá bèèrè lọ́wọ́ Olọ́run kí Ó ṣe ọ́ ní onírẹ̀lẹ̀, yíò yí o padà yíò si ràn ọ́ lọ́wọ́ kí o rìn ní iwájú Rẹ̀ ní mímọ́ àti ìbárẹ́ pẹ̀lú Rẹ.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

5 Prayers of Humility

Nilo diẹ sii ti oore-ọfẹ, ojurere, ati ibukun Ọlọrun? Lẹhinna gbadura awọn adura irẹlẹ marun marun wọnyi ti irẹlẹ, beere lọwọ Oluwa lati ṣe ojurere fun ọ ati iranlọwọ fun ọ. On o dahun adura rẹ; O fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ! Ati pe ti o ba rẹ ara rẹ silẹ niwaju Oluwa, Oun yoo gbe ọ soke.

More

A fẹ́ dúpẹ́ ní ọwọ́ From His Presence Inc. fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí iwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.fromhispresence.com