Àdúrà 5 ti Ìrẹ̀lẹ̀Àpẹrẹ

5 Prayers of Humility

Ọjọ́ 4 nínú 5

Àdúrà 4: “Olúwa, Ràn Mí Lọ́wọ́ Kí N Lè Gba Ọ̀rọ̀ Rẹ Gbọ́.”

Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fún aráyé, kò sì ní àṣìṣe kankan. Jòhánù orí 1 sọ fún wa pé Bíbélì jẹ́ Jésùní ọ̀nà tí a kọ!

Òtítọ́ ni: Jésù ni Ọ̀rọ̀ náà, Ọ̀rọ̀ náà sì ni Jésù.

Ronú nípa èyí fún ìgbà díẹ̀. Òtítọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù yìí yóò mú ọ kún fún ìbẹ̀rù, yóò sì mú kí o sin Kristi.

Àmọ́ kí ni "Ọ̀rọ̀ náà di ẹran ara" ní í ṣe pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀?

Kò sí àṣìṣe kankan nínú Bíbélì. Òtítọ́ pátápátá ni. Síbẹ̀, ó sọ ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó lè má dùn mọ́ wa nínú:

  • Ó sọ àwọn nǹkan tí ó lè yí wa lérò padà; àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń lò láti yí ọkàn wa padà.
  • Ó sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tí àṣà ẹ̀ṣẹ̀ kórìíra.
  • Ohun tí ó ṣe àjèjì jù lọ ni pé, ó sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun rere tí ọkàn ìgbéraga wa kì í fẹ́ gbà ní ìgbà míràn.

Kókó náà rèé:

Ó gba ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kí ènìyàn tó lè gba àwọn ohun rere tí Ọlọ́run sọ gbọ́.

Mi ò lè sọ fún ọ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí ẹnìkan ti sọ fún mi pé wọ́n múra tán láti fetí sí gbogbo àtúnṣe tí Ọlọ́run fẹ́ fi ránṣẹ́ sí wọn — àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí tí ó sọ fún wa ní ìgbà tí a bá ṣe àṣìṣe. Àmọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn ti jókòó níwájú mi tí wọ́n sì sọ fún mi ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ohun kan náà ni wọ́n ń sọ pé wọn ò fẹ́ gba èyíkéyìí nínú àwọn ohun rere tí Olúwa sọ nípa wọn gbọ́.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, bí a kò bá gba gbogbo ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa wa—bóyá ọ̀rọ̀ yẹn ń fúnni ní ìṣírí tàbí ó ń mú ni ronú pìwà dà—ó túmọ̀ sí pé a ní ìṣòro ìgbéraga.

Bí o kò bá gba gbogbo ohun tí Ọlọ́run sọ—kódà àwọn ohun tí ó jẹ́ kí o mọ̀; àwọn nǹkan tí ó ń tako ìfọkànbalẹ̀ ara rẹ tí kò dára —ní ìgbà náà o jẹ́ agbéraga. Bí ẹ bá sì ní ìgbéraga nínú ọkàn yín, ìgbéraga yẹn kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Ó ń mú kí Ó fi "àwọn ohun tí ń dènà" sínú ìgbésí ayé rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni, Ó máa bá ẹ wí kí ó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti di onírẹ̀lẹ̀ ...

... njẹ́ kò ní rọrùn láti pinnu pé á máa gbà Á gbọ́, ohunkóhun tí Ì bá À sọ?

Ìdí nìyí tí a fi ń gbàdúrà pé, "Olúwa, ràn mí lọ́wọ́ láti gba Ọ̀rọ̀ Rẹ gbọ́".

Tí ènìyàn bá gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́, ó fi hàn pé onítọ̀hún ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Àti pé bí a bá fẹ́ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́, a gbọ́dọ̀ gba ohun gbogbo tí ó sọ gbọ́—kódà ní ìgbà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá fi àwọn ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wa hàn, tàbí àwọn èrò búburú wa, tàbí bí a kò ṣe níyì lójú ara wa.

Ọ̀rẹ́ mi, tí o bá fẹ́ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, pinnu láti gba gbogbo ohun tí Ọlọ́run bá sọ gbọ́:

  • Gbàgbọ́ ninu Ọ̀rọ̀ Rẹ ní ìgbà tí O ba kò ọ́ lójú, àti ní ìgbà tí Ó bà gbè ọ́ níjà.
  • Gbà Á gbọ́ ní ìgbà tí Ó bá bá ọ wí, kí o sì tún gbà Á gbọ́ bí Ó ṣe ń bù kún ọ.

Òtítọ́ ni Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, ṣùgbọ́n o ní láti fi etí sílẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Rẹ̀—kí o sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ní abẹ́ ọwọ́ agbára Rẹ̀—kí o lè jèrè rẹ̀ ní kíkún.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

5 Prayers of Humility

Nilo diẹ sii ti oore-ọfẹ, ojurere, ati ibukun Ọlọrun? Lẹhinna gbadura awọn adura irẹlẹ marun marun wọnyi ti irẹlẹ, beere lọwọ Oluwa lati ṣe ojurere fun ọ ati iranlọwọ fun ọ. On o dahun adura rẹ; O fi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ! Ati pe ti o ba rẹ ara rẹ silẹ niwaju Oluwa, Oun yoo gbe ọ soke.

More

A fẹ́ dúpẹ́ ní ọwọ́ From His Presence Inc. fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí iwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.fromhispresence.com