Ìwòye Bíbélì Lóríi Ìyípadà ÀwùjọÀpẹrẹ
Ìṣẹ́gun
Kì í ṣe pé Jésù kàn fẹ́ káwọn ènìyàn máa jẹ́ aláìní lọtítí. A rí èyí nígbàtí a ka ìwé Ìhìnrere Máàkù. Àánú wọn ṣe É, Ó sì fẹ́ kí wọ́n rí oúnjẹ jẹ. Àmọ́, ọ̀nà tí Ó ń gbà ṣe é ni láti ṣọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀. Wọ́n máa ń kó ipa pàtàkì nínú wíwá oúnjẹ, èyí tí a ó sì sọ di púpọ̀ sí i, tí wọ́n á sì pín oúnjẹ náà fún àwọn èyìnyàn.
Jésù fẹ́ ki á mọ àwọn ohun àmúlò tí Ọlọ́run ti fún wa àti àwọn ẹlòmíràn, bó ti wù kí wọ́n kéré tó, kí á sì lò wọ́n láti pèsè níbití àìní bá wà
"Jésù nílò ohun tí a lè fún Un. Ohun náà lè má fi bẹ́ẹ̀ tó, àmọ́ Ó nílò rẹ̀. Ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé iṣẹ́ ìyanu lẹ́yìn iṣẹ́ ìyanu àti ayọ̀ ńlá lẹ́yìn ayọ̀ ńlá ni a ti fi dun ayé nítorí pé a ò mú ohun tí a ní àti ohun tí a jẹ́ wá fún Jésù. Bí a bá gbé ara wa lé pẹpẹ iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀, kò sí ẹni tí yóò lè sọ ohun tí Yóò fi wá ṣe àti ti Yóò nípasẹ̀ wa. Ó lè máa dùn wá kí ó sì tì wá lára pé a kò lè múwá jù báyìí lọ - òtítọ́ sì ni; àmọ́ ìyẹn kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ìdí tí à kó fi ní mú ohun tí a ní wá. Ìwọ̀nba ma ń di púpọ̀ lọ́wọ́ Kristi."
-William Barclay
Ṣe Àṣàrò
Báwo ni Jésù ṣe fẹ́ báwa ṣé àṣepọ̀ fún ire àwọn ènìyàn? Àwọn ìgbésẹ̀ wo pàtó ni Óún bi wá láti gbé kí á bàa lè pèsè fún àwọn tó wà láyìíká wa?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ Krìstẹ́nì ni bíbá àìní yálà nípa ti ara tàbí ti ẹ̀mí jẹ lógún. Kíni ó yẹ kí jẹ́ ọ̀kúndùn jùlọ fún wa bíi Krìstẹ́nì? Kíni a leè kọ́ láti inú Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ yí?
More