Ìwòye Bíbélì Lóríi Ìyípadà ÀwùjọÀpẹrẹ
Oun tí ó Ṣe Kókó
Nínú ìwé ìhìnrere ti Lúùkù, a ri wípé Jésù, fún ìgbà àkọ́kọ́, Ó ṣe àfihàn ìdí tí ó fi wá. Èyí tí a tún kọ nípa rẹ̀ nínú ìwé Aísáyà 61:1-2, ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn kí á tó bí Jésù. Kí ni àwọn ìdí tí Jésù fún wa nípa wí wá rẹ̀? Ṣé ó ní ṣe ní ọ̀nà tó pọ̀ sí àìní tí ẹ̀mí àwọn ènìyàn àbí àìní tí ara tàbí pẹ̀lú àwọn méjèèjì?
Ní pa ṣíṣe àṣàrò lórí ọ̀rọ̀ rere tí Jésù sọ, a ó ní òye àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà pè wá láti jẹ́ alábàṣepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ láti mú ojútùú sí àwọn ìdojúkọ ati àìní tí ó wà ní àwùjọ wa. Láìsí ìlọwọsí Ọlọ́run, a kò lè bá àwọn àìní wa pàdé--ṣùgbọ́n láìsí ìbáṣepọ̀ wa Ọlọ́run kò ní ṣe ohunkóhun.
Ṣe Àṣàrò
Ní ìgbà míràn yíò dàbí wípé a kò ní agbára, á dàbí wípé a kò ní ohùn èlò tí a nílò láti kọjú àwọn ìṣòro tí àá hún dojú kọ. Ìwé Mímọ́ ti fihàn wá wípé àwọn ohun àmúlò tí a ní tí ó ṣe bíntí ó ma tó nígbà tí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run, Ẹni tí o lè ṣe ìsọdipúpọ̀ ipa wọn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ Krìstẹ́nì ni bíbá àìní yálà nípa ti ara tàbí ti ẹ̀mí jẹ lógún. Kíni ó yẹ kí jẹ́ ọ̀kúndùn jùlọ fún wa bíi Krìstẹ́nì? Kíni a leè kọ́ láti inú Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ yí?
More