Ìwòye Bíbélì Lóríi Ìyípadà ÀwùjọÀpẹrẹ

A Biblical View On Social Change

Ọjọ́ 4 nínú 5

Ìpèsè

Njẹ́ o lè ronú àkókò kan nígbàtí o ní ìmọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì nítorí títóbi tàbí ti ìwọ̀n ipenija tàbí iṣẹ́ ṣíṣe tí o dojú kọ? Báwo ni ó ṣe rí lára? Kíni ìgbésẹ̀ tí o gbé?

Ọ̀re mi, Màríà, ní ìmọ̀lára yí I. Ìgbé ayé ní Uganda le koko fun u. Ọkọ rẹ̀ sá lọ, ó sì fi àwọn ọmọ kékeré mẹ́rin sílẹ̀ fun. Wọ́n ń gbé ní ahéré tí a fí amọ̀ kọ́ pẹ̀lú òrùlé ewéko wọ́n sì ní ewúrẹ́ kan. Màríà ń ṣiṣẹ́ nígbàkigbà tí ó bá lè ṣeé, owó ọ̀yà rẹ̀ kéré jọjọ, ṣùgbọ́n kò sí ìgbà tí owó tí ó ń gbà tó òun àti ẹbí rẹ̀ ń wà nínú ebi nígbà gbogbo. Bẹ́ẹ̀ ni owó kìí ṣé kù láti sàn owó ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀.

Ní ọjọ́ kan Màríà gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì ní ilé ìjọsìn agbègbè rẹ̀. Ó lọ síbẹ̀ bótilẹ̀jẹ́pé kò tíì dì onígbàgbọ́. Nigbati o gbọ nípa bí Jésù ṣé bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ènìyàn ní ọjọ́ kan ṣoṣo, ó hàn síi pé Ọlọ́run fiyèsí àwọn ẹni tí ebi ń pa! Ẹ̀kọ́ náà dá wo bí Jésù ṣe gba àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ níyànjú láti ṣiṣẹ́ papọ̀ láti ríi dájú pé gbogbo ènìyàn ni ó jẹun. Pẹlú áwọn ará míràn, Màríà ní ìmísí láti bẹ̀rẹ̀ ètò fún irú ọjọ́ iwájú tí ó yàtọ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀.

Màríà àti ẹbí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní gbin àwọn irúgbìn fún títà wọ́n sì ṣàkóso nínú owó tó ń wọlé láti ra adìẹ dí ẹ̀, lẹ́yìn èyí àwọn ẹlẹ́dẹ̀, àti l'ákótán màlúù méjì. Èyí ní ipá ńlá púpọ̀ lórí ìgbésí ayé wọn: oúnjẹ pẹ̀lú gbogbo èròjà f'ára, aṣọ wíwọ̀, owó ilé ẹ̀kọ́, ibùgbé tó dára, ati òógùn láti tọ́jú àìsàn.

Màríà tí dí ẹnití ayọ̀ rẹ̀ bú jáde lónìí. Ó ń bá Olúwa rìn pẹ́kípẹ́kí ó sì ti ri bi Ó ti ṣe ràn l'ọ́wọ́ láti pèsè fún òun àti ẹbí rẹ̀.

Ṣe Àṣàrò:

Bí a ṣé ń ronú nípa àwọn òkè ìṣòro tí ó dojúkọ agbègbè wa àti àìní àwọn ohun àmúlò wa, kíni àwọn ìwúrí pàtó tí a rí nínú ìtàn yí?

Key: ọjọ_4

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

A Biblical View On Social Change

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ Krìstẹ́nì ni bíbá àìní yálà nípa ti ara tàbí ti ẹ̀mí jẹ lógún. Kíni ó yẹ kí jẹ́ ọ̀kúndùn jùlọ fún wa bíi Krìstẹ́nì? Kíni a leè kọ́ láti inú Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ yí?

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Tearfund fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọwọ lọ sí: http://www.tearfund.org/yv