Ìwòye Bíbélì Lóríi Ìyípadà ÀwùjọÀpẹrẹ
A Sọdi Alágbára
Báwo ni a ṣe ní láti fẹ́ràn Ọlọ́run? Kí ni ó túmọ̀ sí láti fẹ́ràn ọmọnìkejì wa gẹ́gẹ́ bíi ara wa? Ṣé a ní ìtara ní tòótọ́ fún àláfíà wọn, nípa ti ara àti nípa ti ẹ̀mí?
Jésù ní ìtara nípa ènìyàn ní àkótán. Ó wo aláìsàn sàn bí Ó ti ń wàásù àti bí Ó ti ń kọ́ wọn. Ní tí tẹ̀le, àwa náà gbọ́dọ̀ pín nínú ìtara rẹ̀.
Nígbàtí Jésù rán àwọn ọmọ lẹ́yìn Rẹ̀ méjèjìlá jáde láti jí'ṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn, Ó pàṣẹ fún wọn láti wo aláìsàn sàn àti láti ní ìtara fún àìní àwọn ènìyàn nípa ti ara bí wọ́n ti ń wàásù ìhìnrere ti Jésù Krístì.
Ṣe Àṣàrò:
Jèsú ti ró wa ní agbára láti bá àìní àwọn èyìnyàn pàdé. Báwo ni a ṣe lè ṣe sí àwọn aláìní ní àgbègbè wa láti fún wọn ní agbára láti bá àìní ara wọn pàdé?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹgbẹ́ Krìstẹ́nì ni bíbá àìní yálà nípa ti ara tàbí ti ẹ̀mí jẹ lógún. Kíni ó yẹ kí jẹ́ ọ̀kúndùn jùlọ fún wa bíi Krìstẹ́nì? Kíni a leè kọ́ láti inú Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ yí?
More